Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ORIN 17

“Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”

Yan Àtẹ́tísí
“Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”

(Lúùkù 5:13)

 1. 1. Ọmọ Ọlọ́run wá sáyé

  Láti fẹ̀rí hàn pó fẹ́ wa.

  Ó fi ọ̀run sílẹ̀

  Ká lè rígbàlà,

  Ó fẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa.

  Aláàánú ni Jésù Kristi,

  Ó fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀.

  Ẹ̀rí fi hàn pé onínúure ni

  Nígbà tó sọ pé, “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.”

 2. 2. Àǹfààní ńlá lèyí fún wa

  Pá a lè tẹ̀ lápẹẹrẹ Jésù;

  Ká jẹ́ onínúure,

  Ká máa fìfẹ́ hàn,

  Ní ojoojúmọ́ ayé wa.

  Táwọn opó bá wá bá ọ

  Tàbí àwọn tó sorí kọ́,

  Fẹ̀rí hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn dénú;

  Kíwọ náà sọ pé, “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.”