Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ORIN 30

Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi

Yan Àtẹ́tísí
Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi

(Hébérù 6:10)

 1. 1. Ìnira pọ̀ gan-an láyé.

  Ó ń fa ẹkún àti ìrora.

  Ṣùgbọ́n mo mọ̀ dájú pé,

  “Asán kọ́ layé mi.”

  (ÈGBÈ)

  Olóòótọ́ ni Jèhófà.

  Kò ní gbàgbé iṣẹ́ ìsìn mi.

  Yóò sì máa wà pẹ̀lú mi,

  Kò ní fi mí sílẹ̀ láéláé.

  Jèhófà l’aláàbò mi,

  aláàánú àti olùpèsè.

  Bàbá mi ni, Ọ̀rẹ́ mi ni,

  Ọlọ́run mi.

 2. 2. Ìgbà ọ̀dọ́ mi ti lọ.

  Ọjọ́ ogbó ti wá ńdé báyìí.

  Síbẹ̀, mo nígbàgbọ́ pé

  Ìrètí mi dájú.

  (ÈGBÈ)

  Olóòótọ́ ni Jèhófà.

  Kò ní gbàgbé iṣẹ́ ìsìn mi.

  Yóò sì máa wà pẹ̀lú mi,

  Kò ní fi mí sílẹ̀ láéláé.

  Jèhófà l’aláàbò mi,

  aláàánú àti olùpèsè.

  Bàbá mi ni, Ọ̀rẹ́ mi ni,

  Ọlọ́run mi.

(Tún wo Sm. 71:17, 18.)