Màá Dúró Tì Ẹ́
Wà á Jáde:
1. Láìròtẹ́lẹ̀,
Nǹkan lè dédé yí pa dà.
Nígbà míì, ohun tí a kò retí
Lè ṣàdédé ṣẹlẹ̀ sí wa.
Àmọ́ Baba ń rí wa;
Ó mọ̀ wá ju bá a ṣe rò lọ.
Ó mẹni tá a jẹ́, ó sì máa ń rọ́kàn wa.
Ká má ṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
(ÌṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Ó fẹ́ràn gbogbo wa,
Ẹ̀bùn àbínibí yòówù kí a ní.
Ó fẹ́ kí gbogbo wa
Máa fìfẹ́ hàn sí ara wa.
(ÈGBÈ)
O ṣeun ọ̀rẹ́, kú àdúrótì
Ní ìgbà dídùn àtìgbà kíkan.
Èmi náà
Máa dúró tì ẹ́ tíṣòro bá yọjú.
A jọ wà fúnra wa.
Fọkàn ẹ balẹ̀.
2. Tẹ́lẹ́kún bá ń sunkún,
Ṣe ló yẹ ká bá wọn sunkún.
Nígbà míì, tá ò bá mohun tá a máa sọ,
Ẹkún tá a bá sun náà ti tó.
(ÌṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Tí ìṣòro bá dé.
Ó dájú pé Jèhófà máa ṣèrànwọ́.
Káwa náà fara wé e,
Ká máa ran ara wa lọ́wọ́.
(ÈGBÈ)
O ṣeun ọ̀rẹ́, kú àdúrótì
Ní ìgbà dídùn àtìgbà kíkan.
Èmi náà
Máa dúró tì ẹ́ tíṣòro bá yọjú.
A jọ wà fúnra wa.
Fọkàn ẹ balẹ̀.
(ÈGBÈ)
O ṣeun ọ̀rẹ́, kú àdúrótì
Ní ìgbà dídùn àtìgbà kíkan.
Èmi náà
Máa dúró tì ẹ́ tíṣòro bá yọjú.
A jọ wà fúnra wa.
Fọkàn ẹ balẹ̀.

