Yorùbá
Ẹ Káre, Ẹ̀yin Arábìnrin Wa!
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/502900119/univ/art/502900119_univ_sqr_xl.jpg

Ẹ Káre, Ẹ̀yin Arábìnrin Wa!

Ẹ Káre, Ẹ̀yin Arábìnrin Wa!

Wà á jáde:

  1. 1. Ó wù mí láti kọ orin kan fún yín.

    Ó sì wù mí kí ẹ máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo.

    Mo fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé, ẹ̀ ń múnú wa dùn.

    Bí ẹ ṣe ń fòótọ́ ọkàn sin Jáà ń mórí wa wú.

    (ṢÁÁJÚ-ÈGBÈ)

    Tẹ́ ẹ bá rẹ̀wèsì,

    A fẹ́ kẹ́ ẹ máa rántí ọ̀rọ̀ orin yìí.

    (ÈGBÈ)

    Òṣìṣẹ́ kára

    Ni ẹ̀yin arábìnrin wa.

    A kò lè gbàgbé

    Iṣẹ́ aláyọ̀ tí ẹ̀ ń ṣe.

    Tó bá jẹ́ pẹ́ ẹ lè rọ́kàn wa, ẹ máa rí i

    Pẹ́ni ọ̀wọ́n lẹ jẹ́ sí wa.

    A mọyì yín gan-an.

  2. 2. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere lẹ̀ ń ṣe tí a kò rí.

    Ẹ̀ ń bójú tó ilé ẹ tún ń wáyè fáwọn ará.

    Ìfẹ́ àtọkànwá yín hàn kedere.

    A mọyì àwọn iṣẹ́ rere yín, ó ń gbé wa ró.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Àpẹẹrẹ rere ni ẹ jẹ́ fún gbogbo wa.

    A mọrírì yín.

    (ÈGBÈ)

    Òṣìṣẹ́ kára

    Ni ẹ̀yin arábìnrin wa.

    A kò lè gbàgbé

    Iṣẹ́ aláyọ̀ tí ẹ̀ ń ṣe.

    Tó bá jẹ́ pẹ́ ẹ lè rọ́kàn wa, ẹ máa rí i

    Pẹ́ni ọ̀wọ́n lẹ jẹ́ sí wa.

    A mọyì yín gan-an.

    (ÀSOPỌ̀)

    Jèhófà mọyì iṣẹ́ yín.

    Kò fẹ́ kẹ́ ẹ ṣe ju ohun tẹ́ ẹ lè ṣe.

    Ó mohun tágbára yín gbé.

    (ÈGBÈ)

    Òṣìṣẹ́ kára

    Ni ẹ̀yin arábìnrin wa.

    A kò lè gbàgbé

    Iṣẹ́ aláyọ̀ tí ẹ̀ ń ṣe.

    Tó bá jẹ́ pẹ́ ẹ lè rọ́kàn wa, ẹ máa rí i

    Pẹ́ni ọ̀wọ́n lẹ jẹ́ sí wa.

    A mọyì yín gan-an.

    (ÌPARÍ)

    Ẹ káre! Ẹ máa fayọ̀ ṣiṣẹ́ yín lọ. Ẹ káre!

    A mọrírì yín láàárin wa. Ẹ káre!

    A nífẹ̀ẹ́ yín gan-an. Ẹ káre, ẹ́ káre, ẹ káre.

    A nífẹ̀ẹ́ yín.

    A mọyì yín gan-an!

    A mọyì yín gan-an!