Mi Ò Ní Kúrò Lọ́nà Ìyè
Wà á jáde:
1. Kò rọrùn fún ọ̀dọ̀ bíi tèmi
Láti ṣèpinnu tó dáa.
Báwo ni ayé mi ṣe máa nítumọ̀?
Àwọn nǹkan yìí gbà mí lọ́kàn.
(ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Sùgbọ́n ó dájú pé
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi.
Á ràn mí lọ́wọ́,
Kí n lè ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́.
(ÈGBÈ)
Ọ̀rọ̀ rẹ ń tọ́ mi sọ́nà ìyè.
Ọlọ́run mi wà pẹ̀lú mi, mo mọ̀.
Mi ò ní kúrò lọ́nà ìyè tòótọ́.
2. Àwọn nǹkan wà tọ́kàn mi ń fà sí,
Tí mo mọ̀ pé kò dáa.
Mo wá bẹ Jèhófà kó ràn mí lọ́wọ́.
Kí n má kúrò lọ́nà ìyè.
(ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́,
Tó nífẹ̀ẹ́ mi dénú
L’Ọlọ́run fi kẹ́ mi;
Wọn kò ní dá mi dá ìṣòro mi.
(ÈGBÈ)
Ọ̀rọ̀ rẹ ń tọ́ mi sọ́nà ìyè.
Ọlọ́run mi wà pẹ̀lú mi, mo mọ̀.
Mi ò ní kúrò lọ́nà ìyè tòótọ́.
(ÀSOPỌ̀)
Mi ò ní wọ̀tún, mi ò ní wòsì.
Màá dúró sọ́nà tó lọ síyè àìnípẹ̀kun.
(ÈGBÈ)
Ọ̀rọ̀ rẹ ń tọ mi sọ́nà ìyè.
Ọlọ́run mi wà pẹ̀lú mi, mo mọ̀.
Mi ò ní kúrò lọ́nà ìyè tòótọ́.
Títí ayé mi.

