Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 APÁ 6

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Ṣe Kẹ́yìn

“Ọba rẹ ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.”—Mátíù 21:5

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Ṣe Kẹ́yìn

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 101

Wọ́n Lọ Jẹun Nílé Símónì ní Bẹ́tánì

Màríà àbúrò Lásárù ṣe nǹkan kan tó dá àríyànjiyàn sílẹ̀, àmọ́ Jésù gbèjà rẹ̀.

ORÍ 102

Ọba Gun Ọmọ Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Wọ Jerúsálẹ́mù

Àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ti wà láti ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún ṣẹ sí Jésù lára.

ORÍ 103

Jésù Fọ Tẹ́ńpìlì Mọ́ Lẹ́ẹ̀kan Sí I

Ó jọ pé òwò tó dáa làwọn tó ń tajà nínú tẹ́ńpìlì yẹn ń ṣe, kí wá nìdí tí Jésù fi pè wọ́n lólè?

ORÍ 104

Lẹ́yìn Táwọn Júù Gbọ́ Ohùn Ọlọ́run, Ṣé Wọ́n Gba Jésù Gbọ́?

Ṣé ìyàtọ̀ wà nínú kéèyàn nígbàgbọ́ nínú Jésù àti kéèyàn fi hàn pé òun nígbàgbọ́ nínú rẹ̀?

ORÍ 105

Jésù Fi Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Kan Kọ́ Wọn Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìgbàgbọ́

Jésù jẹ́ káwọn èèyàn mọ bó ṣe máa ń rí tí ìgbàgbọ́ èèyàn bá lágbára, ó sì ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run ò fi gba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.

ORÍ 106

Àpèjúwe Méjì Nípa Ọgbà Àjàrà

Wàá rí ìtumọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa bàbá kán tó ní kí ọmọ òun lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà àti àpèjúwe tó ṣe nípa ọkùnrin kan tó jẹ́ pé èèyàn burúkú làwọn tó ń bá a ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà rẹ̀.

ORÍ 107

Ọba Kan Pe Àwọn Èèyàn Wá Síbi Ayẹyẹ Ìgbéyàwó

Ṣe ni Jésù fi àpèjúwe yìí sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

ORÍ 108

Ìdáhùn Jésù Ò Jẹ́ Káwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Rí I Mú

Jésù kọ́kọ́ pa àwọn Farisí lẹ́nu mọ́, lẹ́yìn náà àwọn Sadusí, nígbà tó yá, ó pa gbogbo àwọn alátakò rẹ̀ lẹ́nu mọ́.

ORÍ 109

Ó Dẹ́bi Fáwọn Aṣáájú Ìsìn Tó Ń Ta Kò Ó

Kí nìdí tí Jésù ò fi gbàgbàkugbà fún àwọn aṣáájú ìsìn yẹn?

ORÍ 110

Ọjọ́ Tí Jésù Wá sí Tẹ́ńpìlì Kẹ́yìn

Jésù lo àpẹẹrẹ opó to jẹ́ aláìní láti kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan.

ORÍ 111

Àwọn Àpọ́sítélì Ní Kí Jésù Fún Àwọn Ní Àmì

Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ṣé ó ṣeé ṣe kó tún ṣe lọ́jọ́ iwájú lọ́nà tó lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?

ORÍ 112

Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Wúńdíá Mẹ́wàá Kọ́ Wa

Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé ìdajì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa jẹ́ òmùgọ̀, tí ìdajì á sì jẹ́ olóye?

ORÍ 113

Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Tálẹ́ńtì Kọ́ Wa

Àpèjúwe tí Jésù sọ ló jẹ́ ká rí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Gbogbo ẹni tó bá ní, a máa fi kún èyí tó ní.”

ORÍ 114

Kristi Ṣèdájọ́ Àgùntàn àti Ewúrẹ́

Jésù fi àpèjúwe kan tó wọni lọ́kàn ṣàlàyé ohun tó fi máa ṣèdájọ́ lọ́jọ́ iwájú.

ORÍ 115

Ìrékọjá Tí Jésù Máa Ṣe Kẹ́yìn Ń Sún Mọ́lé

Kí ló yani lẹ́nu nípa ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà tí àwọn aṣáájú ìsìn sọ pé àwọn máa san fún Júdásì kó lè sọ bí wọ́n á ṣe mú Jésù?

ORÍ 116

Jésù Kọ́ Wọn Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Níbi Ìrékọjá Tó Ṣe Kẹ́yìn

Jésù ṣiṣẹ́ tí ẹrú máa ń ṣe, ó sì ya àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́nu.

ORÍ 117

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

Jésù dá ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lè máa ṣe é lọ́dọọdún .

ORÍ 118

Wọ́n Jiyàn Nípa Ẹni Tó Tóbi Jù

Àwọn àpọ́sítélì ti yára gbàgbé ohun tí Jésù kọ́ wọn nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn.

ORÍ 119

Jésù Ni Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè

Jésù kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní òótọ́ pàtàkì kan nípa bí wọ́n ṣe lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.

ORÍ 120

Béèyàn Ṣe Lè Dà Bí Ẹ̀ka Tó Ń So Èso, Kó sì Di Ọ̀rẹ́ Jésù

Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe ń “so èso”?

ORÍ 121

“Ẹ Mọ́kàn Le! Mo Ti Ṣẹ́gun Ayé”

Báwo ni Jésù ṣe ṣẹ́gun ayé nígbà tó jẹ pé ṣe làwọn èèyàn pa á?

ORÍ 122

Àdúrà Tí Jésù Gbà Kẹ́yìn ní Yàrá Tó Wà Lókè

Jésù jẹ́ ká mọ pé òun tún ṣe ohun mí ì tó ṣe pàtàkì ju bóun ṣe jẹ káwọn èèyàn rí ìgbàlà.

ORÍ 123

Jésù Gbàdúrà Nígbà Tí Ẹ̀dùn Ọkàn Bá A

Kí nìdí tí Jésù fi gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Mú ife yìí kúrò lórí mi”? Ṣé kò fẹ́ ra àwa èèyàn pa dà mọ́ ni?

ORÍ 124

Júdásì Da Jésù, Wọ́n sì Fàṣẹ Ọba Mú Jésù

Júdásì mọ ibi tó ti máa rí Jésù bó tiẹ̀ jẹ́ pé àárín òru ni.

ORÍ 125

Wọ́n Mú Jésù Lọ Sọ́dọ̀ Ánásì àti Káyáfà

Wọ́n gbọ́ ẹjọ́ Jésù lọ́nà tí kò bófin mu.

ORÍ 126

Pétérù Sẹ́ Jésù Nílé Káyáfà

Ó ṣe jẹ́ pé Pétérù tó nígbàgbọ́, tó sì sún mọ́ Ọlọ́run ló yára sọ pé òun ò mọ Jésù rí?

ORÍ 127

Jésù Jẹ́jọ́ Níwájú Sàhẹ́ndìrìn àti Pílátù

Àwọn aṣáájú ìsìn Júù sọ ohun tó fi èrò burúkú tó wà lọ́kàn wọn hàn.

ORÍ 128

Pílátù àti Hẹ́rọ́dù Rí I Pé Jésù Ò Jẹ̀bi

Kí nìdí tí Pílátù fi ní kí wọ́n mú Jésù lọ bá Hẹ́rọ́dù kóun náà lè gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀? Ṣé Pílátù ò lágbára láti ṣèdájọ́ Jésù ni?

ORÍ 129

Pílátù Sọ Pé: “Ẹ Wò Ó! Ọkùnrin Náà Nìyí!”

Pílátù náà gbà pé Jésù láwọn ànímọ́ tọ́ ṣàrà ọ̀tọ̀.

ORÍ 130

Ó Fa Jésù Lé Wọn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Lọ Pa Á

Kí nìdí tí Jésù fi sọ fáwọn obìnrin tó ń sunkún pé kí wọ́n sunkún torí ara wọn àtàwọn ọmọ wọn dípò tí wọ́n fi ń sunkún torí òun?

ORÍ 131

Ọba Kan Ń Jìyà Láìṣẹ̀ Lórí Òpó Igi

Jésù ṣèlérí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún ọ̀kan lára àwọn ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

ORÍ 132

“Ó Dájú Pé Ọmọ Ọlọ́run Ni Ọkùnrin Yìí”

Òkùnkùn dédé sú bolẹ̀ nígbà tí Jésù kú, ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé, aṣọ ìdábùú tẹ́ńpìlì sì ya sí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn nǹkan yìí jẹ́rìí sí ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa Jésù.

ORÍ 133

Wọ́n Ṣètò Òkú Jésù, Wọ́n sì Lọ Sin Ín

Kí nìdí tí wọ́n fi tètè sin Jésù kí oòrùn tó wọ̀?

ORÍ 134

Ọlọ́run Ti Jí Jésù Dìde, Ibojì Rẹ̀ sì Ti Ṣófo!

Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó kọ́kọ́ fara han àwọn obìnrin dípò kó fara han àwọn àpọ́sítélì rẹ̀.

ORÍ 135

Jésù Fara Han Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́yìn Tó Jíǹde

Kí ni Jésù ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ kó lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ti jíǹde?

ORÍ 136

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Létíkun Gálílì

Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù sọ ohun tí Pétérù máa ṣe fún un láti fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ òun.

ORÍ 137

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Rí Jésù Ṣáájú Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì

Láàárín ọjọ́ tí Jésù jíǹde sí ọjọ́ tó gòkè lọ sọ́run, léraléra ló sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọ́n máa gba ẹ̀bùn kan, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe máa lo ẹ̀bùn náà.

ORÍ 138

Kristi Wà Lọ́wọ́ Ọ̀tún Ọlọ́run

Kí ni Jésù á máa ṣe bó ṣe ń dúró dìgbà tí Ọlọ́run máa fún un láṣẹ láti dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá rẹ̀?

ORÍ 139

Jésù Parí Iṣẹ́ Rẹ̀, Ó sì Máa Sọ Ayé Di Párádísè

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jésù ṣì ní láti ṣe kó tó dá Ìjọba pa dà fún Baba rẹ̀ àti Ọlọ́run rẹ̀.