Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn

Báwo la ṣe lè jáǹfààní ní báyìí tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Bíbélì sọ pé wọ́n lo ìgbàgbọ́?

Àtẹ Tó Fi Àwọn Déètì Pàtàkì Inú Bíbélì Hàn

Àtẹ tó fi àwọn déètì pàtàkì hàn àti àwòrán ilẹ̀ yóò jẹ́ kó o lè fojú inú rí ibi tí àwọn olóòótọ́ èèyàn tí Bíbélì mẹ́nu kàn gbé àti ìgbà tí wọ́n gbé láyé.

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ìgbìmọ̀ Olùdarí fìfẹ́ rọ gbogbo èèyàn pé kí wọ́n jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ látinú kíka ìwé yìí, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lẹ́nìkọ̀ọ̀kan àti bí ìdílé.

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Bíbélì kún fọ́fọ́ fún ojúlówó ìtàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́. Báwo ni àpẹẹrẹ wọn ṣe lè ṣe wá láǹfààní?

ÉBẸ́LÌ

“Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ó Kú, Ó Ń Sọ̀rọ̀ Síbẹ̀”

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Ébẹ́lì àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀?

NÓÀ

Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”

Àwọn nǹkan wo ni kò ní jẹ́ kó rọrùn fún Nóà àti aya rẹ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn? Báwo ló ṣe jẹ́ pé ìgbàgbọ́ ló mú kí Nóà kan áàkì yẹn?

ÁBÚRÁHÁMÙ

“Baba Gbogbo Àwọn Tí Wọ́n Ní Ìgbàgbọ́”

Báwo ni ohun tí Ábúrámù ṣe ṣe fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́? Àwọn ọ̀nà wo ni wàá fẹ́ gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Ábúrámù?

RÚÙTÙ

“Ibi Tí O Bá Lọ Ni Èmi Yóò Lọ”

Kí nìdí tí Rúùtù fi gbà láti fi ìdílé rẹ̀ àti ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀? Àwọn ànímọ́ wo ni Rúùtù ní tí Jèhófà fi kà á sí ẹni tó ṣeyebíye?

RÚÙTÙ

“Obìnrin Títayọ Lọ́lá”

Kí nìdí tí ìgbéyàwó Rúùtù àti Bóásì fi ṣe pàtàkì? Ẹ̀kọ́ wo ni Rúùtù àti Náómì kọ́ wa nípa ìdílé?

HÁNÀ

Ó Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀ fún Ọlọ́run Nínú Àdúrà

Ìgbàgbọ́ tí Hánà ní nínú Jèhófà mú kó borí ìṣòro tó dà bíi pé kò ṣeé fara dà.

SÁMÚẸ́LÌ

Ó “Ń Bá A Lọ ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà””

Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìgbà tí Sámúẹ́lì wà lọ́mọdé? Kí ló mú kí ìgbàgbọ́ Sámúẹ́lì máa pọ̀ sí i nígbà tó wà ní àgọ́ ìjọsìn?

SÁMÚẸ́LÌ

Ó Lo Ìfaradà Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Wọ́n Já A Kulẹ̀

A lè rí àwọn ìnira àti ìjákulẹ̀ tó máa dán ìgbàgbọ́ wa wò. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára bí Sámúẹ́lì ṣe lo ìfaradà?

ÁBÍGẸ́LÌ

Ó Hùwà Ọlọgbọ́n

Kí la rí kọ́ látinú bí ilé ọkọ kò ṣe rọrùn fún Ábígẹ́lì?

ÈLÍJÀ

Ó Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́

Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíjà tá a bá bá àwọn èèyàn tí kò fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ pà dé?

ELIJAH

Ó Ṣọ́nà, Ó sì Ní Sùúrù

Báwo ni Èlíjà ṣe fi hàn pé òun ò fi ọ̀rọ̀ àdúrà gbígbà ṣeré bó ṣe ń dúró dé ìgbà tí Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣe?

ELIJAH

Ọlọ́run Rẹ̀ Tù Ú Nínú

Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ìdààmú ọkàn fi bá Èlíjà, débi pé ó gbàdúrà pé kí òun kú?

JÓNÀ

Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Àwọn Àṣìṣe Rẹ̀

Ǹjẹ́ iṣẹ́ tí Jèhófà ní kó o ṣe ti bà ọ́ lẹ́rù rí bíi ti Jónà? Kí ni ìtàn Jónà kọ́ wa nípa sùúrù àti àánú Jèhófà.

JÓNÀ

Ó Kọ́ Ìdí Tó Fi Yẹ Kó Jẹ́ Aláàánú

Báwo ni ìtàn Jónà ṣe lè mú ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò irú ẹni tá a jẹ́ gan-an?

Ẹ́SÍTÉRÌ

Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run

Ó máa ń gba pé ká ní ìgboyà àti ìgbàgbọ́ bíi ti Ẹ́sítérì ká tó lè fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn.

Ẹ́SÍTÉRÌ

Ó Lo Ọgbọ́n àti Ìgboyà, Kò sì Mọ Tara Rẹ̀ Nìkan

Báwo ní Ẹ́sítérì ṣe fínnúfíndọ̀ lo ara rẹ̀ fún Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀?

MÀRÍÀ

“Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”

Kí ni ìdáhùn tí Màríà fún Gébúrẹ́lì fi hàn nípa irú ìgbàgbọ́ tó ní? Àwọn ànímọ́ pàtàkì míì wo ló tún fi hàn?

MÀRÍÀ

Ó Dé ‘Ìparí Èrò Nínú Ọkàn Rẹ̀’

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú àwọn ìlérí Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i.

JÓSẸ́FÙ

Ó Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Ní Ìfaradà

Báwo ni Jósẹ́fù ṣe dáàbò bo ìdílé rẹ̀? Kí nìdí tó fi ní láti kó Màríà àti Jésù lọ sí Íjíbítì?

MÀTÁ

“Mo Ti Gbà Gbọ́”

Kí ni Màtá ṣe tó fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ tó wúni lórí kódà lásìkò tí ẹ̀dùn ọkàn bá a?

PÉTÉRÙ

Ó Borí Ìbẹ̀rù àti Iyè Méjì

Iyè méjì burú, ó lè ba ayé ẹni jẹ́. Àmọ́ Pétérù borí ìbẹ̀rù àti iyè méjì tó ní pé bóyá ni òun lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.

PÉTÉRÙ

Ó Dúró Ṣinṣin Nígbà Ìdánwò

Báwo ni ìgbàgbọ́ Pétérù àti ìdúróṣinṣin rẹ̀ ṣe jẹ́ kó tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ Jésù?

PÉTÉRÙ

Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìdáríjì Lọ́dọ̀ Ọ̀gá Rẹ̀

Kí ni Jésù kọ́ Pétérù nípa ìdáríjì? Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun ti dárí ji Pétérù?

Ìparí

Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i kí ìrètí tá a ní sì dá wa lójú hán-únhán-ún?

O Tún Lè Wo

ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ ỌLỌ́RUN

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn

Tó o bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn, wàá sún mọ́ Ọlọ́run.