Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ORÍ 15

Ẹ̀kọ́ Nípa Jíjẹ́ Onínúure

Ẹ̀kọ́ Nípa Jíjẹ́ Onínúure

ǸJẸ́ o mọ ohun tí à ń pè ní ẹ̀tanú?— Ẹ̀tanú ni pé kí èèyàn máà fẹ́ràn ẹnì kan nítorí pé àwọ̀ ara onítọ̀hún yàtọ̀ tàbí pé èdè tirẹ̀ yàtọ̀ sí tiwa. Nítorí náà, ẹni tó bá ń rò pé èèyàn burúkú ni ẹnì kan tàbí tó ka ẹnì kan sí èèyàn burúkú láìjẹ́ pé ó ti mọ ìwà onítọ̀hún dáadáa jẹ́ ẹlẹ́tanú.

Ǹjẹ́ o rò pé ó dára kí á kórìíra èèyàn ṣáájú ká tó mọ irú ẹni tó jẹ́ tàbí kí á kórìíra rẹ̀ torí pé bó ṣe rí yàtọ̀ sí ti àwọn èèyàn yòókù?— Rárá o, ẹ̀tanú kò tọ̀nà, kò sì dára. Kò dára láti máa kanra mọ́ ẹnì kan nítorí pé ìrísí rẹ̀ yàtọ̀ sí tiwa.

Ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí wò. Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan tí àwọ̀ ara rẹ̀ yàtọ̀ sí tìrẹ tàbí tí ó ń sọ èdè tí ó yàtọ̀ sí tìrẹ?— Bóyá o tiẹ̀ lè mọ àwọn èèyàn tí ìrísí wọn yàtọ̀ nítorí pé wọ́n fara pa rí tàbí pé àìsàn kan ṣe wọ́n. Ṣé ò ń fi inú rere hàn sí àwọn tí ìrísí wọn yàtọ̀ sí tìrẹ, ṣé o sì fẹ́ràn wọn?—

Irú ìwà wo ló yẹ ká máa hù sí àwọn tó bá yàtọ̀ sí wa?

Tí a bá fetí sílẹ̀ sí Jésù Kristi Olùkọ́ Ńlá náà, a óò máa fi inú rere hàn sí gbogbo èèyàn. Kò yẹ kí á máa bínú sí ẹnì kan nítorí orílẹ̀-èdè tí ó ti wá tàbí nítorí pé ó ní àwọ̀ ara dúdú tàbí funfun. Ó yẹ kí á máa fi inú rere hàn sí ẹni náà. Lóòótọ́ gbogbo èèyàn kọ́ ló gbà pé ó dára láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wa nìyẹn. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ yẹn.

Ọmọ Júù kan tí wọ́n ti kọ́ ní ìwà ẹ̀tanú sí àwọn ẹlòmíràn wá bá Jésù, ó sì béèrè pé, ‘Kí ni kí n máa ṣe láti lè wà láàyè títí láé?’ Jésù mọ̀ pé ọkùnrin yìí yóò fẹ́ kí òun sọ pé kí ó máa fi inú rere hàn sí kìkì àwọn èèyàn tí wọ́n bá jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà tàbí ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà. Nítorí náà, dípò tí Jésù yóò fi fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè yìí, ó béèrè  lọ́wọ́ ọkùnrin náà pé: ‘Kí ni Òfin Ọlọ́run ní kí á ṣe?’

Ọkùnrin náà dáhùn pé: ‘Kí ìwọ fi gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ bí ara rẹ.’ Jésù sọ pé: ‘Ìdáhùn rẹ tọ́. Máa ṣe èyí, ìwọ yóò sì rí ìyè.’

Àmọ́ ọkùnrin náà kò fẹ́ fi inú rere hàn sí àwọn èèyàn tí kì í ṣe ẹ̀yà tirẹ̀ tàbí kí ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Nítorí náà ó gbìyànjú láti wá àwáwí. Ó béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Ó lè máa retí pé kí Jésù sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ni aládùúgbò rẹ” tàbí, “Àwọn tí ẹ jọ wá láti ibì kan náà ni.” Àmọ́ láti dáhùn ìbéèrè rẹ̀ Jésù sọ ìtàn kan nípa Júù kan àti ará Samáríà kan. Ìtàn náà lọ báyìí.

Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ìlú Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò. Júù ni ọkùnrin náà. Bí ó ṣe ń rìn lọ, ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn olè. Wọ́n lù ú bolẹ̀, wọ́n sì gba gbogbo owó rẹ̀ àti aṣọ rẹ̀. Àwọn olè yìí nà án, wọ́n sì ṣe é léṣe. Bí wọ́n ṣe rí i pé ó kù díẹ̀ kí ó kú, wọ́n wá fi í sílẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà.

Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, àlùfáà kan ń gba ọ̀nà yẹn bọ̀. Ó rí ọkùnrin tí wọ́n ti ṣe léṣe gan-an yẹn. Tó bá jẹ́ ìwọ ni kí lo máa ṣe?— Àlùfáà  yìí gba ẹ̀gbẹ́ kejì ọ̀nà yẹn ó sì kọjá lọ. Kò tiẹ̀ dúró. Kò ṣe ohunkóhun láti ran ọkùnrin náà lọ́wọ́.

Lẹ́yìn náà, ọkùnrin mìíràn tó ń sin Ọlọ́run déédéé ń gba ọ̀nà yẹn sọ̀ kalẹ̀ bọ̀. Ọmọ Léfì ni, ó lọ ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run ní tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Ǹjẹ́ ó dúró láti ran ọkùnrin náà lọ́wọ́?— Kò dúró o. Ohun tí àlùfáà yẹn ṣe gẹ́lẹ́ lòun pẹ̀lú ṣe.

Níkẹyìn, ará Samáríà kan ń gba ọ̀nà yẹn bọ̀. Ǹjẹ́ o rí i tó ń bọ̀ ní ọ̀kánkán yẹn?— Ó rí Júù yẹn níbi tó dùbúlẹ̀ sí, tí ọgbẹ́ pọ̀ lára rẹ̀ gan-an. Wàyí o, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Samáríà àti àwọn Júù kò fẹ́ràn ara wọn rárá. (Jòhánù 4:9) Ṣé ará Samáríà yìí á fi ọkùnrin náà sílẹ̀ láì ràn án lọ́wọ́? Ǹjẹ́ á sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘Èé ṣe tí mo fi máa  ran Júù yìí lọ́wọ́? Bí mo bá fara pa kò ṣáà ní ràn mí lọ́wọ́’?

Kí nìdí tí ará Samáríà náà fi jẹ́ aládùúgbò rere?

Ó dára, ará Samáríà náà wo ọkùnrin náà tó dùbúlẹ̀ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àánú rẹ̀ ṣe é. Kò lè fi í sílẹ̀ níbẹ̀ kí ó kú dà nù. Nítorí náà, ó sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí ẹranko tó gùn, ó lọ bá ọkùnrin náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú ọgbẹ́ rẹ̀. Ó tú òróró àti ọtí wáìnì sí àwọn ọgbẹ́ náà. Èyí yóò jẹ́ kí àwọn ọgbẹ́ yìí sàn. Lẹ́yìn náà, ó fi aṣọ di àwọn ọgbẹ́ náà.

Ará Samáríà náà wá rọra gbé ọkùnrin tó fara pa náà sórí ẹranko rẹ̀. Wọ́n wá rọra ń lọ lójú ọ̀nà títí wọ́n fi dé ilé èrò, tàbí ilé àgbàwọ̀ kékeré kan. Ará Samáríà yìí gba yàrá kan fún ọkùnrin náà níbẹ̀, ó sì tọ́jú rẹ̀ dáadáa.

Jésù wá béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tí ó ń bá sọ̀rọ̀ pé: ‘Nínú àwọn mẹ́ta yìí, ta ni o rò pé ó jẹ́ aládùúgbò rere?’ Kí lo máa sọ? Ṣé àlùfáà yẹn ni tàbí ọmọ Léfì náà, tàbí ará Samáríà náà?—

Ọkùnrin náà dáhùn pé: ‘Ẹni tó dúró tó tọ́jú ọkùnrin tó fara pa yẹn ni aládùúgbò rere.’ Jésù sọ pé: ‘O gbà á. Máa bá ọ̀nà rẹ lọ, kí ìwọ alára sì máa ṣe bákan náà.’—Lúùkù 10:25-37.

Ǹjẹ́ ìtàn tó dùn kọ́ nìyẹn? Ó jẹ́ ká mọ ẹni tó jẹ́  aládùúgbò wa kedere. Kì í ṣe àwọn ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ nìkan. Kì í sì í ṣe kìkì àwọn èèyàn tó ní àwọ̀ dúdú tàbí àwọ̀ funfun bíi tiwa tàbí àwọn tó ń sọ èdè kan náà pẹ̀lú wa. Jésù kọ́ wa pé ká máa fi inú rere hàn sí àwọn èèyàn, láìka ìlú tí wọ́n ti wá sí, láìka bí ìrísí wọn ṣe rí, láìka èdè tí wọ́n bá ń sọ sí.

Bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe ń ṣe nìyẹn. Òun kì í ṣe ẹ̀tanú. Jésù sọ pé: ‘Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run máa ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára èèyàn burúkú àti èèyàn rere. Ó ń mú kí òjò rọ̀ sórí èèyàn rere àti àwọn tí kì í ṣe èèyàn rere.’ Nítorí náà, a ní láti máa fi inú rere hàn sí gbogbo èèyàn, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ń ṣe.—Mátíù 5:44-48.

Báwo lo ṣe lè jẹ́ aládùúgbò rere?

Nítorí náà, tí o bá rí ẹni tó fara pa, kí lo máa ṣe?— Bí ẹni yẹn bá jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ńkọ́, tàbí tí àwọ̀ ara rẹ̀ bá yàtọ̀ sí tìrẹ? Ọmọnìkejì rẹ ṣì ni, o yẹ kí o ràn án lọ́wọ́. Bí o bá rí i pé o kò lágbára láti ràn án lọ́wọ́ nítorí pé o jẹ́ ọmọ kékeré, o lè lọ bẹ ẹni tó dàgbà jù ọ́ lọ pé kó ràn án lọ́wọ́. Tàbí kó o tilẹ̀ pe olùkọ́ rẹ tàbí ọlọ́pàá kí wọ́n ràn án lọ́wọ́. Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o fi inú rere hàn nìyẹn bíi ti ọkùnrin ará Samáríà yẹn.

Olùkọ́ Ńlá ń fẹ́ kí á jẹ́ onínúure. Ó fẹ́ kí á máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, irú ẹni tó wù kí wọ́n jẹ́. Ìyẹn ló jẹ́ kí ó sọ ìtàn aláàánú ará Samáríà yìí.

Láti lè kọ́ ẹ̀kọ́ sí i nípa bí ó ṣe yẹ kí á máa fi inú rere hàn sí àwọn èèyàn láìka ẹ̀yà tí wọ́n ti wá tàbí orílẹ̀-èdè wọn sí, ka Òwe 19:22; Ìṣe 10:34, 35, àti Ìṣe 17:26.