Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ORIN 71

Ọmọ Ogun Jèhófà Ni Wá

Yan Àtẹ́tísí
Ọmọ Ogun Jèhófà Ni Wá

(Éfésù 6:11-14)

 1. 1. Ọmọ ogun Jáà ni wá;

  Kristi lọ̀gá wa.

  Bí Èṣù tiẹ̀ ń ta kò wá,

  A wà ní ìṣọ̀kan.

  À ń jọ́sìn tọkàntọkàn;

  À ń wàásù fáyé.

  A sì ti pinnu pé

  A kò ní bẹ̀rù.

  (ÈGBÈ)

  Ọmọ ogun Jáà ni wá.

  À ń tẹ̀ lé Kristi.

  À ń fayọ̀ kéde pé

  ’Jọba Rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.

 2. 2. Jèhófà là ńṣiṣẹ́ sìn

  Bá a ṣe ń wá àwọn

  Àgùntàn rẹ̀ tó sọ nù,

  Tó sì fọ́n káàkiri.

  A fẹ́ ṣèrànwọ́ fún wọn,

  Ká sì tọ́jú wọn.

  A máa ń pè wọ́n wá sí

  Gbọ̀ngàn Ìjọba.

  (ÈGBÈ)

  Ọmọ ogun Jáà ni wá.

  À ń tẹ̀ lé Kristi.

  À ń fayọ̀ kéde pé

  ’Jọba Rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.

 3.  3. Àwa lọmọ ogun Jáà

  Tí Kristi ń darí.

  Gbogbo wa ti gbára dì;

  A ti wà ní sẹpẹ́.

  Ó yẹ ká wà lójúfò,

  Ká sì dúró gbọn-in.

  Tí àtakò bá dé,

  Ká jẹ́ olóòótọ́.

  (ÈGBÈ)

  Ọmọ ogun Jáà ni wá.

  À ń tẹ̀ lé Kristi.

  À ń fayọ̀ kéde pé

  ’Jọba Rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.