Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 64

À Ń Fayọ̀ Ṣe Iṣẹ́ Ìkórè Náà

À Ń Fayọ̀ Ṣe Iṣẹ́ Ìkórè Náà

(Mátíù 13:1-23)

 1. 1. Àǹfààní àláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́

  Pé ìgbà ‘kórè la wà yìí.

  Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀, ká bọ́ sí pápá,

  Ká sì sa gbogbo ipá wa.

  Torí pé Kristi wà pẹ̀lú wa,

  Tó ń darí iṣẹ́ tá à ń ṣe yìí,

  Èyí ń fún wa láyọ̀ lójoojúmọ́,

  Ọlá ńlá ló sì jẹ́ fún wa.

 2. 2. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run

  Àtàwọn aládùúgbò wa,

  Ó ń mú ká tẹra mọ́ ìwàásù,

  Torí òpin ti sún mọ́lé.

  À ń láyọ̀ bí a ṣe ńṣiṣẹ́ yìí;

  Jèhófà ló ń fún wa láyọ̀.

  A ó fìgbàgbọ́ fara dà á dé òpin,

  A ó sì máa fayọ̀ bá a ṣiṣẹ́.