Ẹ̀tọ́ Àdàkọ

© 2014 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ jẹ́ tiwa.

Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. (tá a tún mọ̀ sí “Watchtower”) ló ni ìkànnì yìí, àwọn ló sì ń bójú tó o. Tá ò bá sọ pé kò rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ọ̀rọ̀ àti àwọn ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì yìí jẹ́ ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.

Àmì Oní-nǹkan

Ọ̀rọ̀ náà, “Adobe,” àti àmì “Adobe,” ọ̀rọ̀ náà “Acrobat,” àti àmì “Acrobat” jẹ́ ti ilé iṣẹ́ Adobe Systems Incorporated. Ilé iṣẹ́ Apple Inc. ló ni àmì “iTunes” àti “iPod.” Gbogbo àwọn àmì oní-nǹkan àti àwọn àmì oní-nǹkan tó ti lóǹtẹ̀ ìjọba yòókù jẹ́ tí àwọn ilé iṣẹ́ tó ni wọ́n.

Àdéhùn Lílo Ìkànnì àti Àṣẹ Láti Lo Ìkànnì

Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí ló máa sọ bó ṣe yẹ kó o lo ìkànnì yìí. Lílò tó ò ń lo ìkànnì yìí fi hàn pé o fara mọ́ Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí láìkù síbì kan. Àmọ́, bí o kò bá fara mọ Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí tàbí apá èyíkéyìí lára Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí, má ṣe lo ìkànnì yìí.

Kí lo túmọ̀ sí láti lo ìkànnì yìí lọ́nà tó tọ́? O lè wò, wà jáde, kí o sì tẹ àwọn àwòrán, àwọn ìtẹ̀jáde tá a ká sórí ẹ̀rọ, orin, fọ́tò, ọ̀rọ̀, àti fídíò (“ohun tó wà lórí ìkànnì yìí”) tó ní ẹ̀tọ́ àdàkọ láti orí ìkànnì yìí fún ìlò ara rẹ àti fún ète tí kò la ìṣòwò lọ, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìkálọ́wọ́kò tó wà nísàlẹ̀ yìí àti láwọn ibòmíì nínú Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí. Torí náà, o lè má:

  • Gbé ohun tó wà lórí ìkànnì yìí sórí íńtánẹ́ẹ̀tì (ìkànnì èyíkéyìí lórí íńtánẹ́ẹ̀tì, ìkànnì téèyàn ti lè wa ìsọfúnni láìgbàṣẹ tàbí ìkànnì àjọlò);

  • Tún ohun tó wà lórí ìkànnì yìí gbé sórí àwọn ètò orí kọ̀ǹpútà èyíkéyìí tàbí kó jẹ́ apá kan ètò orí kọ̀ǹpútà náà;

  • Ṣe àtúnkọ, ṣe ohun tó jọ tàbí fi ohun tó wà lórí ìkànnì yìí ṣòwò (kódà kó o má jèrè lórí ẹ̀ pàápàá), tó fi mọ́ pínpín àwọn ètò orí kọ̀ǹpútà tá a lò, tó tan mọ́, tàbí so mọ́ ìkànnì yìí (bóyá èyí tó ṣeé yí pa dà tàbí èyí tí ò ṣeé yí pa dà);

  • Wọ ìkànnì yìí torí àti ṣe àgbékalẹ̀ tàbí pín ìlànà ìṣiṣẹ́, ohun èlò ìṣiṣẹ́, tàbí ọnà ìṣiṣẹ́ láti fi kó ìsọfúnni jọ, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀rọ tàbí ìlànà àgbékalẹ̀ kan (títí kan ètò orí kọ̀ǹpútà tá a ti pa tì, títú orí ìkànnì fún àwọn ìsọfúnni tá a fi pa mọ́, yíyọ ìsọfúnni lára àwọn ọ̀wọ́ ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì tàbí fífara balẹ̀ kó àwọn ìsọfúnni jọ pẹ̀lú ète àtijèrè) lórí tàbí tó níí ṣe pẹ̀lú ìkànnì yìí;

  • Lo ìkànnì yìí tàbí àwọn ètò tó wà níbẹ̀ fún ètè tí kò dáa, irú bíi ṣíṣe màdàrú ọ̀nà tó tọ́ láti wọlé sórí ìkànnì tàbí lílo àwọn ọgbọ́n àyínìke míì láti wọlé sórí ìkànnì yìí tàbí àwọn ètò orí rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn ọ̀nà tó ṣe kedere tí a ti pèsè;

  • Lo ìkànnì yìí lọ́nà èyíkéyìí tó lè ba ìkànnì yìí jẹ́ tàbí tó lè mú kó má ṣiṣẹ́ dáadáa, tó lè da nǹkan rú tí ò sì ní jẹ́ káwọn èèyàn lè wọlé tàbí rí ìkànnì náà lò; tàbí lọ́nà èyíkéyìí tí kò bá òfin mu, tó tàpá sófin, fún lílu jìbìtì, tó lè pani lára, tàbí tó kan ìgbòkègbodò èyíkéyìí tí kò bá òfin mu, tó tàpá sófin, tí wọ́n fi ń luni ní jìbìtì, tàbí tó lè ṣe ìpalára;

  • Lo ìkànnì yìí lọ́nà èyíkéyìí tó bá jẹ mọ́ ètò ìpolówó ọjà.

Yíyẹ Àdéhùn Lílo Ìkànnì

Láìní fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ẹ̀tọ́ míì tí Watchtower ní lábẹ́ Àdéhùn Lílo Ìkànnì, tó o bá yẹ Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí lọ́nàkọnà, Watchtower ò ní kùnà láti gbé ìgbésẹ̀ bó bá ṣe tọ́ lójú Watchtower láti bójú tó títẹ àdéhùn lójú, lára irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé, wọ́n ò ní gbà ọ́ láyè láti wọlé sórí ìkànnì yìí fún àkókò díẹ̀, wọn ò ní jẹ́ kó o rí ìkànnì yìí lò mọ́, wọn ò ní jẹ́ kí àwọn kọ̀ǹpútà tó ń lo àdírẹ̀sí ìwọlé sórí íńtánẹ́ẹ́tì, ìyẹn “IP address” kan náà pẹ̀lú rẹ wọlé sí ìkànnì yìí, wọ́n sì máa kàn sí ilé iṣẹ́ tó ń pèsè íńtánẹ́ẹ̀tì fún ẹ pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kó wọlé sórí ìkànnì yìí àti/tàbí kí wọ́n pè ẹ́ lẹ́jọ́.

Àtúnṣe

Watchtower lè ṣe àtúnṣe sí Àdéhùn Lílo Ìkànnì látìgbàdégbà. Ọjọ́ tí Àdéhùn Lílo Ìkànnì tí wọ́n tún ṣe bá dé orí ìkànnì yìí ni àdéhùn náà tí di àmúlò fẹ́ni tó bá fẹ́ lo ìkànnì yìí. Torí náà, jọ̀wọ́, máa wo abala tó o wà yìí déédéé kó o lè mọ àwọn àtúnṣe tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe.

Òfin àti Ibi Tí Wọ́n Ti Lè Gbọ́ Ẹjọ́

Òfin ìpínlẹ̀ New York ní Amẹ́ríkà la gbé Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí kà láì jẹ́ kí àwọn abala òfin míì tó ta kò ó dá wa lọ́wọ́ kọ́. Ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ tàbí ti ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ New York ní Amẹ́ríkà ló máa gbọ́ ẹjọ́ èyíkéyìí tó jẹ mọ́ yíyẹ Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí.

Tí Ilé Ẹjọ́ Kò Bá Fara Mọ́ Abala Kan

Tí ilé ẹjọ́ kan tó lẹ́tọ̀ọ́ láti gbọ́ irú ẹjọ́ yìí bá dájọ́ pé abala kan lára Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí kò ṣeé pe ẹjọ́ lé lórí, kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, a ò lè fipá múni tẹ̀ lé e, tàbí pé kò bófin mu, àwọn abala tó kù á ṣì lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Tí Watchtower kò bá fòfin gbé ẹnì kan tó yẹ abala kan lára Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé wọ́n ti gbójú fo abala yẹn tàbí pé Watchtower ò lẹ́tọ̀ọ́ láti pe èèyàn lẹ́jọ́ lórí abala yẹn.

Àdéhùn Náà Látòkèdélẹ̀

Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí jẹ́ àjọgbà láàárín ìwọ àti Watchtower lórí lílo ìkànnì yìí àti pé àdéhùn yìí borí àwọn àdéhùn tó ti wà tẹ́lẹ̀ nípa lílo ìkànnì yìí.