ÀWỌN ORIN WA MÍÌ

Ilé Mi

Yorùbá
Ilé Mi
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/1014380/univ/art/1014380_univ_sqr_xl.jpg

Ilé Mi

Ilé Mi

Wà á jáde:

  1. 1. Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

    Àmọ́ láwọn ìgbà kan.

    Ìṣòro tí mo ní

    Mú kí n yẹsẹ̀ kúrò lọ́nà ìyè.

    Mo mọ̀ pó yẹ kí n ṣàtúnṣe

    Bàbá, jọ̀ọ́ mo fẹ́ pa dà wálé.

    (ÈGBÈ)

    Ó wá mi, ó tún fìfẹ́ hàn mí.

    Ó sì yọ mí kúrò nínú ewu

    Jèhófà ti mú mi pa dà wá sí ilé mi

    Ọkàn mi ti balẹ̀. Mo dúpẹ́.

  2. 2. Ètò Jèhófà dùn!

    Ọ̀nà ìyè la wà yìí.

    A máa ń gbéra wa ró.

    Jèhófà kò fẹ́ kẹ́nì kankan ṣègbé.

    Tó o bá ti yẹsẹ̀ lọ́nà ìyè,

    Bẹ Jèhófà pó o fẹ́ pa dà wálé.

    (ÈGBÈ)

    Yóò wá ẹ, yóò fìfẹ́ hàn sí ẹ.

    Yóò fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀ lọ́nà ìyè.

    Jèhófà Bàbá rẹ yóò fìfẹ́ fa ẹ́ mọ́ra.

    Ọkàn rẹ máa balẹ̀, wàá láyọ̀.

    (ÀSOPỌ̀)

    Gbogbo wa pátá la nífẹ̀ẹ́ rẹ, kú ààbọ̀.

    Inú wa dùn gan-an pé o ti pa dà wá sílé

    Kú ààbọ̀.

    Kú ààbọ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ó wá ẹ, ó tún fìfẹ́ hàn sí ẹ.

    Ó sì yọ ẹ́ kúrò nínú ewu.

    Ó fìfẹ́ fà ẹ́ mọ́ra.

    Yóò sì máa bójú tó ẹ.

    Kú ààbọ̀.