Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÌSỌ̀RÍ 8

Jáwọ́ Nínú Ìsìn Èké; Máa Ṣe Ìsìn Tòótọ́

Jáwọ́ Nínú Ìsìn Èké; Máa Ṣe Ìsìn Tòótọ́

1. Ní ti ọ̀ràn ìjọsìn, kí làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ yàn láti ṣe lónìí?

JÉSÙ sọ pé: “Ẹni tí kò bá sí ní ìhà ọ̀dọ̀ mi lòdì sí mi.” (Mátíù 12:30) A gbọ́dọ̀ wà lọ́dọ̀ ẹnì kan, bí a ò bá ti sí lọ́dọ̀ Jèhófà a jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Sátánì la wà yẹn. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló ń ronú pé àwọn ń sin Ọlọ́run lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà, ṣùgbọ́n Bíbélì sọ pé Sátánì “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló gbà pé àwọn ń sin Ọlọ́run nígbà tó sì jẹ́ pé Sátánì Èṣù ni wọ́n ń sìn ní ti gidi! Àwọn èèyàn lónìí gbọ́dọ̀ yan ohun kan nítorí a kì í jẹ méjì lábà Àlàdé: Wọ́n gbọ́dọ̀ sin yálà Jèhófà, “Ọlọ́run òtítọ́,” tàbí Sátánì, “baba irọ́.”—Sáàmù 31:5; Jòhánù 8:44.

Já Ara Rẹ Gbà Lọ́wọ́ Ìsìn Èké

2. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà tí Sátánì máa ń fẹ́ lò láti mú kí àwọn èèyàn má lè jọ́sìn Jèhófà?

2 Kí á pinnu láti sin Jèhófà lohun tó bọ́gbọ́n mu, ìyẹn ló ń múni rí ojú rere Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n inú Sátánì kì í dùn sí ẹnikẹ́ni tó bá ń sin Ọlọ́run; wàhálà ló máa ń kó bá àwọn tó bá ń sin Ọlọ́run. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó máa ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni nípa mímú kí àwọn ẹlòmíràn títí kan àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ará ilé ẹni máa fini ṣẹ̀sín tàbí kí wọ́n máa ta koni. Jésù kìlọ̀ pé: “Ní tòótọ́, àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀.”—Mátíù 10:36.

3. Bí ìdílé rẹ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá ta ko jíjọ́sìn tí ò ń jọ́sìn Ọlọ́run, kí ni wàá ṣe?

3 Bí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, kí lo máa ṣe? Ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ pé ọ̀nà táwọn ń gbà jọ́sìn kò tọ́, síbẹ̀ wọ́n ń lọ́ tìkọ̀ láti fi í sílẹ̀. Wọ́n ronú pé báwọn bá fi í sílẹ̀, àwọn ti ṣẹ ìdílé àwọn.  Ǹjẹ́ ìyẹn bọ́gbọ́n mu? Bí o bá mọ̀ pé àwọn èèyàn rẹ tímọ́tímọ́ kan ń lo oògùn olóró, ǹjẹ́ o ò ní kìlọ̀ fún wọn pé oògùn náà yóò ṣe wọ́n léṣe? O kò ní bá wọn máa lo oògùn náà, àbí wàá ṣe bẹ́ẹ̀?

4. Kí ni Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìjọsìn ìgbà ayé rẹ̀?

4 Jóṣúà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n jáwọ́ nínú ìṣe àti àṣà ìsìn èké tó jẹ́ ti àwọn baba ńlá wọn. Ó sọ pé: “Wàyí o, ẹ bẹ̀rù Jèhófà, kí ẹ sì máa sìn ín ní àìlálèébù àti ní òtítọ́, kí ẹ sì mú àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìhà kejì Odò àti ní Íjíbítì kúrò, kí ẹ sì máa sin Jèhófà.” (Jóṣúà 24:14) Jóṣúà dúró ṣinṣin ti Ọlọ́run, Jèhófà sì bù kún un. Bí a bá dúró ṣinṣin ti Jèhófà, yóò bù kún àwa náà.—2 Sámúẹ́lì 22:26.

Kó Àwọn Nǹkan Tí Wọ́n Ń Lò fún Ìjọsìn Èké Dà Nù

5. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ pa àwọn ohun èlò iṣẹ́ òkùnkùn run?

5 Láti já ara wa gbà kúrò nínú ìsìn èké tún túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ dáná sun ohun èlò iṣẹ́ òkùnkùn èyíkéyìí tá a bá ní, àwọn bí, oògùn ìṣọ́ra, ońdè, òrùka ẹ̀rẹ, ìgbàdí àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Èyí ṣe pàtàkì nítorí yóò fi hàn pé Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá.

6. Kí làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe sáwọn ìwé idán tí wọ́n ní?

6 Wo ohun táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kan ṣe nígbà tí wọ́n pinnu láti ṣe ìsìn tòótọ́. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn.”—Ìṣe 19:19.

7. Kí la lè ṣe bí àwọn ẹ̀mí èṣù bá ń dààmú wa?

7 Ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹ̀mí èṣù dààmú àwọn kan tó bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ rí wọ́n ti lọ́wọ́ ní tààràtà nínú iṣẹ́ àjẹ́, iṣẹ́ adáhunṣe tàbí àwọn iṣẹ́ òkùnkùn mìíràn. Bí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, gbàdúrà sókè ketekete sí Jèhófà, kí o ké pe orúkọ rẹ̀. Òun yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.—Òwe 18:10; Jákọ́bù 4:7.

8. Ojú wo làwọn Kristẹni fi ń wo òrìṣà, ère àti àwòrán táwọn èèyàn máa ń lò nínú ìjọsìn èké?

8 Àwọn tó bá fẹ́ sin Jèhófà kò gbọ́dọ̀ ní òrìṣà, ère tàbí àwòrán ìsìn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn èké, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọ́dọ̀ júbà wọn. ‘Nípa ìgbàgbọ́ ni [àwọn Kristẹni tòótọ́ máa] ń rìn, kì í ṣe nípa ohun tí wọ́n rí.’ (2 Kọ́ríńtì 5:7) Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún òfin Ọlọ́run tó ka lílo ère èyíkéyìí nínú ìjọsìn léèwọ̀.—Ẹ́kísódù 20:4, 5.

Dara Pọ̀ Mọ́ Àwọn Èèyàn Jèhófà

9. Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì gbani lórí dídi ọlọgbọ́n?

9 Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” (Òwe 13:20) Bí a bá fẹ́ gbọ́n, a óò ní láti máa bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rìn tàbí kí a máa dara pọ̀ mọ́ wọn. Àwọn ló ń rin ọ̀nà tó lọ sí ìyè.—Mátíù 7:14.

10. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sin Ọlọ́run?

10 Ire àwọn èèyàn jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí lógún púpọ̀. Iṣẹ́ wọn ni pé kí wọ́n ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ Bíbélì tó ń ṣamọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun. Wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nípa bíbá ọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Wọ́n á dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ, wọ́n á sì fi bí o ṣe lè fi ìmọ̀ Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé rẹ hàn ọ́.—Jòhánù 17:3.

11. Báwo ni àwọn ìpàdé Kristẹni yóò ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́?

11 Wàá túbọ̀ kọ́ nípa ọ̀nà Jèhófà láwọn ìpàdé wọn, tí wọ́n sábà máa ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. A óò fún ọ lókun láti túbọ̀ fẹ́ láti máa ṣe ẹ̀sìn tòótọ́. Wàá sì tún gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa bí o ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì.—Hébérù 10:24, 25.

12. Báwo ni àdúrà yóò ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sin Ọlọ́run?

12 Bí o ṣe túbọ̀ ń kọ́ nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ àti nípa ète rẹ̀, òye rẹ nípa àwọn ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti ìmọrírì rẹ fún un yóò túbọ̀ pọ̀  sí i. Ó yẹ kí o túbọ̀ máa fẹ́ láti ṣe ohun tí ó fẹ́, kí o sì yẹra fún ohun tí kò fẹ́. Rántí pé o lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́ kí o sì yẹra fún ohun tí kò tọ́.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Fílípì 4:6.

Báwo lo ṣe lè dẹni tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́?

13. Báwo ni o ṣe lè mú ọkàn Jèhófà yọ̀?

13 Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ tí o sì ń tẹ̀ síwájú sí i nípa tẹ̀mí, ó dájú pé wàá rí i pé ó yẹ kí o ya ara rẹ sí mímọ́ kí o sì ṣèrìbọmi láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí o bá dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà, wàá mú ọkàn Jèhófà yọ̀. (Òwe 27:11) Wàá wà lára àwọn èèyàn aláyọ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa wọn pé: “Èmi yóò máa gbé láàárín wọn, èmi yóò sì máa rìn láàárín wọn, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”—2 Kọ́ríńtì 6:16.