Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrántí Ikú Kristi—Friday, April 3, 2015

Ìrántí Ikú Kristi—Friday, April 3, 2015

LÁTỌJỌ́ Sátidé, March 7, 2015, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé bẹ̀rẹ̀ sí í pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá síbi tá a ti máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi kí wọ́n sì gbọ́ àlàyé nípa bí ikú Jésù Kristi ṣe ṣaráyé làǹfààní. Ọ̀sẹ̀ mẹ́rin gbáko la fi lọ káàkiri láti pe àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ìwé ìkésíni la fún àwọn èèyàn, a sọ fáwọn mí ì lórí fóònù tàbí nípasẹ̀ lẹ́tà. Ṣé àwọn èèyàn wá àbí wọn ò wá? Ẹ wo bí inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dùn tó nígbà tí 19,862,783 èèyàn pé jọ síbi Ìrántí Ikú Kristi ní Friday, April 3, 2015. A ti túbọ̀ ń koná mọ́ ìsapá wa ká lè ṣèrànwọ́ fún gbogbo àwọn tó wá lọ́jọ́ yẹn kí wọ́n lè máa dara pọ̀ mọ́ àwa èèyàn Jèhófà déédéé, káwọn náà lè máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kí wọ́n sì rí ojúure àti ìbùkún rẹ̀.Míkà 4:2.