ÀWỌN ORIN WA MÍÌ

Ká Nítẹ̀ẹ́lọ́rùn

Yorùbá
Ká Nítẹ̀ẹ́lọ́rùn
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/1014397/univ/art/1014397_univ_sqr_xl.jpg

Ká Nítẹ̀ẹ́lọ́rùn

Ká Nítẹ̀ẹ́lọ́rùn

Wà á jáde:

  1. 1. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni èèyàn máa ń fẹ́

    Díẹ̀ sì ni ohun tí a nílò

    Ó yẹ ká sọ́ra kóhun tá a ní

    Má tún wá di ‘dẹkùn fún wa.

    (ÈGBÈ)

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn

    Jèhófà mohun tá a nílò

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn A máa láyọ̀

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn

    Ká lè nífọ̀kànbalẹ̀

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn A máa láyọ̀.

  2. 2. Tí a bá ti rílé gbé

    Tá a láṣọ, tá a sì lóúnjẹ

    Táwọn nǹkan yìí bá tẹ́ wa lọ́rùn,

    Á jẹ́ ká ní àlàáfíà.

    (ÈGBÈ)

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn

    Jèhófà mohun tá a nílò

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn A máa láyọ̀

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn

    Ká lè nífọ̀kànbalẹ̀

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn A máa láyọ̀.

    (ÀSOPỌ̀)

    Ọlọ́run ti ṣèlérí

    Pé òun máa bójú tó wa.

    Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an

    Ó mọ ohun tá a nílò.

    Ẹ jẹ́ ká gbọ́kàn lé e.

  3. 3. Tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn láyé wa

    Ara máa tù wá, a sì máa láyọ̀.

    Á jẹ́ ká lè ṣèfẹ́ Jèhófà,

    Jèhófà sì máa bù kún wa.

    (ÈGBÈ)

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn

    Jèhófà mohun tá a nílò

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn A máa láyọ̀

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn

    Ká lè nífọ̀kànbalẹ̀

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn.

    (ÈGBÈ)

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn

    Jèhófà mohun tá a nílò

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn A máa láyọ̀

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn

    Ká lè nífọ̀kànbalẹ̀

    Ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn A máa láyọ̀.