Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà
Wà á jádé:
1. Ìṣòro tó pọ̀ láyé yìí ń kó ìdààmú bá ọ̀pọ̀ èèyàn.
Mo máa ń pàdé àwọn tára ń kan toránìíyàn ayé.
Ti wọ́n bá fẹ́ mú kí n gbaná jẹ́, mo máa ń gbàdúrà pé:
‘Jèhófà jọ̀wọ́, fún mi ní sùúrù, kí n kápá ìbínú mi.’
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ìyẹn ni ó dára jù.
Ìyẹn máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbé pẹ̀lú ìṣọ̀kan ní Párádísè!
2. Lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa náà, a tún ń fìwà tútù hàn.
Wọ́n lè bú wa, wọ́n lè fẹ́ jà, ṣùgbọ́n a kò gbaná jẹ́.
Ó lè jẹ́ ‘ṣòro tí wọ́n ń dojú kọ ló mú wọn ṣìwà hù.
Tí a bá ní sùúrù, a lè wá rí i pé èèyàn dáadáa ni wọ́n jẹ́
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ìyẹn ni ó dára jù.
Ìyẹn máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbé pẹ̀lú ìṣọ̀kan ní Párádísè!
(ÀSOPỌ̀)
Ó nira gan-an láyé yìí,
Láti j’ẹlẹ́mìí àlàáfíà.
Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà,
Yóò jẹ́ ká lè ṣàṣeyọrí.
3. Ní òpin ọ̀sẹ̀, a jáde pé ká lọ wàásù ìhìn rere.
Lẹni tó kórìíra Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá fẹ́ gbé ìjà kò wá.
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la ṣe ohun tí Bíbélì rọ̀ wá pé ká ṣe.
“Kí ìjà tó bẹ́,” a kúrò níbẹ̀, a sì lọ ní àlàáfíà.