ORÍ 7
Àwọn Awòràwọ̀ Wá Sọ́dọ̀ Jésù
-
“ÌRÀWỌ̀” KAN DARÍ ÀWỌN AWÒRÀWỌ̀ LỌ SÍ JERÚSÁLẸ́MÙ ÀTI SỌ́DỌ̀ JÉSÙ
Àwọn ọkùnrin kan wá láti Ìlà Oòrùn, awòràwọ̀ ni wọ́n. Àwọn awòràwọ̀ máa ń wo ibi tí àwọn ìràwọ̀ wà, wọ́n sì máa ń sọ pé àwọn lè fìyẹn mọ ìtumọ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé àwọn èèyàn. (Àìsáyà 47:13) Nígbà tí wọ́n wà nílùú wọn ní Ìlà Oòrùn, wọ́n rí “ìràwọ̀” kan, wọ́n sì tẹ̀ lé e lọ sí ọ̀nà tó jìn gan-an. Kì í ṣe Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n tẹ̀ lé e lọ, Jerúsálẹ́mù ni.
Nígbà tí àwọn awòràwọ̀ náà débẹ̀, wọ́n béèrè pé: “Ibo ni ọba àwọn Júù tí wọ́n bí wà? Torí a rí ìràwọ̀ rẹ̀ nígbà tí a wà ní Ìlà Oòrùn, a sì ti wá ká lè forí balẹ̀ fún un.”—Mátíù 2:1, 2.
Hẹ́rọ́dù ọba Jerúsálẹ́mù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, inú sì bí i gan-an. Ló bá pe àwọn olórí àlùfáà àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù míì, ó sì bi wọ́n nípa ibi tí wọ́n ti máa bí Kristi. Wọ́n tọ́ka sí Ìwé Mímọ́, wọ́n sì dá a lóhùn pé, ‘Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni.’ (Mátíù 2:5; Míkà 5:2) Hẹ́rọ́dù wá ránṣẹ́ pe àwọn awòràwọ̀ náà ní bòókẹ́lẹ́, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ fara balẹ̀ wá ọmọ kékeré náà, tí ẹ bá sì ti rí i, ẹ pa dà wá jábọ̀ fún mi, kí èmi náà lè lọ forí balẹ̀ fún un.” (Mátíù 2:8) Àmọ́ irọ́ ni, torí kí Hẹ́rọ́dù lè pa ọmọ náà ló ṣe ń wá a!
Lẹ́yìn táwọn awòràwọ̀ náà lọ, ohun àgbàyanu kan ṣẹlẹ̀. “Ìràwọ̀” tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n wà ní Ìlà Oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí í lọ níwájú wọn. Ó ṣe kedere pé ìràwọ̀ yìí kì í ṣe ìràwọ̀ lásán, ẹnì kan ló dìídì ń lò ó láti darí wọn. Àwọn awòràwọ̀ náà ń tẹ̀ lé e títí ó fi dúró lórí ilé tí Jósẹ́fù àti Màríà pẹ̀lú ọmọ wọn kékeré ń gbé.
Nígbà táwọn awòràwọ̀ náà wọnú ilé, wọ́n rí Màríà àti ọmọ kékeré kan, Jésù ni. Ni àwọn awòràwọ̀ náà bá forí balẹ̀ fún un, wọ́n sì fún un ní wúrà, oje igi tùràrí àti òjíá. Lẹ́yìn náà, wọ́n fẹ́ pa dà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù, àmọ́ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wọn lójú àlá pé wọn ò gbọ́dọ̀ pa dà síbẹ̀. Bí wọ́n ṣe gba ọ̀nà ibòmíì lọ sí ìlú wọn nìyẹn.
Ta lo rò pé ó fi “ìràwọ̀” yẹn darí àwọn awòràwọ̀ náà? Má gbàgbé pé ọ̀dọ̀ Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù kọ́ ló darí wọn lọ ní tààràtà. Ṣe ló kọ́kọ́ darí wọn lọ sí Jerúsálẹ́mù, níbi tí wọ́n ti pàdé Ọba Hẹ́rọ́dù tó fẹ́ pa Jésù. Ká ní Ọlọ́run ò dá sí ọ̀rọ̀ náà ni, tí kò kìlọ̀ fún àwọn awòràwọ̀ náà pé kí wọ́n má sọ ibi tí Jésù wà fún Hẹ́rọ́dù, Hẹ́rọ́dù ò bá rí Jésù pa. Torí náà, ó ṣe kedere pé Sátánì, ọ̀tá Ọlọ́run, ló fẹ́ pa Jésù, òun ló sì lo “ìràwọ̀” yẹn kó lè ṣiṣẹ́ ibi tó fẹ́ ṣe.