Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ELFRIEDE URBAN | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Gbádùn Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Tí Mo Fayé Mi Ṣe

Mo Gbádùn Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Tí Mo Fayé Mi Ṣe

Wọ́n bí mi ní December 11, 1939 ní Czechoslovakia, ìyẹn oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé mi kún fún ìdààmú gan-an. Ojú màmá mi rí tóó nígbà tí wọ́n fẹ́ bí mi, ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí wọ́n bí mi ni wọ́n sì kú. Ṣáájú ìgbà yẹn ni bàbá mi ti kó lọ sí Jámánì láti lọ máa ṣiṣẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi àgbà ṣì ń tọ́ àwọn àbúrò ìyá mi mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ obìnrin, wọ́n tún gba èmi náà tọ́.

Èmi àtàwọn òbí mi àgbà

 Nǹkan nira gan-an lẹ́yìn tí ogun náà parí lọ́dún 1945. Torí pé ọmọ ìlú Jámánì ni wá, wọ́n lé wa kúrò ní Czechoslovakia, wọ́n sì dá wa pa dà sí Jámánì. Nígbà tá a fi máa débẹ̀, gbogbo ìlú ti dìdàkudà, ọ̀pọ̀ sì ti di aláìní. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn àbúrò ìyá mi máa ń fi gbogbo òru tò láti gba oúnjẹ tí kò tó nǹkan. Láwọn ìgbà míì, á máa ń lọ sínú igbó láti lọ wá olú àti àwọn èso míì tá a lè fi pààrọ̀ oúnjẹ tá a máa jẹ. Oúnjẹ wọ́n gan-an débi tí àwọn èèyàn fi ń jí àwọn ohun ọ̀sìn àwọn míì láti pa jẹ. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni a kì í jẹun sùn.

Bá A Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́

 Ẹ̀sìn Kátólíìkì ni àwọn òbí mi àgbà ń ṣe, àmọ́ a ò ní Bíbélì kankan. Bàbá àgbà wá ní kí àlùfáà ta Bíbélì kan fún wa àmọ́ ó kọ̀ jálẹ̀, ó wá sọ pé àwọn ọmọ ìjọ kò nílò rẹ̀, tiwọn ni kí wọ́n ṣáà ti tẹ́tí sílẹ̀. Ìyẹn ò jẹ́ kí bàbá àgbà rí ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí wọ́n ní nípa Ọlọ́run.

 Ọmọ ọdún méje ni mí nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá sílé wa. Wọ́n fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè bàbá àgbà lórí àwọn ọ̀rọ̀ bíi Mẹ́talọ́kan, iná ọ̀run àpáàdì àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. Wọ́n rí i pé àwọn ìdáhùn tó wà nínú Bíbélì ò lójú pọ̀ rárá, wọ́n sì bọ́gbọ́n mu. Ìyẹn mú kó dá wọn lójú pé àwọn ti rí òtítọ́. Bí gbogbo ìdílé wa ṣe gbà kí tọkọtaya kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn.

Mo Fi Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Ṣe Àfojúsùn Mi

 Àtikékeré ni mo ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ńṣe ni mo máa ń gbádùn kí n máa kà nípa àwọn míṣọ́nnárì tó ń sìn láwọn ibi tó jìnnà gan-an. Mo máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni ìgbésí ayé wọn ṣe rí? Báwo ló ṣe máa ń rí téèyàn bá wàásù fún ẹni tí ò gbọ́ orúkọ Jèhófà rí?’

Èmi rèé kí n tó pinnu pé màá fayé mi ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì

 Ọmọ ọdún méjìlá (12) ni mí nígbà tí mo pinnu pé èmi náà á di míṣọ́nnárì, ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kọ́wọ́ mi lè tẹ àfojúsùn yẹn. Ohun tí mo kọ́kọ́ ṣe ni pé, mo sapá kí n lè dẹni tó ń fìtara wàásù. Nígbà tó di December 12, 1954, mo ṣèrìbọmi, kò sì pẹ́ tí mo fi di aṣáájú-ọ̀nà. Bọ́wọ́ mi ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn àfojúsùn mi díẹ̀díẹ̀ nìyẹn.

 Mo mọ̀ dáadáa pé tí mo bá fẹ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì níbi tí wọ́n tí ń dá àwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́, ó pọndandan kí n gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ èdè náà. Mo ronú pé á dáa kí n máa bá àwọn sójà ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó wà ní Jámánì lákòókò yẹn sọ èdè náà, kó lè yọ̀ mọ́ mi lẹ́nu. Lọ́jọ́ kan, mo lọ bá sójà kan, mo sì sọ fún un pé, “Kristi ni mí.” Ó wò mí, ó sì fohùn jẹ́jẹ́ sọ fún mi pé, “Àbí ohun tó o fẹ́ sọ ni pé ‘Kristẹni ni ẹ́.’” Àṣé mi ò tíì gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì tó bí mo ṣe rò.

 Nígbà tí mo lé díẹ̀ lọ́mọ ogún ọdún, mo kó lọ sórílẹ̀-èdè England. Lárààárọ̀, mo máa ń bá ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tọ́jú ọmọ wọn, tó bá sì dọ̀sán, mo máa ń lọ wàásù láti ilé dé ilé, ìyẹn jẹ́ kí èdè Gẹ̀ẹ́sì túbọ̀ yọ̀ mọ́ mi lẹ́nu. Nígbà tí màá fi lo bí ọdún kan ní England, mo ti gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa.

 Nígbà tó yá, mo pa dà sí Jámánì. Ní October 1966, ètò Ọlọ́run sọ mi di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì rán mi lọ sílùú Mechernich. Àmọ́ àwọn tó wà lágbègbè yẹn ò nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa rárá. Láìka bí òtútù ṣe máa ń mú tó níbẹ̀, wọn kì í jẹ́ ká wọlé tá a bá wàásù dé ọ̀dọ̀ wọn. Mo máa ń bẹ Jèhófà léraléra pé, “Tí mo bá láǹfààní iṣẹ́ míṣọ́nnárì lọ́jọ́ kan, jọ̀ọ́, ilẹ̀ olóoru ni kó o jẹ́ kí wọ́n rán mi lọ.”

Ọwọ́ Mi Tẹ Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tí Mò Ń Wá

 Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí mo ti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọnà àkànṣe, Jèhófà dáhùn àdúrà mi, ọwọ́ mi tẹ àfojúsùn mi! Wọ́n pè mí sí kíláàsì kẹrìnlélógòjì (44) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, a sì kẹ́kọ̀ọ́ yege ní September 10, 1967. Ṣé ẹ mọ ibi tí wọ́n rán mi lọ? Kò ní yà yín lẹ́nu pé ilẹ̀ olóoru ni wọ́n rán mi lọ, ìyẹn orílẹ̀-èdè Nikarágúà tó wà láàárín gbùngbùn Amẹ́ríkà! Kódà, èmi àtàwọn arábìnrin mẹ́ta míì ni wọ́n rán lọ síbẹ̀. Nígbà tá a dọ́hùn-ún, àwọn míṣọ́nnárì tó wà níbẹ̀ gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Ọ̀rọ̀ mi wá dà bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó “dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, [tó] sì mọ́kàn le” nígbà tí àwọn ará wá pàdé rẹ̀.​—Ìṣe 28:15.

Èmi rèé lọ́wọ́ òsì ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, pẹ̀lú Francis àti Margaret Shipley

 Ìlú kan tó ń jẹ́ León ni wọ́n rán mi lọ, èèyàn àlàáfíà làwọn tó wà níbẹ̀. Láì fàkókò ṣòfò, mo pinnu láti kọ́ èdè Sípáníìṣì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wákàtí mọ́kànlá (11) ni mo fi ń kọ́ èdè yẹn lójoojúmọ́ fún oṣù méjì, síbẹ̀ kò rọrùn fún mi rárá!

 Mo rántí ọjọ́ kan tí mò ń wàásù fún obìnrin kan. Bá a ṣe ń bọ́rọ̀ lọ, obìnrin náà fún mi ní fresco, ìyẹn ọtí ẹlẹ́rìndòdò kan táwọn ará Nikarágúà máa ń mu. Lójú ara mi, mo ronú pé èsì tí mo fún un ni pé “omi tí wọ́n sẹ́” nìkan ni mo lè mu. Àmọ́ ojú tí obìnrin yẹn fi wò mí fi hàn pé ọ̀rọ̀ mi ò yé e. Ó tó ọjọ́ mélòó kan kí n tó mọ̀ pé ọ̀tọ̀ ni ohun tí mo sọ fún obìnrin yẹn. Ohun tí mo sọ ni pé “omi àdúrà” nìkan ni mo lè mu. Inú mi dùn pé bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, èdè Sípáníìṣì bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀ mọ́ mi lẹ́nu.

Èmi àti Marguerite tá a jọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì fún ọdún mẹ́tàdínlógún (17)

 Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń kọ́ gbogbo ìdílé kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí pé ara tù mí nílùú León tọ́kàn mi sì balẹ̀, mo máa ń gbádùn kí n máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, kódà a máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ di aago mẹ́wàá alẹ́ nígbà míì. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà nílùú yẹn ni mo mọ̀. Tí mo bá ń lọ sílé nírọ̀lẹ́, mo máa ń kọjá lọ́dọ̀ àwọn ará àdúgbò tí wọ́n jókòó sórí àga ìnàyìn níwájú ilé wọn, tí wọ́n sì rọra ń gba atẹ́gùn. Bí mo ṣe ń kí tibí, ni mo máa ń kí tọ̀hún, àá sì máa tàkùrọ̀sọ.

 Àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nílùú León tó mélòó kan. Ọ̀kan lára wọn ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Nubia tó ní ọmọkùnrin mẹ́jọ. A ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ títí ètò Ọlọ́run fi rán mi lọ sílùú Managua lọ́dún 1976. Odindi ọdún méjìdínlógún (18) ni mi ò fi gbúròó Nubia àtàwọn ọmọ rẹ̀. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, mo lọ sí àpéjọ agbègbè nílùú León, nígbà tó di àkókò ìsinmi, àwọn ọmọkùnrin mélòó kan ṣùrù bò mí, àṣé àwọn ọmọ Nubia ni! Inú mi dùn gan-an pé Nubia tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nínú òtítọ́. Ká sòótọ́, akọ iṣẹ́ ló ṣe.

Iṣẹ́ Ìsìn Míṣọ́nnárì Lákòókò Rògbòdìyàn

 Ní nǹkan bí ọdún 1979, rògbòdìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ ní Nikarágúà. Láìka ìyẹn sí, a ṣì ń wàásù bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ní ìlú Masaya tí ètò Ọlọ́run rán mi lọ, a sábà máa ń pàdé àwọn tó ń wọ́de, tí wọ́n sì ń fi ẹ̀hónú hàn àtàwọn ajìjàgbara. Mo rántí alẹ́ ọjọ́ kan tá a wà nípàdé, bẹ́ẹ̀ ni ìbọn bẹ̀rẹ̀ sí í dún lákọlákọ láàárín àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ Sandinista tó ń jìjàgbara àtàwọn sójà. Ṣe ni gbogbo wa yára dọ̀bálẹ̀. a

 Ohun kan tún ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan tí mo wà lóde ìwàásù. Ṣàdédé ni mo rí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sandinista tó lo ìbòjú tó sì ń yìnbọn fún sójà kan. Bí mo ṣe fẹ́ sá lọ, bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọ ẹgbẹ́ yìí tún bẹ̀rẹ̀ sí í yọ láwọn ibòmíì. Ohun tá à ń wí yìí pẹ́, àwọn sójà ti bẹ̀rẹ̀ sí i yìnbọn látinú ọkọ̀ òfuurufú ẹlikópítà. Ló bá di pé iwájú ò ṣeé lọ, ẹ̀yìn ò ṣeé pa dà sí. Mo ronú pé ó ti tán fún mi. Àmọ́ lójijì, ọkùnrin kan ṣílẹ̀kùn ilé rẹ̀, ó sì fà mí wọlé. Mo gbà pé Jèhófà ló dáàbò bò mí lọ́jọ́ yẹn!

Wọ́n Lé Wa Kúrò Nílùú!

 March 20, 1982 ni mo lò kẹ́yìn nílùú Masaya. Mi ò lè gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn láéláé. Bí àwa míṣọ́nnárì mẹ́fà tá à ń gbé pa pọ̀ ṣe fẹ́ jẹun àárọ̀ lọ́jọ́ yẹn, lójijì la rí àwọn sójà ẹgbẹ́ Sandinista tí wọ́n dé tìbọn-tìbọn. Wọ́n já wọlé, wọ́n sì pàṣẹ fún wa pé: “Wákàtí kan péré lá fún kálukú yín láti gbé báàgì kan péré kẹ́ ẹ si tẹ̀ lé wa.”

 Àwọn sójà náà mú wa lọ sínú oko kan, wọ́n sì dá wa dúró síbẹ̀ fún wákàtí mélòó kan. Kò pẹ́ sígbà yẹn, wọ́n fi àwa mẹ́rin sínú ọkọ̀ kékeré kan, ó di ibodè orílẹ̀-èdè Costa Rica. Bí wọ́n ṣe lé wa kúrò nílùú nìyẹn o. Nígbà tó yá, àwa míṣọ́nnárì mọ́kànlélógún (21) ni wọ́n lé kúrò nílùú.

 Àwọn ará ní Costa Rica gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì gbé wa lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní San José lọ́jọ́ kejì. A ò pẹ́ níbẹ̀ rárá. Nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà, wọ́n rán àwa mẹ́jọ lọ sí orílẹ̀-èdè Honduras ká lè máa bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa lọ.

Iṣẹ́ Ìsìn Mi ní Honduras

 Ilú Tegucigalpa ni wọ́n rán mi lọ ní Honduras, ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) sì ni mo fi sìn níbẹ̀. Ìjọ kan péré ló wà níbẹ̀ nígbà tí mo kọ́kọ́ débẹ̀, àmọ́ láàárín àkókò yẹn, iye wọn di mẹ́jọ. Ó bani nínú jẹ́ pé bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, ìwà ọ̀daràn bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ nílùú yẹn. Àwọn olè sì bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i, kódà ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n dá mi lọ́nà. Ó tún ní ẹgbẹ́ kan tó máa ń béèrè owó lọ́wọ́ mi tàbí “owó ilẹ̀” bí wọ́n ṣe máa ń pè é. Mo máa ń sọ fún wọn pé, “Mo ní ohun tó sàn ju owó lọ,” màá sì fún wọn ní ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé ìròyìn wa. Wọ́n á sì fi mí sílẹ̀!

 Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ń gbé ìlú Tegucigalpa ló jẹ́ èèyàn àlàáfíà, wọ́n sì níwà ọmọlúàbí, mo sì ràn àwọn kan nínú wọn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, mo rántí obìnrin kan tó ń jẹ́ Betty tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, tó sì ń tẹ̀ síwájú gan-an. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, ó pè mí, ó sì sọ fún mi pé, òun fẹ́ máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì àwọn ajíhìnrere. Ó dùn mí gan-an! Àmọ́, ó yà mí lẹ́nu pé ọdún méjì lẹ́yìn náà, Betty fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ pa dà. Kí ló mú kó pa dà? Betty rí i pé àárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan lòun ti lè rí ìfẹ́ tòótọ́. (Jòhánù 13:34, 35) Ó sọ fún mi pé: “Ṣe lẹ máa ń kí gbogbo èèyàn tọ̀yàyàtọ̀yàyà, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ ò mọ olówó yàtọ̀ sí tálákà. Ẹ yàtọ̀ sáwọn tó kù.” Nígbà tó yá, Betty ṣèrìbọmi.

 Nígbà tó dọdún 2014, ètò Ọlọ́run kó gbogbo àwa míṣọ́nnárì tó wà ní Tegucigalpa kúrò, wọ́n sì rán mi lọ sí orílẹ̀-èdè Panama. Ní báyìí, èmi àtàwọn míṣọ́nnárì mẹ́rin míì tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ la jọ ń gbé pa pọ̀.

Tọ́wọ́ Èèyàn Bá Tẹ Àfojúsùn Tó Ń Lé, Ó Máa Láyọ̀

 Mo ti lo ohun tó tó ọdún márùndínlọ́gọ́ta (55) lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, mi ò lè ṣe púpọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ nítorí àìlera mi. Síbẹ̀, Jèhófà ń fún mi lókun kí n má bàa dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

 Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan míì ni mo lè fayé mi ṣe, àmọ́ ká ní nǹkan míì ni mo ṣe ni, mi ò bá má gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún tí mo ti rí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà! Àwọn tí mo ti ràn lọ́wọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin láti wá sínú òtítọ́ lé ní àádọ́ta (50), gbogbo wọn sì dà bí ọmọ fún mi nípa tẹ̀mí. Kò tán síbẹ̀ o, mo tún ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ gidi. Yàtọ̀ sí àwọn ọmọ ìyá nípa tẹ̀mí tí mo ní yìí, àbúrò ìyá mi tó ń jẹ́ Steffi tó ń gbé nílẹ̀ Jámánì tún ń tì mí lẹ́yìn.

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò lọ́kọ, mi ò ronú pé mo dá wà rí. Ìdí ni pé, Jèhófà wà pẹ̀lú mi. Mo tún ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà bí Marguerite Foster tá a jọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì pa pọ̀ fún ọdún mẹ́tàdínlógún (17). Ọ̀pọ̀ ìrírí la jọ ní, a sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ títí di òní olónìí.​—Òwe 18:24.

 Ọkàn mi balẹ̀ torí mo mọ̀ pé ohun tó dáa jù ni mo fayé mi ṣe, ìyẹn bí mo ṣe fayé mi ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Mo dúpẹ́ pé ohun tí mo ní lọ́kàn nígbà tí mo wà lọ́mọdé ni mo fayé mi ṣe, mo sì ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí tó ń wúni lórí. Ká sòótọ́, mo ní ayọ̀ tó tọ́kàn wá, mo sì ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí màá lè sin Jèhófà títí ayé.

a Ẹgbẹ́ Sandinista National Liberation Front bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ láwọn ọdún 1970. Nígbà tó yá, wọ́n gbàjọba lọ́wọ́ ìdílé tó ti ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè náà fún ogójì (40) ọdún.