Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 3

Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

(Òwe 14:26)

 1. 1. A ní ìrètí iyebíye

  tí à ń sọ fáráyé.

  Ìrètí tó ń mórí wa wú,

  lo fún wa, Jèhófà.

  Ṣùgbọ́n tíṣòro bá ti pọ̀ jù,

  ṣe nìbẹ̀rù máa ń bò wá.

  Ìrètí wa tó lágbára

  sì lè wá máa kú lọ.

  (ÈGBÈ)

  Agbára wa àti

  Olùpèsè wa;

  A gbọ́kàn lé ọ, Jèhófà.

  À ń wàásù, à ń kọ́ni,

  ọkàn wa balẹ̀

  Torí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.

 2. 2. Jọ̀ọ́, Jèhófà Olùtùnú wa,

  Jẹ́ ká máa rántí pé,

  Gbogbo ìgbà tá a níṣòro

  lo máa ń tù wá nínú.

  Èyí ló sì mú ká lókun gan-an

  tírètí wa fi ń sọjí;

  Tá a fi lè fìgboyà sọ̀rọ̀

  nípa orúkọ rẹ.

  (ÈGBÈ)

  Agbára wa àti

  Olùpèsè wa;

  A gbọ́kàn lé ọ, Jèhófà.

  À ń wàásù, à ń kọ́ni,

  ọkàn wa balẹ̀

  torí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.