Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ASTER PARKER | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Ó Wù Mí Kí N Fi Gbogbo Ayé Mi Sin Jèhófà

Ó Wù Mí Kí N Fi Gbogbo Ayé Mi Sin Jèhófà

 Inú mi dùn gan-an pé àtikékeré làwọn òbí mi ti kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Mo ṣì rántí ìgbà tí wọ́n fi ìwé Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́. Bí wọ́n ṣe ṣàlàyé àwọn àwòrán àtàwọn ìtàn tó wà nínú ìwé náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sì mú kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Èyí mú kí n lè máa fìtara wàásù fáwọn ọmọ tó wà ládùúgbò wa, kódà mo tún máa ń wàásù fún bàbá mi àgbà ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá wá kí wa. Bí àwọn òbí mi ṣe fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Jèhófà tí wọ́n sì fi kọ́ àwa ọmọ wọn mú kára wa tètè mọlé nígbà tá a kó kúrò nílùú Asmara lórílẹ̀-èdè Eritrea, tá a sì kó lọ sílùú Addis Ababa lórílẹ̀-èdè Etiópíà.

 Àtikékeré ni mo ti nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, ó sì ń wù mí kí n ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà kí n sì ṣèrìbọmi. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13), mo ṣèrìbọmi, inú mi sì dùn gan-an pé ọwọ́ mi tẹ ohun tí mò ń wá. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Arákùnrin Helge Linck a béèrè lọ́wọ́ mi pé, ṣé mo ti ń ronú àtiṣe aṣáájú-ọ̀nà. Mi ò lè gbàgbé ọjọ́ yẹn láé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi àti màmá mi máa ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà onígbà kúkúrú (ìyẹn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́), mi ò mọ nǹkan kan nípa iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ṣé ẹ rí i, ìbéèrè tí Arákùnrin Linck bi mí lọ́jọ́ yẹn mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

Èmi àti Josiah nígbà tí mo ṣì wà lọ́mọdé

Wọ́n Múra Wa Sílẹ̀ De Àtakò

 Lọ́dún 1974, rògbòdìyàn nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú wáyé ní Etiópíà, ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n fàṣe ọba mú, wọ́n pa àwọn èèyàn nípakúpa ìlú ò sì fara rọ rárá. Lásìkò yẹn a ò lè wàásù láti ilé dé ilé mọ́, àwùjọ kéékèèké la sì ti ń kóra jọ láti ṣèpàdé. Àwọn òbí wa wá bẹ̀rẹ̀ sí í múra wa sílẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé a ṣì máa kojú àtakò tó le. Àwọn ìlànà Bíbélì tá à ń kọ́ wá jẹ́ ká lóye ohun tó túmọ̀ sí láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. A kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe máa fèsì tí wọ́n bá ń da ìbéèrè bò wá, á sì tún jẹ́ ká mọ ìgbà tó yẹ ká dákẹ́.​—Mátíù 10:19; 27:12, 14.

AFP PHOTO

Lákòókò ogun abẹ́lé tó jà lọ́dún 1974

 Lẹ́yìn tí mo parí ilé ẹ̀kọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú ti Etiópíà. Láàárọ̀ ọjọ́ kan tí mo dé ibi iṣẹ́, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kí mi ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá, wọ́n sọ pé èmi ni wọ́n yàn pé kó ṣáájú àwọn tó máa yan lọ́jọ́ tí wọ́n ń ṣe àjọyọ̀ àyájọ́ ọjọ́ tí wọ́n dá ìjọba sílẹ̀. Ojú ẹsẹ̀ ni mo lọ sọ fún ọ̀gá mi pé mi ò ní lè ṣe iṣẹ́ yẹn torí pé mi ò kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú.

 Bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ ní pápákọ̀ òfúrufú lọ́jọ́ kejì, mo rí àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n gbé ìbọn kọ́rùn tí wọ́n ń bọ̀ tààràtà síbi tí àwọn èèyàn ti ń gba ìwé ìrìnnà. Èrò mi ni pé ṣe ni wọ́n fẹ́ wá mú ẹnì kan tó ń sá kúrò nílùú. Àmọ́ ó yà mí lẹ́nu pé èmi gan-an ni wọ́n wá mú, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé èmi kẹ̀, kí ni mo ṣe? Bí iṣẹ́ ọjọ́ yẹn ṣe dàrú nìyẹn.

Jèhófà Ràn Mí Lọ́wọ́ Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n

 Àwọn sójà náà mú mi lọ sí ọ́fíìsì kan níbi tí wọ́n ti fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Wọ́n bi mí pé: “Ta ló ń sanwó fún ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ṣé o wà lára àwọn ajìjàgbara orílẹ̀-èdè Eritrea? Àbí ìjọba Amẹ́ríkà ní ìwọ tàbí bàbá rẹ ń ṣe amí fún” Àsìkò yẹn ò rọrùn rára, àmọ́ ọkàn mí balẹ̀, ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà lára mi.​—Fílípì 4:6, 7.

 Lẹ́yìn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò tán, àwọn sójà náà gbé mi lọ sí ilé kan tí wọ́n ti sọ di ọgbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n wá fi mí sínú yàrá kótópó kan tí àwọn obìnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ọ̀rọ̀ òṣèlú wà.

Nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ ní pápákọ̀ òfúrufú

 Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, bí mo ṣe sùn sílẹ̀ pẹ̀lú aṣọ iṣẹ́ lọ́rùn mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa àwọn òbí mi àtàwọn àbúrò mi torí mo mọ̀ pé ọkàn wọn ò ní balẹ̀, ìdí sì ni pé wọ́n mọ̀ pé wọ́n ti mú mi, àmọ́ wọn ò mọ ibi tí mo wà. Mo bẹ Jèhófà kó lè jẹ́ kí wọ́n mọ ibi tí mo wà.

 Bí mo ṣe ń jí láàárọ̀ ọjọ́ kejì, mo rí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà tí mo mọ̀. Ó yà á lẹ́nu bó ṣe rí mi, ó bi mí pé, “Aster, kí lò ń ṣe níbí?” Ni mo bá bẹ̀ ẹ́ pé, jọ̀ọ́ lọ bá mi sọ fáwọn òbí mi pé ibí ni mo wà. Bí ẹ̀ṣọ́ yẹn ṣe sọ fún wọn, kí ilẹ̀ ọjọ́ yẹn tó ṣú, wọ́n fi aṣọ àti oúnjẹ ránṣẹ́ sí mi. Olùgbọ́ àdúrà mà ni Jèhófà o. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí n rí i pé mi ò dá wà.

 Wọn ò jẹ́ kí àwọn ẹbí mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi wá kí mi, kódà, wọn ò jẹ́ kí n ní Bíbélì àtàwọn ìwé wa. Síbẹ̀, Jèhófà ń lo àwọn tá a jọ wà lẹ́wọ̀n láti fún mi ní ìṣírí. Inú wọn máa ń dùn bí mo ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn lójoojúmọ́. Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń sọ fún mi pé: “Àwa ń jà fún ìjọba èèyàn, ìwọ ń jà fún Ìjọba Ọlọ́run, tí wọ́n bá tiẹ̀ fikú halẹ̀ mọ́ ẹ, má gbà fún wọn o.”

 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n máa ń fọ̀rọ̀ wá àwọn ẹlẹ́wọ̀n lẹ́nu wò, wọ́n sì máa ń lù wọ́n. Ní nǹkan bí aago mọ́kànlá alẹ́ ọjọ́ kan, wọ́n wá mú mi. Nígbà tí wọ́n mú mi dé yàrá tí wọ́n ti máa fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fẹ̀sùn oríṣiríṣi kàn mí. Wọ́n ní mò ń tako ìjọba. Nígbà tí mo kọ̀ láti kọrin àwọn olóṣèlú, méjì nínú àwọn ẹ̀ṣọ́ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í lù mí. Bí wọ́n sì ṣe máa ń wá látìgbàdégbà nìyẹn láti fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò. Nígbàkigbà tí wọ́n bá ti wá mú mi, mo máa ń gbàdúrà gan-an, Jèhófà sì máa ń fún mi lókun.

 Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, ọkàn lára àwọn ẹ̀ṣọ́ náà wá bá mi, ó sọ pé o lè máa lọ, o ti dòmìnira. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé, inú mi dùn, ó tún rí bákan lára mi torí mo ti ń gbádùn bí mo ṣe ń wàásù fáwọn obìnrin tá a jọ wà lẹ́wọ̀n.

 Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, àwọn sójà wá sílé wa, wọ́n sì mú gbogbo àwọn ọmọ tó wà nínú ìdílé wa, àmọ́ èmi ò sí nílé lọ́jọ́ yẹn. Wọ́n mú àbúrò mi mẹ́ta, obìnrin méjì àti ọkùnrin kan. Ó wá ṣe kedere pé mo gbọ́dọ̀ fi ìlú sílẹ̀. Inú mi ò dùn sí ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí, àmọ́ màámi sọ fún mi pé kí n ṣọkàn akin, kí n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo wọ ọkọ̀ òfúrufú tó ń lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, àwọn sójà wá sílé wa láti wá mú mi. Nígbà tí wọn ò bá mi nílé wọ́n sáré wá mí lọ sí pápákọ̀ òfúrufú. Àmọ́ kí wọ́n tó dé, ọkọ̀ òfúrufú tí mo wọ̀ ti gbéra.

 Ọ̀dọ̀ Haywood àti Joan Ward tó jẹ́ mísọ́nnárì ni mo dé sí nílùú Maryland, àwọn ló sì kọ́ àwọn òbí mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn oṣù márùn-ún, ọwọ́ mi tẹ ohun tó ti ń wù mí tipẹ́, ìyẹn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Èmi àti Cyndi tó jẹ́ ọmọ àwọn tí mo dé sọ́dọ̀ wọn la jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ọ̀pọ̀ ìrírí alárinrin la ní lẹ́nu iṣẹ́ náà, a sì gbádùn iṣẹ́ náà dọ́ba.

Èmi àti Cyndi Ward tá a jọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé

Mo Gbádùn Iṣẹ́ Ìsìn Mi ní Bẹ́tẹ́lì

Nígbà témi àti ọkọ mi ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Wallkill nílùú New York

 Mo pàdé Wesley Parker nígbà tí mo lọ ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní New York lọ́dún 1979. Mo mọyì àwọn ìwà dáadáa tó ní àti bó ṣe wù ú láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. A ṣègbéyàwó ní 1981, ètò Ọlọ́run sì pe èmi àti ọkọ mi sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Wallkill, New York. Onírúurú ẹ̀ka ni mo ti ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì irú bi, ẹ̀ka tó ń tún ilé ṣe, ẹ̀ka tó ń fọṣọ àti ẹ̀ka tó ń bójú tó ètò ìṣiṣẹ́ MEPS. Bí mo ṣe ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ti fún mi láǹfààní láti lo ara mi gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó sì ti jẹ́ kí n láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, a ṣì ń bá ọ̀rẹ́ wa lọ títí di báyìí.

 Ohun kan ń kó ìdààmú ọkàn bá mi, ohun náà sì ni pé wọ́n ń ṣe inúnibíni tó gbóná janjan sáwọn ará ilé mi ní Etiópíà. Àwọn àbúrò mi mẹ́ta tí wọ́n mú nígbà yẹn ṣì wà lẹ́wọ̀n. b Ojoojúmọ́ sì ni màámi máa ń gbé oúnjẹ lọ fún wọn, torí wọn ò fún wọn lóúnjẹ níbẹ̀.

 Ní gbogbo àkókò tí nǹkan ò rọrùn fún mi yẹn, Jèhófà wà pẹ̀lú mi. Àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì náà ràn mí lọ́wọ́, wọ́n sì tù mí nínú. (Máàkù 10:29, 30) Lọ́jọ́ kan, Arákùnrin John Booth sọ fún mi pé: “Inú wa dùn pé ẹ wà pẹ̀lú wa ní Bẹ́tẹ́lì. Mo mọ̀ pé Jèhófà ló jẹ́ kẹ́ ẹ wà níbí.” c Irú àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí jẹ́ kí ń rí i pé ìpinnu tó dáa ni mo ṣe bí mo ṣe kúrò ní Etiópíà, ó sì dá mi lójú pé Jèhófà máa bójú tó àwọn ara ilé mi.

Ipò Wa Yí Pa Dà, Àmọ́ À Ń Bá Iṣẹ́ Ìsìn Wa Lọ

 Ní January 1989, àyẹ̀wò fi hàn mo ti lóyún. Bá a ṣe kọ́kọ́ gbọ́, ó bá wa lójijì. Àmọ́ nígbà tó yá, a fi ara wa lọ́kàn balẹ̀, a sì ń fi ayọ̀ retí ọmọ wa. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló ń jà gùdù lọ́kàn wa irú bí, ibo la máa gbé, iṣẹ́ wo la máa ṣe tá a bá kúrò ní Bẹ́tẹ́lì àti irú òbí tá a máa jẹ́.

 Ní April 15, 1989, a kó gbogbo ẹrù wa a sì forí lé ìlú Oregon, ká lè máa bá iṣẹ́ ìsìn wa lọ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Kò pẹ́ tá a débẹ̀ làwọn ọ̀rẹ́ wa kan gbà wá níyànjú pé, kì í ṣe irú àkókò yìí ló yẹ ká ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Òótọ́ sì ni wọ́n sọ torí ìwọ̀nba lohun tá a ní, a sì tún ń retí ọmọ. Gbogbo ẹ̀ tojú sú wa, a ò mọ ohun tá a lè ṣe. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Arákùnrin Guy Pierce tó jẹ́ alábòójútó àyíká wa àti Penny ìyàwó wọn wá bẹ ìjọ wa wò. d Wọ́n rọ̀ wá pé ká dúró lórí ìpinnu tá a ṣe. Torí náà, a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà a sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. (Málákì 3:10) À ń bá iṣẹ́ náà lọ títí a fi bí àwọn ọmọ wa Lemuel àti àbúrò ẹ̀ Jadon.

 A ò jẹ́ gbàgbé àkókò alárinrin tá a fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà tá a sì tún ń tọ́ àwọn ọmọ wa. Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí fún wa láǹfààní láti kọ́ àwọn aládùúgbò wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì títí kan àwọn ọmọkùnrin wa. (Diutarónómì 11:19) Àmọ́, lẹ́yìn tá a bí Japheth, ọmọkùnrin wa kẹta a pinnu láti dá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà dúró fáwọn àkókò kan.​—Míkà 6:8.

A Kọ́ Àwọn Ọmọ Wa Láti Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà

 A mọ̀ pé iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì fáwa òbí ni bá a ṣe máa ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn kí wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Kí ìyẹn lè ṣeé ṣe, a máa ń gbìyànjú láti rí i pé àwọn ọmọ wa gbádùn ìjọsìn ìdílé. Mo rántí pé nígbà tí wọ́n ṣì kéré, a jọ máa ń ka ìwé Fifetisilẹ si Olukọ Nla Na àti Ìwé Ìtàn Bíbélì. Kódà, a máa ń fi lára àwọn ìtàn náà ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́. Torí pé èmi nìkan ni obìnrin, nígbà tá a ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ Jésíbẹ́lì, èmi ni mo ṣe Jésíbẹ́lì. Inú àwọn ọmọ wa dùn láti ṣe bí àwọn ọkùnrin tó ti Jésíbẹ́lì láti ojú fèrèsé, wọ́n sì tún ṣe bí àwọn ajá tó jẹ ẹ́. Yàtọ̀ síyẹn ọkọ mi tún máa ń bá ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ wa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

 A nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wa gan-an, a sì ń tọ́jú wọn. Bákan náà, a máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ìdílé wa wà níṣọ̀kan. Bí wọ́n ṣe ń dàgbà, a kọ́ wọn làwọn iṣẹ́ ilé, wọ́n máa ń fọ abọ́, wọ́n ń fọ aṣọ, wọ́n sì ń tún yàrá wọn ṣe. Kódà a kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń dáná.

 Bá a ṣe ń kọ́ àwọn ọmọ wa làwa náà ń kọ́ ara wa. Bí àpẹẹrẹ àwọn ìgbà míì wà tá a máa ń fi ìbínú sọ̀rọ̀ sáwọn ọmọ wa tàbí ká tiẹ̀ fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí ara wa. Àmọ́, làwọn ìgbà tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀ a kì í jọ ara wa lójú ṣe la máa ń tọrọ àforíjì.

 Látìgbàdégbà, a máa ń pe àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ wá sílé wa ká lè ṣe wọ́n lálejò. Bákan náà, a máa ń pe àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn míṣọ́nnárì, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò, àtàwọn tó ń sìn níbi tí àìní wà. (Róòmù 12:13) Táwọn àlejò bá wà pẹ̀lú wa, a kì í sọ pé káwọn ọmọ wa lọ ṣeré ní yàrá míì, ṣe ni wọ́n máa ń dúró tì wá tí wọ́n á sì máa gbọ́ ìrírí àwọn tó wá kí wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun táwọn ọmọ mi máa ń rántí nípa àwọn ìkórajọ yìí máa ń ju tèmi àti tọkọ mi lọ.

 Èmi àti ọkọ mi ṣiṣẹ́ kára ká lè gbádùn iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bi àpẹẹrẹ, a máa ń tọ́jú owó pamọ́ ká lè fi rìnrìn àjò lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì lákòókò ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́. A máa ń lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì làwọn orílẹ̀-èdè tá a bá lọ, a sì máa ń lọ sípàdé àti òde ìwàásù níbẹ̀. Ká sòótọ́ ohun tá à ń ṣe yìí mú ká túbọ̀ mọyì ètò Jèhófà kárí ayé, ó sì tún jẹ́ kí ìdílé wa sún mọ́ra.

Nígbà tí ìdílé wa ṣè ìbẹ̀wò sí oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn nílùú New York lọ́dún 2013

Mi Ò Jẹ́ Kí Ohunkóhun Dí Mi Lọ́wọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

 Ládùúgbò wa àwọn tó ń sọ èdè Sípáníìṣì pọ̀ gan-an, àmọ́ àwọn ará tó gbọ́ èdè yẹn ò pọ̀. Torí pé àwọn ọmọ wa ṣì kéré, a ronú pé á dáa ká lọ sí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì, la bá bi Arákùnrin Pierce bóyá a lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó kọ́kọ́ rẹ́rìn-ín músẹ́, ó wá sọ fún wa pé, “Ibi táwọn ẹja bá wà làwọn apẹja máa ń lọ.” Ọ̀rọ̀ ìṣírí tí wọ́n sọ fún wa yìí ló jẹ́ ká pinnu láti lọ sí ìjọ tó ń sọ èdè Sípáníìṣì ní Woodburn, Oregon. Inú wa dùn gan-an torí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn la kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ohun tí wọ́n ń kọ, kódà lára wọn ṣèrìbọmi. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ àwùjọ kékeré tó ń fi èdè Sípáníìṣì ṣèpàdé di ìjọ.

 Ìgbà kan wà tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọkọ mi, èyí mú ká kó lọ sí California torí ibẹ̀ ni wọ́n ti rí iṣẹ́ míì. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, èmi, Lemuel àti Jadon bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó sì di ọdún 2007, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà, a sì gbádùn ẹ̀ dọ́ba. Kété lẹ́yìn tá a parí ilé ẹ̀kọ́ náà, a kíyè sí pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Lárúbáwá ló wà ní ìpínlẹ̀ wa. Torí náà, a pinnu láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè náà lẹ́yìn tá a ti lo ọdún mẹ́tàlá ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì. Ká sòótọ́, a gbádùn bá a ṣe ń fi èdè Lárúbáwá wàásù fáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa àtàwọn míì tá a pà dé lákòókò àkànṣe ìwàásù tá a ṣe lórílẹ̀-èdè míì. Bá a ṣe ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ nìyẹn ní San Diego nílùú California.

 Ọkọ rere àti bàbá dáadáa ni ọkọ mi. Gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ. Kì í sọ ohun tí ò dáa nípa Bẹ́tẹ́lì tàbí bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ìjọ. Ohun tó dáa ló máa ń sọ ní gbogbo ìgbà. A jọ máa ń gbàdúrà pa pọ̀, gbogbo ìgbà ló sì máa ń fi ọ̀rọ̀ mi, àtàwọn àníyàn wa sínú àdúrà. Kí n sòótọ́, àwọn àdúrà yẹn máa ń tù mí nínú, ó sì máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀

 Tí mo bá ronú pa dà sáwọn àkókò tá a lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ìgbà tá a fi tọ́ àwọn ọmọ wa àti bá a ṣe lọ sìn láwọn ìjọ tí àìní wà, a ti wá rí i pé Jèhófà máa ń dúró ti àwọn tó bá fi í sípò àkọ́kọ́ láyé wọn, torí ó dúró tì wá, a ò sì tọrọ jẹ. (Sáàmù 37:25) Ohun tó dá mi lójú ni pé, tẹ́nì kan bá fi gbogbo ayé ẹ̀ sin Jèhófà, kò ní kábàámọ̀ láé àti láéláé.​—Sáàmù 84:10.

Láti apá òsì: Èmi, Japheth, Lemuel, Jadon, àti Wesley

a Arákùnrin Linck ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Kenya, ẹ̀ka yìí ló sì ń bójú tó iṣẹ́ tó ń lọ ní Etiópíà.

b Wọ́n dá àwọn àbúrò mi sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti lo ọdún mẹ́rin lẹ́wọ̀n.

c Arákùnrin Booth jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí títí wọ́n fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé lọ́dún 1996.

d Arákùnrin Pierce náà jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí títí wọ́n fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé lọ́dún 2014.