Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Sí Ẹ̀yin Arákùnrin àti Arábìnrin Wa Ọ̀wọ́n:

Inú ẹ̀dà àkọ́kọ́ Ilé Ìṣọ́ tá à ń fi sóde, ìyẹn ti January 1, 2008, la ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tuntun kan tó fani lọ́kàn mọ́ra jáde. Àkòrí ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà ni, “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn.” Ó sì dùn mọ́ wa pé látìgbà náà la ti ń gbé àpilẹ̀kọ tuntun jáde lábẹ́ àkòrí yìí ní oṣù mẹ́ta mẹ́ta!

Kí ni àwọn òǹkàwé wa ti ń sọ nípa àwọn àpilẹ̀kọ náà? Lẹ́yìn tí obìnrin kan ti ka àpilẹ̀kọ tó dá lórí Màtá, ó ní: “Ẹ̀rín pa mí nígbà tí mo kà á, torí pé mo máa ń ṣe bíi tiẹ̀ gẹ́lẹ́. Mo máa ń fẹ́ ṣe àwọn tó bá wá kí wa lálejò dáadáa. Nítorí èyí, ọwọ́ mi máa ń dí nígbà míì débi pé màá gbàgbé pé ó yẹ kí n jókòó tì wọ́n, ká jọ gbádùn ìbẹ̀wò wọn.” Ọ̀dọ́bìnrin kan tí kò tíì pé ogún ọdún sọ ọ̀rọ̀ tó gba àfiyèsí yìí nípa ìtàn Ẹ́sítérì, ó ní: “Mo gbà pé lóòótọ́ ni àwọn aṣọ àti ọ̀nà ìmúra tó lòde lè gbà wá lọ́kàn. Ó yẹ kí ìmúra wa yááyì; àmọ́ kò yẹ ká ki àṣejù bọ̀ ọ́.” Ó wá fi kún un pé: “Irú ẹni tá a jẹ́ gan-an ló ṣe pàtàkì sí Jèhófà.” Arábìnrin wa kan fi ìtara sọ̀rọ̀ nípa àpilẹ̀kọ kan tó dá lórí àpọ́sítélì Pétérù, ó ní: “Ìtàn náà gbà mí lọ́kàn pátápátá bí mo ṣe ń kà á. Ńṣe ló dà bíi pé mo wà níbẹ̀. Tí ìtàn náà bá sọ ohun kan lọ́nà tí kò ṣe tààràtà, mo máa ń fi òye gbé e.”

Yàtọ̀ sí àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí, àìmọye àwọn òǹkàwé wa ló ti kọ̀wé sí wa láti fi hàn pé àwọn mọrírì àwọn àpilẹ̀kọ náà. Èyí fi hàn pé òótọ́ ni ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ tipẹ́tipẹ́ pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa.” (Róòmù 15:4) Ó dájú pé Jèhófà fẹ́ ká kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye nínú àwọn ìtàn yìí ló ṣe fi wọ́n sínú Bíbélì. Gbogbo wa la lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ìtàn náà láìka iye ọdún tá a ti wà nínú òtítọ́ sí.

A fìfẹ́ rọ̀ ẹ́ pé kó o tètè ka ìwé yìí tó o bá ti rí i gbà. Ẹ fi í kún àwọn ìtẹ̀jáde tẹ́ ẹ̀ ń lò nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín. Ó dájú pé àwọn ọmọ yín máa gbádùn rẹ̀ gan-an. Nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, rí i dájú pé o kò pa ọ̀sẹ̀ kankan jẹ! Ńṣe ni kó o máa fara balẹ̀ kà á kó o lè ronú lé e lórí. Jẹ́ kó dà bíi pé o wà níbẹ̀; má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ níyà. Gbìyànjú láti mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀, kó o sì rí ohun tí wọ́n rí. Kíyè sí ohun tí wọ́n ṣe lábẹ́ ipò pàtó kan, kó o sì wò ó bóyá ohun tí ìwọ náà máa ṣe nìyẹn.

Inú wa dùn gan-an láti pèsè ìwé yìí fún ìlò rẹ̀. Kí Jèhófà jẹ́ kí ìwọ àti ìdílé rẹ̀ jàǹfààní nínú rẹ̀. A fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ yín gan-an ni! Ire o.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà