Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ORIN 54

“Èyí Ni Ọ̀nà”

Yan Àtẹ́tísí
“Èyí Ni Ọ̀nà”

(Àìsáyà 30:​20, 21)

 1. 1. Ọ̀nà kan wà tó ti

  Wà lọ́jọ́ tó ti pẹ́.

  Jésù sọ nípa rẹ̀

  Nígbà tó wá sáyé.

  Mo kẹ́kọ̀ọ́, mo sì ti

  Wá mọ ọ̀nà yìí gan-an.

  Ọ̀nà àlàáfíà yìí

  Wà nínú Bíbélì.

  (ÈGBÈ)

  Ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun nìyí.

  Tẹsẹ̀ mọ́rìn, má ṣe wọ̀tún-wòsì!

  Jèhófà ń sọ pé: ‘Má yà kúrò;

  Má ṣe wẹ̀yìn, ojú ọ̀nà lo wà.’

 2. 2. Ọ̀nà ìfẹ́ lo wà,

  Má ṣe wọ̀tún-wòsì.

  Bíbélì fi hàn pé

  Jèhófà jẹ́ ìfẹ́.

  Ìfẹ́ tó dára, tó

  Jinlẹ̀ ló ní sí wa.

  Ọ̀nà tí à ń sọ yìí

  Kan ìgbé ayé wa.

  (Ègbè)

  Ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun nìyí.

  Tẹsẹ̀ mọ́rìn, má ṣe wọ̀tún-wòsì!

  Jèhófà ń sọ pé: ‘Má yà kúrò;

  Má ṣe wẹ̀yìn, ojú ọ̀nà lo wà.’

 3.  3. Ọ̀nà ìyè la wà,

  Má ṣe bojú wẹ̀yìn.

  Kò sí ibòmíràn

  Tá a lè lọ, tá a lè rí

  Àlàáfíà àtìfẹ́

  Tí Jáà ṣèlérí rẹ̀.

  Ọ̀nà ìyè nìyí,

  Ọpẹ́ yẹ Jèhófà.

  (Ègbè)

  Ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun nìyí.

  Tẹsẹ̀ mọ́rìn, má ṣe wọ̀tún-wòsì!

  Jèhófà ń sọ pé: ‘Má yà kúrò;

  Má ṣe wẹ̀yìn, ojú ọ̀nà lo wà.’