Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà (àwọn orin wa míì)

Mọ Àwọn Ìwé Bíbélì Lórí (Apá 3)

Yorùbá
Mọ Àwọn Ìwé Bíbélì Lórí (Apá 3)
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/502016182/univ/art/502016182_univ_sqr_xl.jpg
pkon

Mọ Àwọn Ìwé Bíbélì Lórí (Apá 3)

Mọ Àwọn Ìwé Bíbélì Lórí (Apá 3)

Wà á jáde:

  1. 1. Mátíù—Jésù wá sáyé, ó kọ́ gbogbo wa.

    Máàkù—Ọmọ Ọlọ́run ṣiṣẹ́ ìyanu.

    Lúùkù—Jésù sọ̀tàn tó kọ́ wa ní ẹ̀kọ́.

    Jòhánù—Bíi Lásárù, òkú lè jí dìde.

    Ìṣe—Bíṣẹ́ ìwàásù ṣe dé gbogbo ayé.

    Róòmù—Báàánú Ọlọ́run ṣe kan gbogbo wa.

    Kọ́ríńtì Kìíní—Ó kọ́ wa lóhun tífẹ̀ẹ́ tòótọ́ jẹ́.

    Kọ́ríńtì Kejì—Ọlọ́run fẹ́ ká máa dárí jini.

    Gálátíà—Máa ṣe rere, má sì jẹ́ kó sú ẹ.

    Éfésù—Ó kọ́ wa bó ṣe yẹ kídìílé rí.

    Fílípì—Máa ṣohun tó tọ́, tó sì tún dára.

    Kólósè—A máa láyọ̀ tá a bá ń ṣègbọràn.

    Tẹsalóníkà Kìíní—Níbikíbi, nígbà gbogbo la lè gbàdúrà.

    Tẹsalóníkà Kejì—Jèhófà máa ń dúró tàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.

    Tímótì Kìíní—Kékeré ló ti mọ Ìwé Mímọ́.

    Tímótì Kejì—Ó fi ìgboyà ran ìjọ lọ́wọ́.

    Títù—Ó yẹ ká fìfẹ́ hàn sáwọn alàgbà.

    Fílémónì—Ẹrú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ wá di Kristẹni.

    Hébérù—Ó yẹ ká máa lọ sípàdé déédéé.

    Jákọ́bù—Gbogbo ẹ̀bùn rere wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

    Pétérù Kìíní—A gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lápẹẹrẹ Kristi.

    Pétérù Kejì—Jáà fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ jẹ́ mímọ́.

    Jòhánù Kìíní—Ìgbọràn fi hàn pá a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.

    Jòhánù Kejì—Fi tọkàntọkàn rìn lọ́nà òtítọ́.

    Jòhánù Kẹta—Ẹ máa ní ẹ̀mí aájò àlejò.

    Júúdà—Má gb’Èṣù láyè, máa ṣohun tó tọ́.

    Ìṣípayá—Bí ayé ṣe máa di Párádísè.

    (ÈGBÈ)

    Bíbélì nìwé tó dára jù lọ.

    Jèhófà ló mí sí àwọn tó kọ ọ́.

    Máa kà á lójoojúmọ́, kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ṣègbọràn.

    Bíbélì nìwé tó dára jù lọ.