Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ORIN 109

Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá

Yan Àtẹ́tísí
Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá

(1 Pétérù 1:22)

 1. 1. Jèhófà lorísun ìfẹ́.

  Bí a bá ń fẹ́ni látọkàn,

  A ó mú ọkàn rẹ̀ yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀;

  Ìyẹn ṣeyebíye.

  Bíjì bá ń jà, tílé sì ńjó,

  Ìfẹ́ ará wa ń gbèrú sí i.

  A kò ní fi wọ́n sílẹ̀ láé;

  A nífẹ̀ẹ́ wọn dọ́kàn.

  Bí a bá ń báni kẹ́dùn,

  T áa fúnni lókun nígbà ‘ṣòro,

  Ọ̀rẹ́ àìṣẹ̀tàn nìyẹn,

  Elétí bánigbọ́rọ̀.

  Bí Jésù sì ṣe nífẹ̀ẹ́ wa

  Fi ànímọ́ Jèhófà hàn.

  Àwa náà lè máa fìfẹ́ hàn

  Lọ́nà tó dára jù lọ;

  Ká nífẹ̀ẹ́ látọkàn wá.