ORIN 80
‘Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà’
-
1. Ayọ̀ tá a ní kò láfiwé;
A láǹfààní láti wàásù.
Tọkàntọkàn ni ká fi ṣiṣẹ́ náà
Ká lè ráwọn ẹni yíyẹ.
(ÈGBÈ)
Tọ́ ọ wò, kó o sì rí adùn rẹ̀ pé
Jèhófà jẹ́ni rere.
Bá a ṣe ń fọkàn sin Ọlọ́run wa,
Ó ń bù kún ìsapá wa.
-
2. A mọyì àwọn ará wa
Tó jẹ́ alákòókò kíkún.
Ọ̀pọ̀ ìbùkún ń dúró de àwọn
Tó fara síṣẹ́ Jèhófà.
(ÈGBÈ)
Tọ́ ọ wò, kó o sì rí adùn rẹ̀ pé
Jèhófà jẹ́ni rere.
Bá a ṣe ń fọkàn sin Ọlọ́run wa,
Ó ń bù kún ìsapá wa.
(Tún wo Máàkù 14:8; Lúùkù 21:2; 1 Tím. 1:12; 6:6.)