Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ORIN 94

A Mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Yan Àtẹ́tísí
A Mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

(Fílípì 2:16)

 1. 1. Jèhófà Bàbá wa, jọ̀ọ́ gba ọpẹ́ wa.

  A mọrírì Ìwé Mímọ́ tó o fún wa!

  Òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ rẹ;

  Ó máa ń tọ́ wa sọ́nà.

  Ó dà bí ìmọ́lẹ̀, ó ń jẹ́ ká róòótọ́.

 2. 2. Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ máa ń wọni lọ́kàn.

  Ó máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́.

  Òfin rẹ ṣe kedere,

  ìdájọ́ rẹ wúlò.

  Àwọn ìlànà rẹ sì máa ń darí wa.

 3. 3. Ọ̀rọ̀ rẹ ṣàǹfààní, ó ń wọ̀ wá lọ́kàn.

  Èèyàn bíi tiwa ni àwọn wòlí ì rẹ.

  Jẹ́ ká tẹ̀ lápẹẹrẹ wọn;

  káwa náà nígbàgbọ́.

  A dúpẹ́ Jèhófà, fún ẹ̀bùn ńlá yìí!