Yorùbá
Àwọn Ọ́fíìsì Àtàwọn Tó Wà Ṣèbẹ̀wò: Cameroon
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/1011232/univ/art/1011232_univ_sqr_xl.jpg

Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì

A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.

Cameroon

Ìbẹ̀wò sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì

Ṣó yẹ kéèyàn sọ ṣáájú kó tó ṣẹ̀bẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ. A fẹ́ kí gbogbo ẹni tó fẹ́ ṣẹ̀bẹ̀wò sí bẹ́tẹ́lì kọ́kọ́ sọ fún wa ṣáájú kí wọ́n tó máa bọ̀, yálà àwọn tó ń bọ̀ pọ̀ tàbí wọn ò tó nǹkan ìdí sì ni pé a ò fẹ́ kí èrò pọ̀ jù, a si fẹ́ kí gbogbo ẹni tó wá lè gbádùn ìbẹ̀wò wọn.

Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ṣé ẹ ṣì lè ṣẹ̀bẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ó ṣeé ṣe ká má gbà yín láàyè láti rìn yíká ọgbà wa. Ìdí sì ni pé ó níye èèyàn tá a lè mù rìn yíká ọgbà wa lójúmọ́.

Ìgbà wo ló yẹ kẹ́ ẹ dé? Kérò má bàa pọ̀ jù, ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí àsìkò tẹ́ ẹ máa dé má ṣe ju ogún (20) ìṣẹ́jú ṣáájú àkókò tí wọ́n máa mú yín rìn yíká.

Báwo lẹ ṣe máa sọ fún wa ṣáájú? Tẹ bọ́tíìnì tá a pè ní “Ṣàdéhùn Ọjọ́ Ìbẹ̀wò.”

Ṣé ẹ lè yí ọjọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá pa dà tàbí kẹ́ ẹ sọ pé ẹ ò ní lè wá mọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ bọ́tíìnì tá a pè ní “Wo Ọjọ́ Àdéhùn Tàbí Kó O Yí I Pa Dà.”

Tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí àyè mọ́ lọ́jọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá ńkọ́? Ẹ máa wo ìkànnì wa látìgbàdégbà. Àyè máa yọ táwọn kan bá yí ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ wá pa dà tàbí tí wọn ò fẹ́ wá mọ́.

Wa Ìwé Pẹlẹbẹ Tó Ń Ṣàlàyé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa jáde

Àdírẹ́sì àti Fóònù

Face commissariat central No. 4

Logbessou

DOUALA

CAMEROON

+237 233-50-70-00

+237 699-99-55-02

+237 699-99-98-37

+1 914-509-0046 (Àkíyèsí: Kò ní ná ẹ lówó jù tó o bá fi nọ́ńbà fóònù ilẹ̀ Amẹ́ríkà yìí pe ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Cameroon, àmọ́ network tó o bá ń lò ló máa pinnu.)