Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà (àwọn orin wa míì)

Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Àgbàlagbà

Yorùbá
Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Àgbàlagbà
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/502015269/univ/art/502015269_univ_sqr_xl.jpg
pkon

Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Àgbàlagbà

Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Àgbàlagbà

Wà á jáde:

  1. 1. Màá tẹ́tí sáwọn àgbàlagbà,

    Kí n kẹ́kọ̀ọ́ lára yín.

    Mo fẹ́ máa gbọ́ nípa àwọn nǹkan

    Tójú yín ti rí láyé:

    Gbogbo ibi tẹ́ ẹ ti dé

    Àtàwọn tẹ́ ẹ ti ràn lọ́wọ́

    Àti bí ẹ ṣe fòótọ́ sìn

    Nígbà tẹ́ ẹ wà lọ́dọ̀ọ́.

    Tọkàntọkàn lẹ fi ń sin Jáà,

    Ẹ sì máa ń ṣoore fáwọn èèyàn.

    Mo wá rí i pé inú yín ń dùn;

    Ẹ ṣohun tẹ́ ẹ lè ṣe.

    Màá tẹ́tí sáwọn àgbàlagbà,

    Kí n sì bọ̀wọ̀ fún wọn.

    Tí mo bá di àgbàlagbà,

    Màá fẹ́ máa ṣe bíi tiyín.