Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÌTÀN 28

Bá a Ṣe Gba Mósè Ọmọ Ọwọ́ Là

Bá a Ṣe Gba Mósè Ọmọ Ọwọ́ Là

WO ỌMỌ kékeré yìí bó ṣe ń sunkún, tó sì di ìka ọwọ́ omidan yẹn mú. Mósè nìyí. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí omidan arẹwà yẹn jẹ́? Ọmọbìnrin Fáráò ọba Íjíbítì ni.

Ìyá Mósè gbé ọmọ rẹ̀ pa mọ́ fún odindi oṣù mẹ́ta nítorí pé kò fẹ́ káwọn ará Íjíbítì pa á. Ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé wọ́n lè rí Mósè, nítorí náà, ó ṣe nǹkan kan láti gbà á là. Kí ló ṣe?

Ó mú apẹ̀rẹ̀ kan, ó sì ṣe é lọ́nà tí omi kò fi ní lè wọ inú rẹ̀. Ó wá gbé Mósè sínú rẹ̀, ó sì gbé apẹ̀rẹ̀ náà sí àárín àwọn koríko gígùn lẹ́bàá Odò Náílì. Ó sọ fún Míríámù, ọmọ rẹ̀ obìnrin tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Mósè pé kó dúró nítòsí kó lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀.

Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni ọmọbìnrin Fáráò wá sí Odò Náílì láti wẹ̀. Lójijì, ó rí apẹ̀rẹ̀ náà láàárín àwọn koríko gígùn. Ó sọ fún ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ obìnrin pé: ‘Lọ gbé apẹ̀rẹ̀ tó wà lọ́hùn-ún yẹn wá fún mi.’ Nígbà tí ọmọbìnrin ọba ṣí apẹ̀rẹ̀ náà, ọmọ tó rí nínú rẹ̀ mà lẹ́wà o! Mósè ọmọ jòjòló ń sunkún, àánú rẹ̀ ṣe ọmọbìnrin ọba. Kò fẹ́ kí wọ́n pa á.

Ni Míríámù bá tọ̀ ọ́ wá. Òun lo rí nínú àwòrán yìí. Míríámù béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Fáráò pé: ‘Ṣé kí n lọ pe obìnrin ará Ísírẹ́lì kan wá láti máa tọ́jú ọmọ náà fún yín?’

Ọmọbìnrin ọba dáhùn pé: ‘Lọ pè é wá.’

Ni Míríámù bá yára sáré lọ sọ fún ìyá rẹ̀. Nígbà tí ìyá Mósè dé ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin ọba yìí, ọmọbìnrin ọba náà sọ pé: ‘Gbé ọmọ yìí kó o sì máa tọ́jú ẹ̀ fún mi, màá sì máa san owó fún ọ.

Nítorí náà, ìyá Mósè gan-an ló tọ́jú ọmọ òun tìkára rẹ̀. Nígbà tí Mósè dàgbà tó, ó mú un lọ fún ọmọbìnrin Fáráò, ẹni tó wá gba Mósè gẹ́gẹ́ bí ọmọ òun tìkára rẹ̀. Bí Mósè ṣe di ẹni tó dàgbà ní ilé Fáráò nìyẹn o.