Jẹ́ Kí Wọ́n Mọ̀ Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn
Wà á jáde:
1. Àwọn tó o nífẹ̀ẹ́ ní láti mọ̀
Pé o nífẹ̀ẹ́ wọn látọkàn wá.
Ọ̀rọ̀ rere ni kó jáde lẹ́nu rẹ
Tó lè mú kínú wọn máa dùn.
(ÈGBÈ)
Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.
Máa sọ fún wọn pé o fẹ́ràn wọn.
Bó o ṣe ń sọ fún wọn, Kí o tún máa fi hàn
Nínú ìwà tó ò ń hù pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.
2. Láwọn ìgbà míì, ó lè ṣòro fún ẹ
Láti mọ bó o ṣe lè fìfẹ́ hàn.
Má ṣe gbàgbé pé wọ́n ní láti mọ̀
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ pó o nífẹ̀ẹ́ wọn.
(ÈGBÈ)
Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.
Máa sọ fún wọn pé o fẹ́ràn wọn.
Bó o ṣe ń sọ fún wọn, Kí o tún máa fi hàn
Nínú ìwà tó ò ń hù pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.
Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.
Máa sọ fún wọn pé o fẹ́ràn wọn.
Bó o ṣe ń sọ fún wọn, Kí o tún máa fi hàn
Nínú ìwà tó ò ń hù pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.
(ÀSOPỌ̀)
Nígbà tí Jésù gbóhùn Bàbá rẹ̀
Pé òun ni àyànfẹ́ tó tẹ́wọ́ gbà,
Inú Jésù dùn gan-an, bó tiẹ̀ jẹ́ pó mọ̀.
Èyí fún un lókun!
(ÈGBÈ)
Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.
Máa sọ fún wọn pé o fẹ́ràn wọn.
Bó o ṣe ń sọ fún wọn, kí o tún máa fi hàn.
Jẹ́ kí wọ́n máa mọ̀ pé ò ń ronú nípa wọn.
Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.
Máa sọ fún wọn pé o fẹ́ràn wọn.
Bó o ṣe ń sọ fún wọn, Kí o tún máa fi hàn
Nínú ìwà tó ò ń hù pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.

