ÀWỌN ORIN WA MÍÌ

Kò Ní Pẹ́ Mọ́

Yorùbá
Kò Ní Pẹ́ Mọ́
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/1014399/univ/art/1014399_univ_sqr_xl.jpg

Kò Ní Pẹ́ Mọ́

Kò Ní Pẹ́ Mọ́

Wà á jáde:

  1. 1. Ìgbà kan wà tí mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́

    Àmọ́ ní báyìí, ìrora mi pọ̀ gan-an.

    Ó dájú, kò ní pẹ́ mọ́.

    Àwọn èèyàn mi kan wà tó ti kú.

    Ẹ̀dùn ọkàn mi ti fẹ́ bò mí mọ́lẹ̀

    Ó dájú, kò ní pẹ́ mọ́.

    (ÈGBÈ)

    Mò ń ronú nípa bí ayé tuntun ṣe máa rí

    Ìjọba Ọlọ́run yóò mú kí àlàáfíà wà ní ayé

    Kò ní pẹ́ mọ́.

    Kò ní sẹ́kún àti ìrora

    Mo sì tún ma kí àwọn òkú káàbọ̀ sí Párádísè

    Ìfẹ́ Jáà yóò ṣẹ láyé

    Kò ní pẹ́ mọ́.

  2. 2. Ayé Èṣù yíì kò ní pẹ́ kọjá lọ

    Ojoojúmọ́ ni òpin ń sún mọ́lé

    Ó dájú, kò ní pẹ́ mọ́.

    Ohun t’Ọlọ́run bá fẹ́ ni màá ṣe

    Òun ni màá fi gbogbo ayé mi sìn

    Ó dájú, kò ní pẹ́ mọ́.

    (ÈGBÈ)

    Mò ń ronú nípa bí ayé tuntun ṣe máa rí

    Ìjọba Ọlọ́run yóò mú kí àlàáfíà wà ní ayé

    Kò ní pẹ́ mọ́.

    Kò ní sẹ́kún àti ìrora

    Mo sì tún máa kí àwọn òkú káàbọ̀ sí Párádísè

    Ìfẹ́ Jáà yóò ṣẹ láyé

    Kò ní pẹ́ mọ́.

    (ÀSOPỌ̀)

    Bí mo tiẹ̀ kú kópin tó dé, Ọkàn mi balẹ̀ pé

    Jèhófà Bàbá mi Kò ní gbàgbé mi láéláé.

    (ÈGBÈ)

    Mò ń ronú nípa bí ayé tuntun ṣe máa rí

    Ìjoba Ọlọ́run yóò mú kí àlàáfíà wà ní ayé

    Kò ní pẹ́ mọ́

    Kò ní sẹ́kún àti ìrora

    Àwọn tẹbí-tọ̀rẹ́ yóò kí mi káàbọ̀ sí Párádísè

    Ìfẹ́ Jáà yóò ṣẹ láyé.

    A ò ní máa kú mọ́.

    Kò ní pẹ́ mọ́.