Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ORÍ 100

Àpèjúwe Mínà Mẹ́wàá

Àpèjúwe Mínà Mẹ́wàá

LÚÙKÙ 19:11-28

  • JÉSÙ SỌ ÀPÈJÚWE MÍNÀ MẸ́WÀÁ

Jerúsálẹ́mù ni Jésù ń lọ, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilé Sákéù lòun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ṣì wà. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà gbà pé Jésù máa tó di Ọba “Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 19:11) Àmọ́ ohun tí Jésù sọ ò yé wọn, bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ tó sọ nípa ikú rẹ̀ ò yé wọn. Torí náà, ó sọ àpèjúwe kan kí wọ́n lè rí i pé Ìjọba náà ṣì máa pẹ́ díẹ̀.

Ó sọ pé: “Ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní ilé ọlá rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ kan tó jìnnà kó lè lọ gba agbára láti jọba, kó sì pa dà.” (Lúùkù 19:12) Irú ìrìn àjò yìí máa ń pẹ́. Ó dájú pé Jésù ni ‘ọkùnrin tí wọ́n bí ní ilé ọlá’ tó rìnrìn àjò lọ sí “ilẹ̀ kan tó jìnnà,” ìyẹn ọ̀run, kí Baba rẹ̀ lè fún un ní agbára láti jọba.

Nínú àpèjúwe yìí, kí ‘ọkùnrin tí wọ́n bí ní ilé ọlá’ yẹn tó lọ, ó pe àwọn ẹrú rẹ̀ mẹ́wàá, ó sì fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní mínà fàdákà kan, ó ní: “Ẹ máa fi ṣòwò títí màá fi dé.” (Lúùkù 19:13) Owó tó ṣeyebíye ni mínà fàdákà. Torí náà, tí àgbẹ̀ kan bá fi ohun tó lé ní oṣù mẹ́ta ṣiṣẹ́, mínà kan ni wọ́n máa san fún un.

Ó ṣeé ṣe kó yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pé àwọn làwọn dà bí ẹrú mẹ́wàá tó wà nínú àpèjúwe yẹn, torí Jésù ti fi wọ́n wé àwọn òṣìṣẹ́ tó ń kórè tẹ́lẹ̀. (Mátíù 9:35-38) Kì í ṣe ọkà ni Jésù ní kí wọ́n lọ kórè. Ohun tó ní lọ́kàn ni pé kí wọ́n túbọ̀ lọ wá àwọn ọmọ ẹ̀yìn sí i, káwọn tó máa wà nínú Ìjọba Ọlọ́run lè pọ̀. Torí náà, wọ́n máa lo gbogbo ohun tí wọ́n ní láti wá wọn.

Kí ni nǹkan míì tí Jésù jẹ́ ká mọ̀ nínú àpèjúwe yìí? Ó sọ pé àwọn aráàlú “kórìíra [ọkùnrin tí wọ́n bí ní ilé ọlá náà], wọ́n sì rán àwọn ikọ̀ tẹ̀ lé e, kí wọ́n sọ pé, ‘A ò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jọba lé wa lórí.’” (Lúùkù 19:14) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀ pé àwọn Júù ò gba ti Jésù, kódà àwọn kan lára wọn fẹ́ pa á. Lẹ́yìn tí Jésù kú, tó sì pa dà sí ọ̀run, ó wá hàn pé àwọn Júù kórìíra rẹ̀ torí wọ́n fojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ rí màbo. Àwọn alátakò yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé wọn ò fẹ́ kí Jésù jọba lé àwọn lórí.—Jòhánù 19:15, 16; Ìṣe 4:13-18; 5:40.

Àmọ́ ní ti àwọn ẹrú mẹ́wàá yẹn, kí ni wọ́n fi mínà wọn ṣe kí ‘ọkùnrin tí wọ́n bí ní ilé ọlá’ náà tó pa dà dé lẹ́yìn tó gba “agbára láti jọba”? Jésù sọ pé: “Nígbà tó pa dà dé lẹ́yìn tó gba agbára láti jọba, ó pe àwọn ẹrú tó fún ní owó náà, kó lè mọ èrè tí wọ́n jẹ nínú òwò tí wọ́n ṣe. Èyí àkọ́kọ́ wá bá a, ó sọ pé, ‘Olúwa, mo fi mínà rẹ jèrè mínà mẹ́wàá.’ Ó sọ fún un pé, ‘O káre láé, ẹrú rere! Torí o ti fi hàn pé o jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tó kéré gan-an, jẹ́ aláṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’ Ìkejì wá dé, ó sọ pé, ‘Olúwa, mo fi mínà rẹ jèrè mínà márùn-ún.’ Ó sọ fún ẹni yìí náà pé, ‘Ìwọ náà, máa bójú tó ìlú márùn-ún.’”—Lúùkù 19:15-19.

Tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá gbà pé àwọn làwọ́n dà bí àwọn ẹrú tó lo gbogbo ohun tí wọ́n ní láti wá ọmọ ẹ̀yìn sí i, ó dájú pé inú Jésù máa dùn. Ó sì dájú pé ó máa san wọ́n lẹ́san torí iṣẹ́ àṣekára wọn. Òótọ́ ni pé nǹkan ò rí bákan náà fún gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ohun tí wọ́n lè ṣe sì yàtọ̀ síra. Ṣùgbọ́n tí Jésù bá ti gba “agbára láti jọba,” ó máa rí bí wọ́n ṣe fòótọ́ inú sapá láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, á sì bù kún wọn.—Mátíù 28:19, 20.

Jésù wá sọ ohun kan tó yàtọ̀ bó ṣe ń parí àpèjúwe náà lọ, ó ní: “Àmọ́ ẹrú míì dé, ó sì sọ pé, ‘Olúwa, mínà rẹ rèé tí mo fi pa mọ́ sínú aṣọ. Ṣó o rí i, ẹ̀rù rẹ ló bà mí, torí pé èèyàn tó le ni ọ́; ohun tó ò fi sílẹ̀ lo máa ń gbà, ohun tó ò sì gbìn lo máa ń ká.’ Ó sọ fún un pé, ‘Ẹrú burúkú, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ni mo fi dá ọ lẹ́jọ́. O mọ̀, àbí, pé èèyàn  tó le ni mí, ohun tí mi ò fi sílẹ̀ ni mò ń gbà, ohun tí mi ò sì gbìn ni mò ń ká? Kí ló dé tó ò fi owó mi sí báǹkì? Tí n bá sì dé, ǹ bá gbà á pẹ̀lú èlé.’ Ló bá sọ fún àwọn tó dúró nítòsí pé, ‘Ẹ gba mínà náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fún ẹni tó ní mínà mẹ́wàá.’”—Lúùkù 19:20-24.

Torí pé ẹrú yìí ò ṣe ohun tó máa jẹ́ kí ọrọ̀ ọ̀gá rẹ̀ pọ̀ sí i, ó pàdánù nǹkan tó pọ̀. Àwọn àpọ́sítélì ń retí ìgbà tí Jésù máa di ọba Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ torí ohun tí Jésù sọ nípa ẹrú tó kẹ́yìn yìí, ó ṣeé ṣe kó yé wọn pé tí wọn ò bá ṣiṣẹ́ kára, wọn ò ní lè dénú Ìjọba yẹn.

Ó dájú pé ohun tí Jésù sọ máa mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ yìí fi kún ìsapá wọn. Jésù parí ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó ní: “Mò ń sọ fún yín, gbogbo ẹni tó bá ní, a máa fi kún èyí tó ní, àmọ́ ẹni tí kò bá ní, a máa gba èyí tó ní pàápàá lọ́wọ́ rẹ̀.” Ó wá fi kún un pé ìparun ló máa gbẹ̀yìn àwọn ọ̀tá òun, tí wọn ò fẹ́ kí òun “jọba lórí wọn.” Lẹ́yìn náà, Jésù lọ sí Jerúsálẹ́mù.—Lúùkù 19:26-28.