Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àdéhùn Láti Pa Àṣírí Mọ́

Àdéhùn Láti Pa Àṣírí Mọ́

Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì, ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí olúkùlùkù ní pé kí ọ̀rọ̀ àṣírí ẹni má lu síta. Ètò náà fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ àárín ẹni méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọn kì í sì í fọ̀rọ̀ ohun tó jẹ́ àṣìrí ẹnì kan ṣeré rárá bí wọ́n ṣe ń bójú tó ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílò tí wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìjọsìn wọn àti ìrànwọ́ tí wọ́n ń ṣe fún àwọn èèyàn. Wọn ò tún gbàgbé pé àwọn gbọ́dọ̀ pa àṣírí mọ́, wọ́n sì ń rí i dájú pé àwọn ìsọfúnni tó wà níkàáwọ́ àwọn ò lu síta. (Òwe 15:22; 25:9) Ọwọ́ gidi ni wọ́n fi mú ọ̀rọ̀ àṣírí.—Òwe 20:19.

Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ìjọba ti ṣe òfin lórí ẹ̀tọ́ oníǹkan, èyí tó máa jẹ́ kí olúkùlùkù ní ẹ̀tọ́ lórí ohun tó jẹ́ àṣírí rẹ̀. Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó ṣe irú òfin yìí ní ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ oníǹkan, wọn kì í sì í fọ̀rọ̀ àṣírí tàfàlà. Bó ṣe wà nínú ìwé àdéhùn yìí, ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò máa bá a nìṣó láti pa ọ̀rọ̀ àṣírí tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ mọ́ bó ti ń ṣe bọ̀ tipẹ́tipẹ́.

Àwọn Tó Wà Lábẹ́ Ìlànà Yìí

Ìlànà yìí kan ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà látòkèdélẹ̀, èyí táwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà láwọn orílẹ̀-èdè kárí ayé ń ṣojú fún.

Ààbò Tó Péye Lórí Ìsọfúnni

Àwọn ìlànà tó tẹ̀ lé e yìí ni ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ ìsọfúnni nípa ara ẹni tó wà lọ́wọ́ wọn:

 1. Ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ kò ní di ohun ṣeréṣeré. A ò ní tẹ òfin lójú.

 2. A máa lo ìsọfúnni tá a bá gbà lọ́wọ́ ẹnì kan fún kìkì ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìrànwọ́ tá à ń ṣe fún àwọn èèyàn.

 3. A ò ní ṣe àfikún tàbí yọ kúrò nínú ìsọfúnni tá a bá gbà. A máa ṣe àtúnṣe sí àṣìṣe èyíkéyìí lójú ẹsẹ̀ tí ètò náà bá ti mọ̀ èyí.

 4. A máa tọ́jú ìsọfúnni kan sọ́wọ́ fún àkókò gígún kìkì tó bá yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tó sì bá òfin mu.

 5. A máa rí i dájú pé a bọ̀wọ̀ tó yẹ fáwọn tá a ní ìsọfúnni wọn lọ́wọ́.

 6. A máa gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti rí i pé a tọ́jú àwọn ìsọfúnni ẹni ẹlẹ́ni tó wà lọ́wọ́ wa, débi tí kò fi ní lu sọ́wọ́ ẹni tí kò yẹ kó mọ̀ nípa rẹ̀. Gbogbo kọ̀ǹpútà táwọn ìsọfúnni àwọn èèyàn wà lórí ẹ̀ ló jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ìwọlé nìkan ni èèyàn lè fi wọ orí rẹ̀, àwọn tó sì lẹ́tọ̀ọ́ sí i nìkan ló mọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwọlé náà. A máa ń ti àwọn ọ́fíìsì wa pa lẹ́yìn àkókò iṣẹ́, àwọn tó sì lẹ́tọ̀ọ́ láti wọlé nìkan ló lè wọ àwọn ọ́fíìsì wọ̀nyí.

 7. A ò ní fi àwọn ìsọfúnni ẹni ẹlẹ́ni ránṣẹ́ sáwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa láìjẹ́ pé ó pọn dandan ká lè ṣe àwọn ohun tó jẹ́ mọ ìjọsìn àti ìrànwọ́ tá à ń ṣe fún àwọn èèyàn. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló fara mọ ètò ìjọsìn wa àti ètò ìrànwọ tá a ń ṣe fun àwọn èèyàn torí fúnra wọn ni wọ́n pinnu láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, káwọn èèyàn sì mọ̀ wọ́n ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ẹ̀tọ́ Oníǹkan

 1. Ẹni tó fún wa ní ìsọfúnni nípa ara rẹ̀ lẹ́tọ̀ọ́ pé ká pa ọ̀rọ̀ àṣírí rẹ̀ mọ́, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe àtúnṣe sí ìsọfúnni tó fún wa, ó sì lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé ká pa ìsọfúnni òun rẹ́ nínú ẹ̀rọ wa, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé ohun tó béèrè bá ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe mú gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú àdéhùn yìí.

 2. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ béèrè fún àwọn ohun tá a sọ ní apá yìí gbọ́dọ̀ pèsè ẹ̀rí ìdánimọ̀ tó péye.

 3. Tí oníǹkan bá fẹ́ láti rí ìsọfúnni àtàwọn ọ̀rọ̀ àṣírí nípa ara rẹ̀ tàbí tó fẹ́ ṣe àtúnṣe sí i tàbí tó fẹ́ ká pa ìsọfúnni òun rẹ́, ètò náà máa gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò fínnífínní kí wọ́n lè rí i dájú pé ohun tó béèrè kò ní tẹ òfin èyíkéyìí tí ètò náà ń tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn lójú, títí kan bóyá irú ìyọ̀ǹda bẹ́ẹ̀ kò ní fi ẹ̀tọ́ òmìnira ìjọsìn àtàwọn ẹ̀tọ́ míì tí ètò náà ní sínú ewu.

 4. O wu ètò náà kó máa bójú tó ìsọfúnni nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà títí lọ gbére. Téèyàn bá pa irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ rẹ́, ńṣe ló ń ṣàkóbá fún àwọn ohun tí ètò náà gbà gbọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn àtàwọn ìgbòkègbodò míì tí ètò náà ń ṣe.

Ẹ̀tọ́ Láti Fi Ẹjọ́ Sùn

Tí ẹnì kan bá gbà pé wọ́n ti tẹ ẹ̀tọ́ òun lójú, ó lè kọ lẹ́tà sí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka kó lè fẹjọ́ sùn wọ́n. Kó fi lẹ́tà náà ránṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀ méjì tó kíyè sí i pé wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ òun lójú náà.