Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 9

Ṣó Yẹ Kí N Gba Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Gbọ́?

Ṣó Yẹ Kí N Gba Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Gbọ́?

ÌDÍ TỌ́RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, a jẹ́ pé ìgbésí ayé ò nítumọ̀ kankan nìyẹn. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan, a lè rí ìdáhùn táá tẹ́ wa lọ́rùn sáwọn ìbéèrè tó ń jẹ wá lọ́kàn nípa ìdí tá a fi wà láyé àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.

LO MÁA ṢE?

Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Lọ́jọ́ kan, olùkọ́ Alex ń kọ́ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ nípa àwọn ohun alààyè, ó sì sọ fún wọn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n torí pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣèwádìí nípa ẹ̀, wọ́n sì ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni. Ọ̀rọ̀ yìí ò yé Alex mọ́, torí ó gbà pé Ọlọ́run wà, ó sì gbà pé òun ló dá gbogbo nǹkan. Àmọ́ Alex ò fẹ́ kó jẹ́ pé èrò tòun nìkan lá dá yàtọ̀. Ó wá ń sọ lọ́kàn ara ẹ̀ pé, ‘Táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá ti ṣèwádìí nípa ẹfolúṣọ̀n, tí wọ́n sì gbà pé òótọ́ ni, ta wá lèmi láti máa sọ pé kì í ṣòótọ́?’

Tó bá jẹ́ ìwọ ni Alex, ṣé wàá gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ torí pé àwọn ìwé kan ṣàlàyé pé ó tọ̀nà?

RÒ Ó WÒ NÁ!

Bí àwọn tí èrò wọn yàtọ̀ síra lórí ọ̀rọ̀ yìí bá ń jiyàn, ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ló máa ń yá wọn lára láti sọ láìtiẹ̀ mọ ìdí tí wọ́n fi gbà á gbọ́.

  • Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo torí ohun tí wọ́n fi kọ́ wọn ní ṣọ́ọ̀ṣì nìyẹn.

  • Àwọn kan gbà pé àwọn ohun alààyè kàn ṣàdédé wà ni, torí pé ohun tí wọ́n fi kọ́ wọn níléèwé nìyẹn.

ÌBÉÈRÈ MẸ́FÀ TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Hébérù 3:4) Ṣé a lè gba ohun tí Bíbélì sọ yìí gbọ́?

Tẹ́nì kan bá sọ pé ṣe ni àwọn ohun alààyè kàn ṣàdédé wà, ṣe ló dà bí ìgbà tẹ́ni náà ń sọ pé ṣe ni ilé yìí lalẹ̀ hù, pé kò sẹ́ni tó kọ́ ọ

OHUN TÁWỌN KAN SỌ: Ṣe ni kinní kan kàn ṣàdédé bú gbàù, gbogbo ohun tó wà lágbàáyé wá bẹ̀rẹ̀ sí í jáde.

1. Kí ló mú kí nǹkan ọ̀hún bú gbàù?

2. Èwo ló bọ́gbọ́n mu nínú kí gbogbo nǹkan ṣàdédé wà àbí kó jẹ́ pé ẹnì kan ló dá gbogbo nǹkan?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ: Ẹranko ló di èèyàn.

3. Tó bá jẹ́ pé ẹranko ló di èèyàn, ká fi ìnàkí ṣe àpẹẹrẹ, kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwa èèyàn gbọ́n ju àwọn ìnàkí lọ fíìfíì?

4. Kí nìdí tọ́rọ̀ àwọn ohun alààyè tó “kéré jù” pàápàá fi máa ń yà wá lẹ́nu nígbà tá a bá rí bí wọ́n ṣe díjú tó?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ: Wọ́n ti ṣèwádìí nípa ẹfolúṣọ̀n, wọ́n sì ti rí i pé òótọ́ ni.

5. Ṣẹ́ni tó ń sọ̀rọ̀ yẹn ti ṣèwádìí fúnra ẹ̀?

6. Ṣé gbogbo èèyàn ló gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ torí pé àwọn kan kàn sọ fún wọn pé gbogbo ẹni tórí ẹ̀ pé ló gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n?

“Ká sọ pé lọ́jọ́ kan, ò ń lọ nínú igbó kan, o wá rí ilé kan tó rẹwà tí wọ́n fi pákó kọ́, kí ló máa wá sí ẹ lọ́kàn? Ṣé wàá sọ pé: ‘Ẹ̀n ẹ́n! Ó ní láti jẹ́ pé ṣe làwọn igi kan to ara wọn pọ̀, tó sì wá di ilé yìí.’ Ó dájú pé o ò ní sọ bẹ́ẹ̀! Kò tiẹ̀ mọ́gbọ́n dá ní. Ṣé ó wá yẹ ká gbà pé ṣe ni gbogbo ohun tó wà lágbàáyé kàn ṣàdédé wà?”​—Julia.

“Ká sọ pé ẹnì kan sọ fún ẹ pé nǹkan kan bú gbàù lára ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kan tó ń ṣiṣẹ́, yíǹkì sì fọ́n jáde sára ògiri àti òrùlé. Ni yíǹkì tó fọ́n jáde yẹn bá di díkíṣọ́nárì ńlá kan. Ṣé wàá gbà á gbọ́?”​—Gwen.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O GBÀ PÉ ỌLỌ́RUN WÀ?

Bíbélì gbà ẹ́ níyànjú pé kó o máa lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ. (Róòmù 12:⁠1) Èyí túmọ̀ sí pé ìgbàgbọ́ tó o ní pé Ọlọ́run wà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ torí

  • OHUN TÓ O KÀN RÒ (Mo kàn ronú pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ wà tí agbára rẹ̀ ju ti ẹnikẹ́ni lọ)

  • OHUN TÁWỌN ẸLÒMÍÌ Ń ṢE (Àárín àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ìsìn ni mò ń gbé)

  • OHUN TÍ WỌ́N FI KỌ́ Ẹ (Láti kékeré làwọn òbí mi ti kọ́ mi láti gbà pé Ọlọ́run wà, kò sì sóhun tí mo lè ṣe, àfi kí n gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́)

Dípò ìyẹn, ó yẹ kó o ní ìdí tó bọ́gbọ́n mu tó o fi gbà pé Ọlọ́run wà.

“Tí mo bá wà ní kíláàsì tí mò ń fetí sí olùkọ́ wa bó ṣe ń ṣàlàyé bí àwọn ẹ̀yà ara wa ṣe ń ṣiṣẹ́, ṣe ló túbọ̀ ń mú kó dá mi lójú pé Ọlọ́run wà. Ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ló ní iṣẹ́ tirẹ̀, àní títí dórí èyí tó kéré jù lọ, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé a kì í mọ̀ pé wọ́n ń báṣẹ́ lọ nínú ara wa. Ọ̀nà tí ara wa yìí ń gbà ṣiṣẹ́ kà màmà lóòótọ́!”​—Teresa.

“Tí mo bá rí ilé gogoro, ọkọ̀ òkun ńlá tí wọ́n fi ń gbafẹ́ tàbí mọ́tò, mo máa ń bi ara mi pé, ‘Ta ló kọ́ ilé yìí tàbí ta ló ṣe ọkọ̀ yìí?’ Bí àpẹẹrẹ, ó ní láti jẹ́ pé àwọn tó ní òye ló ṣe mọ́tò, torí ọ̀pọ̀ nǹkan kéékèèké tó wà nínú rẹ̀ ló gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí mọ́tò tó lè ṣiṣẹ́. Tó bá sì wá jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣe mọ́tò, a jẹ́ pé ẹnì kan ló dá àwa èèyàn náà nìyẹn.”​—Richard.

“Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, bẹ́ẹ̀ ló ṣe túbọ̀ ń hàn sí mi pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. . . . Lójú tèmi, ó rọrùn láti gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà ju kéèyàn gbà ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́.”​—Anthony.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣèwádìí nípa ẹfolúṣọ̀n, síbẹ̀, èrò wọn ò tíì ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún. Tí ẹnu àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó pe ara wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n ò bá kò lórí ọ̀rọ̀ ẹfolúṣọ̀n, ṣé ó wá yẹ kó o kàn gbà pé òótọ́ ni ẹfolúṣọ̀n?