Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 Orin 139

Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in

Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in

Wà á jáde:

(Mátíù 28:19, 20)

 1. Bá a ṣé ń kọ́ àgùntàn Jèhófà

  À ń láyọ̀ pé wọ́n ń dàgbà.

  À ń rọ́wọ́ rẹ̀ bó ṣe ń darí wọn

  Wọ́n ń sòótọ́ di tara wọn.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà, gbọ́ àdúrà wa

  Jọ̀ọ́ f’àbò rẹ bò wọ́n Baba.

  Lórúkọ Jésù, a bẹ̀ ọ́: Kí wọ́n yege;

  Kí gbogbo wọn lè dúró gbọn-in.

 2. ‘Joojúmọ́ là ń gbàdúrà fún wọn,

  Kí ‘gbàgbọ́ wọn má ṣe yẹ̀.

  À ń kọ́ wọn, a sì ń ṣìkẹ́ wọn;

  Wọ́n ń lókun, Jáà ń bù kún wọn.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà, gbọ́ àdúrà wa

  Jọ̀ọ́ f’àbò rẹ bò wọ́n Baba.

  Lórúkọ Jésù, a bẹ̀ ọ́: Kí wọ́n yege;

  Kí gbogbo wọn lè dúró gbọn-in.

 3. Jọ̀ọ́ jẹ́ kí wọ́n máa gbẹ́kẹ̀ lé ọ,

  Ìwọ àti Ọmọ rẹ.

  Pẹ̀lú ‘fa-radà àtìgbọràn,

  Kí wọ́n lè jogún ìyè.

  (ÈGBÈ)

  Jèhófà, gbọ́ àdúrà wa

  Jọ̀ọ́ f’àbò rẹ bò wọ́n Baba.

  Lórúkọ Jésù, a bẹ̀ ọ́: Kí wọ́n yege;

  Kí gbogbo wọn lè dúró gbọn-in.