Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÌBÉÈRÈ 10

Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?

Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?

ÌDÍ TỌ́RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Bíbélì sọ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lọ́rọ̀ yìí, a jẹ́ pé Bíbélì lè tọ́ ẹ sọ́nà nìyẹn.

LO MÁA ṢE?

Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: David ń wa mọ́tò lọ ní ibì kan tí kò dé rí. Àwọn àkọlé àtàwọn ilé tó ń rí jẹ́ kó mọ̀ pé ibi tóun ń lọ kọ́ lòun wà yìí. À ṣé David ti ṣìnà. Ó ní láti jẹ́ pé ó ti yà níbi tí kò yẹ kó ti yà.

Tó bá jẹ́ ìwọ ni David, kí lo máa ṣe?

RÒ Ó WÒ NÁ!

Ohun mélòó kan wà tó o lè ṣe:

  1. O lè ní káwọn èèyàn júwe ọ̀nà fún ẹ.

  2. O lè lo máàpù tàbí ẹ̀rọ tó máa ń jẹ́ kéèyàn mọ̀nà, ìyẹn GPS.

  3. O lè máa wa mọ́tò ẹ̀ lọ, lérò pé tó bá pẹ́ tó o ti ń wa mọ́tò kiri, wàá débi tó ò ń lọ.

Ó ṣe kedere pé àbá kẹta yìí ò lè ṣiṣẹ́.

Èyí èkejì ṣì dáa jú àkọ́kọ́ lọ, ó ṣe tán, máàpù tàbí ẹ̀rọ̀ ajúwe-ọ̀nà á wà lọ́wọ́ ẹ títí tó o fi máa débi tó ò ń lọ, á sì máa sọ bó o ṣe máa rìn ín fún ẹ.

Bẹ́ẹ̀ náà ni Bíbélì ṣe lè tọ́ ẹ sọ́nà.

Ìwé tó tà jù lọ láyé ni Bíbélì, ó sì máa

  • tọ́ ẹ sọ́nà kó o lè yanjú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé

  • jẹ́ kó o mọ irú ẹni tíwọ fúnra ẹ jẹ́, á sì tún ayé ẹ ṣe

  • jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dáa jù lọ

 BÓ O ṢE LÈ RÍ ÌDÁHÙN SÁWỌN ÌBÉÈRÈ PÀTÀKÌ NÍPA ÌGBÉSÍ AYÉ

Àtìgbà tá a ti mọ ọ̀rọ̀ sọ la ti ń béèrè ìbéèrè.

  • Kí ló dé tójú ọ̀run fi funfun?

  • Kí ni wọ́n fi dá àwọn ìràwọ̀?

Tó bá sì yá, àá bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ìbéèrè nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé.

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ọjọ́ pẹ́ táwọn ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí ti wà nínú Bíbélì?

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé ìtàn àròsọ àti ìtàn àtẹnudẹ́nu ló kún inú Bíbélì, pé kò wúlò lóde òní tàbí pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kì í tètè yéèyàn. Àmọ́, ṣé Bíbélì fúnra rẹ̀ ló níṣòro àbí ohun táwọn èèyàn ti gbọ́ nípa Bíbélì gangan ni ìṣòro? Ṣé kì í ṣe pé ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀?

Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn rò pé Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló ń darí ayé. Báwo ló ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ayé yìí ti dà rú! Ó kún fún ìrora àti ìyà, àìsàn àti ikú, ipò òṣì àti àjálù. Ǹjẹ́ Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa lè fa gbogbo nǹkan yìí?

Ṣé wàá fẹ́ mọ ìdáhùn? Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu tó o bá mọ ẹni tí Bíbélì sọ pé ó ń darí ayé!

Wàá ti kíyè sí i pé orí Bíbélì ni gbogbo àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé yìí dá lé. Ó dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú pé inú Bíbélì la ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dára jù lọ. Ìdí sì ni pé “Ọlọ́run [ló] mí sí [Bíbélì], ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.” (2 Tímótì 3:16, 17) O ò rí i pé ó yẹ kó o ṣàyẹ̀wò ìwé àtayébáyé tọ́rọ̀ inú ẹ̀ ṣì bágbà mu yìí!