Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì
A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.
Tahiti
Ìbẹ̀wò sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
Ṣó yẹ kéèyàn sọ ṣáájú kó tó ṣebẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ. A fẹ́ kí gbogbo ẹni tó fẹ́ ṣebẹ̀wò sí bẹ́tẹ́lì kọ́kọ́ sọ fún wa ṣáájú kí wọ́n tó máa bọ̀, yálà àwọn tó ń bọ̀ pọ̀ tàbí wọn ò tó nǹkan ìdí sì ni pé a ò fẹ́ kí èrò pọ̀ jù, a si fẹ́ kí gbogbo ẹni tó wá gbádùn ìbẹ̀wò wọn.
Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ṣé ẹ ṣì lè ṣebẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ó ṣeé ṣe ká má gbà yín láàyè láti rìn yíká ọgbà wa. Ìdí sì ni pé ó níye èèyàn tá a lè mù rìn yíká ọgbà wa lójúmọ́.
Ìgbà wo ló yẹ kẹ́ ẹ dé? Kérò má bàa pọ̀ jù, ẹ jọ̀wọ́, ẹ dé ní ó kéré tán, ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún kó tó di pé wọ́n máa mú yín rìn yíká.
Báwo lẹ ṣe máa sọ fún wa ṣáájú? Tẹ bọ́tíìnì tá a pè ní “Ṣàdéhùn Ọjọ́ Ìbẹ̀wò.”
Ṣé ẹ lè yí ọjọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá pa dà tàbí kẹ́ ẹ sọ pé ẹ ò ní lè wá mọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ bọ́tíìnì tá a pè ní “Wo Ọjọ́ Àdéhùn Tàbí Kó O Yí I Pa Dà.”
Tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí àyè mọ́ lọ́jọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá ńkọ́? Ẹ máa wo ìkànnì wa látìgbàdégbà. Àyè máa yọ táwọn kan bá yí ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ wá pa dà tàbí tí wọn ò fẹ́ wá mọ́.
Ìbẹ̀wò
P.K. 2,7 Cote mer
Toahotu
Taiarapu Ouest
TARAVAO TAHITI
FRENCH POLYNESIA
+689 40-54-70-00
Àwọn Iṣẹ́ Tí À Ń Ṣe Níbẹ̀
À ń tú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè Tahitian. À ń bójú tó bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àwọn erékùṣù kéékèèké àtàwọn erékùṣù òkun. Tá a bá pa gbogbo àgbègbè náà tí wọ́n ń bójú tó pọ̀, ó fẹ́ tó gbogbo Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù.

