Jèhófà Ṣèlérí “Ìyè Tòótọ́”
Wà á jáde:
1. Bí mo ṣe ń ronú páyé tuntun ń bọ̀, Ṣe ló kàn ń múnú mi dùn!
Ìgbà ọ̀tun dé, kò sí ìbẹ̀rù mọ́.
Ìyẹn ni ìyè tòótọ́.
Jèhófà ṣí ọwọ́ rẹ̀, ó sì tẹ́ wa lọ́rùn.
Kò síkú àti ọ̀fọ̀ mọ́. Ayé di tuntun!
(ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Àmọ́ ṣá, àfi ká ní sùúrù.
(ÈGBÈ)
Lọ́jọ́ náà, a óò gbóhùn ayọ̀ wa sókè, Táyé tuntun bá dé.
Jèhófà ṣèlérí ìyè tòótọ́, Baba kì í parọ́.
Olóòótọ́ ni!
2. Mo mọ̀ wí pé táyé tuntun bá dé. Iṣẹ́ máa pọ̀ láti ṣe.
Àwọn òkú máa tún pa dà wà láàyè. A ó fi ìfẹ́ tọ́jú wọn.
Kò ní sẹ́kún ìbànújẹ́, ẹkún ayọ̀ ni.
Ìrètí yìí ń múnú mi dùn. Ó sì ti dé tán.
(ÈGBÈ)
Lọ́jọ́ náà, a óò gbóhùn ayọ̀ wa sókè, Táyé tuntun bá dé.
Jèhófà ṣèlérí ìyè tòótọ́, Baba kì í parọ́.
Olóòótọ́ ni!
(ÀSOPỌ̀)
Bí mo ṣe ń ronú nípa ìlérí yìí. Ọkàn mi balẹ̀ gan-an.
Ìyè tòótọ́ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ dé, ó dé tán.
(ÈGBÈ)
Lọ́jọ́ náà, a óò gbóhùn ayọ̀ wa sókè, táyé tuntun bá dé.
Jèhófà ṣèlérí ìyè tòótọ́, Baba kì í parọ́!
(ÈGBÈ)
Lọ́jọ́ náà, a óò gbóhùn ayọ̀ sókè, Táyé tuntun bá dé.
Jèhófà ṣèlérí ìyè tòótọ́, Baba kì í parọ́.
Olóòótọ́ ni!
(ÌPARÍ)
Ayé máa di tuntun
Ó dájú.
Ayé máa di tuntun.
Ó dájú.
Ayé máa di tuntun
Ó dájú.
Ayé máa di tuntun
Ó dájú.

