Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 9

Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Láyọ̀?

Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Láyọ̀?

1. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn ṣe ìgbéyàwó tí ìdílé bá máa láyọ̀?

Ọ̀dọ̀ Jèhófà, Ọlọ́run aláyọ̀ tó fẹ́ kí ìdílé láyọ̀, ni ìròyìn ayọ̀ ti wá. (1 Tímótì 1:11) Òun ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀. Tí ìdílé bá máa láyọ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya ṣe ìgbéyàwó lọ́nà tó bá òfin mu, torí pé ó máa jẹ́ kí wọ́n lè pa ọwọ́ pọ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn. Ó yẹ kí àwọn Kristẹni tẹ̀ lé ohun tí òfin orílẹ̀-èdè wọn sọ, kí wọ́n fi orúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba.​—Ka Lúùkù 2:1, 4, 5.

Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí ìgbéyàwó rí? Ó fẹ́ kí ìgbéyàwó dà bí okùn alọ́májàá láàárín tọkọtaya. Jèhófà fẹ́ kí tọkọtaya jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. (Hébérù 13:4) Ó kórìíra ìkọ̀sílẹ̀. (Málákì 2:16) Àmọ́, ó gba àwọn Kristẹni láyè pé wọ́n lè kọ ara wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì fẹ́ ẹlòmíì tí ọkọ tàbí aya wọn bá ṣe àgbèrè.​—Ka Mátíù 19:3-6, 9.

2. Báwo ló ṣe yẹ kí tọkọtaya máa ṣe sí ara wọn?

Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin lọ́nà tí wọ́n á fi lè máa ran ara wọn lọ́wọ́ nínú ìgbéyàwó. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Ọkọ ni olórí ìdílé, ó yẹ kó máa pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò, kó sì máa kọ́ wọn nípa Ọlọ́run. Ó gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ látọkàn wá, kó má ṣe jẹ́ pé ti ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀. Tọkọtaya gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Torí pé àwọn tọkọtaya jẹ́ aláìpé, ohun pàtàkì tó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀ nínú ìgbéyàwó wọn ni pé kí wọ́n máa dárí ji ara wọn.​—Ka Éfésù 4:​31, 32; 5:22-25, 33; 1 Pétérù 3:7.

3. Ṣé ó yẹ kó o fi ọkọ tàbí aya rẹ sílẹ̀ torí pé ẹ ò láyọ̀?

Tẹ́ ẹ bá níṣòro nínú ìgbéyàwó yín, ńṣe ni kí ẹ̀yin méjèèjì rí i dájú pé ẹ̀ ń fi ìfẹ́ bá ara yín gbé. (1 Kọ́ríńtì 13:​4, 5) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sọ pé kí tọkọtaya máa wá bí wọ́n á ṣe pínyà nígbàkigbà tí wọ́n bá níṣòro.​—Ka 1 Kọ́ríńtì 7:10-13.

4. Ẹ̀yin ọmọ, kí ni Ọlọ́run fẹ́ kẹ́ ẹ máa ṣe?

Jèhófà fẹ́ kẹ́ ẹ láyọ̀. Ó fún yín ní ìmọ̀ràn tó dára jù tó máa jẹ́ kẹ́ ẹ gbádùn ìgbà ọ̀dọ́ yín. Ó fẹ́ kẹ́ ẹ kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọgbọ́n àti ìrírí àwọn òbí yín. (Kólósè 3:20) Jèhófà tún fẹ́ kẹ́ ẹ rí ayọ̀ tó wà nínú ṣíṣe ohun tí Ẹlẹ́dàá yín àti Ọmọ rẹ̀ fẹ́.​—Ka Oníwàásù 11:9–12:1; Mátíù 19:13-15; 21:​15, 16.

5. Ẹ̀yin òbí, báwo lẹ ṣe lè mú kí àwọn ọmọ yín láyọ̀?

Ó yẹ kẹ́ ẹ ṣiṣẹ́ kára kẹ́ ẹ lè pèsè oúnjẹ, ibùgbé àti aṣọ fún àwọn ọmọ yín. (1 Tímótì 5:8) Àmọ́, kí àwọn ọmọ yín tó lè láyọ̀, ẹ tún gbọ́dọ̀ kọ́ wọn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. (Éfésù 6:4) Tí ẹ̀yin fúnra yín bá ń fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, èyí á mú kí àwọn ọmọ yín rí i pé ó yẹ kí àwọn náà nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ àwọn ọmọ yín dá lé, èyí á mú kí wọ́n lè máa ronú bó ṣe tọ́.​—Ka Diutarónómì 6:4-7; Òwe 22:6.

Ara àwọn ọmọ máa ń yá gágá tẹ́ ẹ bá ń yìn wọ́n, tẹ́ ẹ sì ń fún wọn níṣìírí. Ó tún yẹ kẹ́ ẹ máa bá wọn wí, kẹ́ ẹ sì máa tọ́ wọn sọ́nà. Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kí wọ́n sá fún ìwà tó lè kó ìbànújẹ́ bá wọn. (Òwe 22:15) Síbẹ̀, ẹ má ṣe fi ìbínú tàbí ìkanra bá wọn wí.​—Ka Kólósè 3:21.

Ọ̀pọ̀ ìwé ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dìídì ṣe láti ran àwọn òbí àtàwọn ọmọ lọ́wọ́. Àwọn àlàyé tó dá lórí Bíbélì ló wà nínú àwọn ìwé náà.​—Ka Sáàmù 19:​7, 11.