Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!

Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìsíkíẹ́lì ló dá lórí bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò. Báwo ni àwọn asọtẹ́lẹ̀ náà ṣe kàn wá?

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ohun tó wù wá ni pé kí ìwé yìí mú kí ẹ túbọ̀ pinnu láti jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo torí òun nìkan ni ìjọsìn yẹ.

Àlàyé Nípa Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

Àwọn àpótí ẹ̀kọ́ àtàwọn déètì ìṣẹ̀lẹ̀ sọ àwọn nǹkan mí ì tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ lóye àwọn àlàyé tá a ṣe.

ORÍ 1

“Jèhófà Ọlọ́run Rẹ Ni O Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn”

Bí Sátánì ṣe dá ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì, kò wulẹ̀ fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ tàbí pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, ṣe ló tún gbéjà ko ìjọsìn mímọ́.

ORI 2

“Ọlọ́run Fọwọ́ Sí” Àwọn Ẹ̀bùn Wọn

Àpẹẹrẹ tí àwọn ọkùnrin onígbàgbọ́ fi lélẹ̀ jẹ́ ká rí nǹkan mẹ́rin pàtàkì téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìjọsìn mímọ́.

ORÍ 3

‘Mo Rí Ìran Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run’

Ìran tí Ìsíkíẹ́lì kọ́kọ́ rí yà á lẹ́nu gan-an. Ọ̀pọ̀ àǹfààní làwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run òde òní lè rí nínú ìran náà.

ORÍ 4

Àwọn Wo Ni “Ẹ̀dá Alààyè Tó Ní Ojú Mẹ́rin Náà”?

Jèhófà fi àwọn ohun kan han Ìsíkíẹ́lì tó jẹ́ ká lóye àwọn ohun gidi tó lè má rọrùn fún wa láti lóye.

ORÍ 5

‘Wo Iṣẹ́ Ibi Tó Ń Ríni Lára Tí Wọ́n Ń Ṣe’

Ìsíkíẹ́lì rí ohun tó ń ríni lára tó fi hàn pé orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run

ORÍ 6

“Òpin Ti Dé Bá Yín Báyìí”

Ohun tí Ìsíkíẹ́lì ṣàfihàn rẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fi bí Jèhófà ṣe máa bínú sí Jerúsálẹ́mù hàn.

ORÍ 7

Àwọn Orílẹ̀-Èdè “Á sì Wá Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”

Àwọn orílẹ̀-èdè tó pẹ̀gàn orúkọ Jèhófà tí wọ́n sì kéèràn ran àwọn èèyàn rẹ̀ ò ní lọ láìjìyà. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àjọṣe Ísírẹ́lì àtàwọn orílẹ̀-èdè yẹn?

ORÍ 8

“Èmi Yóò Yan Olùṣọ́ Àgùntàn Kan”

Ọlọ́run mí sí Ìsíkíẹ́lì láti sàsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, tó máa jẹ́ Alákòóso àti Olùṣọ́ Àgùntàn àwọn èèyàn Jèhófà, ó máa dá ìjọsìn mímọ́ pa dà títí lọ.

ORÍ 9

“Èmi Yóò Mú Kí Ọkàn Wọn Ṣọ̀kan”

Ṣé àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn Júù olóòótọ́ tó wà nígbèkùn Bábílónì kàn wá?

ORÍ 10

‘Ẹ Ó Di Alààyè’

Ìsíkíẹ́lì rí ìran kan nípa pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí egungun gbígbẹ kún inú rẹ̀. Kí ló túmọ̀ sí?

ORÍ 11

“Mo Ti Fi Ọ́ Ṣe Olùṣọ́”

Kí ni iṣẹ́ àwọn olùṣọ́? Ìkìlọ̀ wo ni wọ́n sì ń kéde?

ORÍ 12

“Èmi Yóò Sọ Wọ́n Di Orílẹ̀-Èdè Kan”

Jèhófà ṣèlérí pé òun máa mú káwọn èèyàn òun wà níṣọ̀kan.

ORÍ 13

“Ṣàlàyé Bí Tẹ́ńpìlì Náà Ṣe Rí”

Kí ni tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran túmọ̀ sí?

ORÍ 14

“Òfin Tẹ́ńpìlì Náà Nìyí”

Kí làwọn Júù tó wà nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì rí kọ́ látinú ìran tó rí nípa tẹ́ńpìlì? Báwo ni ìran náà ṣe kàn wá lóde òní?

ORÍ 15

“Èmi Yóò Fòpin sí Iṣẹ́ Aṣẹ́wó Rẹ”

Kí la lè rí kọ́ látinú àpèjúwe àwọn aṣẹ́wó tí ìwé Ìsíkíẹ́lì àti Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa wọn?

ORÍ 16

“Sàmì sí Iwájú Orí” Wọn

Bí wọ́n ṣe sàmì sí àwọn olóòótọ́ nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì ṣe pàtàkì sí wa.

ORÍ 17

“Èmi Yóò Bá Ọ Jà, Ìwọ Gọ́ọ̀gù”

Ta ni Gọ́ọ̀gù ti Ilẹ̀ Mágọ́gù, ilẹ̀ wo ló sì gbógun jà?

ORÍ 18

“Inú Á Bí Mi Gidigidi”

Jèhófà máa bínú gidigidi nígbà tí Gọ́ọ̀gù bá gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, àmọ́ Jèhófà máa gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀.

ORÍ 19

‘Gbogbo Ohun Tó Wà Níbi tí Omi Náà Ṣàn Dé Yóò Máa Wà Láàyè’

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa odò tó ń ṣàn jáde látinú tẹ́ńpìlì ti ṣẹ nígbà àtijọ́, ó ń ṣe ní lọ́wọ́lọ́wọ́ àti pé ó máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú?

ORÍ 20

“Pín Ilẹ̀ Náà Bí Ogún”

Nínú ìran, Ọlọ́run sọ fún Ìsíkíẹ́lì àtàwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn pé kí wọ́n pín Ilẹ̀ Ìlérí fún àwọn ẹ̀yà tó wà ní Ísírẹ́lì.

ORÍ 21

“Orúkọ Ìlú Náà Yóò Máa Jẹ́ Jèhófà Wà Níbẹ̀”

Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa ìlú náà àti ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀?

ORÍ 22

“Ọlọ́run Ni Kí O Jọ́sìn”

Ìwé yìí máa ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa pé Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo la máa sìn.

Àkópọ̀ Àwọn Àtúnṣe Tó Bá Òye Wa

Kí nìdí tá a fi ṣàtúnṣe sí òye tá a ní nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 1A

Kí Ni Ìjọsìn?

Kí la lè túmọ̀ ìjọsìn sí gan-an? Kí ni ìwé Ìsíkíẹ́lì sọ nípa ìjọsìn? Kí ni ìjọsìn mímọ́ wé mọ́?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 1B

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

A lè pín ìwé náà bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú rẹ̀ ṣe tẹ̀ léra àti ohun tí wọ́n dá lé.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 2A

Bá A Ṣe Lè Lóye Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì

Àwọn ohun tó wà nínú ìwé náà ni ìran, àpèjúwe, àkàwé àti àwọn àṣefihàn. Ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀ ló jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 2B

Àwọn Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Nígbà Ayé Ìsíkíẹ́lì

Àwọn wòlí ì mí ì sọ tẹ́lẹ̀ nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì. Àwọn ohun pàtàkì kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn àwọn èèyàn Ìsíkíẹ́lì nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 3A

Ìrìn Àjò Ọ̀nà Jíjìn Lọ sí Babilóníà

Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn gbà láàárín Júdà àti Bábílónì?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 4A

‘Mò Ń Wo Àwọn Ẹ̀dá Alààyè Náà’

Kí ló mú kí àwọn ẹ̀dá mẹ́rin tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìràn yàtọ̀ sí àwọn ère gìrìwò tó wà ní ilẹ̀ Ásíríà àti Babilóníà àtijọ́?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 5A

“Ọmọ Èèyàn, Ṣé Ìwọ Náà Rí I?”

Ìsíkíẹ́lì rí ohun mẹ́rin tó ń ríni lára nínú tẹ́ńpìlì àti àgbàlá tẹ́ńpìlì.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 6A

“Fá Orí Rẹ àti Irùngbọ̀n Rẹ”

Ọlọ́run ní kí Ìsíkíẹ́lì ṣe àwọn àṣefihàn láti fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 7A

Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Yí Jerúsálẹ́mù Ká

Júdà àtàwọn ilẹ̀ tó yí i ká figa gbága lọ́pọ̀ ìgbà.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 7B

Àwọn Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

Àwọn ọ̀rọ̀ kan tó jọra fara hàn léraléra nínú ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yìí.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 8A

Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà​—Igi Kédárì Ńlá

Kí nìtúmọ̀ àlá tí wọ́n fi sàsọtẹ́lẹ̀ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 17?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 8B

Àsọtẹ́lẹ̀ Mẹ́ta Nípa Mèsáyà

Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹni tá a lè fọkàn tán ló máa jẹ́ aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 9A

Jèhófà Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ​—Nígbà Àtijọ́

Ọlọ́run mí sí Ìsíkíẹ́lì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ márùn-⁠ún nípa ìtúsílẹ̀ àti ìmúbọ̀sípò.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 9B

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́dún 1919

Kí nìdí tá a fi ń sọ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì Ńlá lọ́dún 1919?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 9D

Jèhófà Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ​—Lóde Òní

Báwo làwọn ìlérí Ọlọ́run kan ṣe ṣẹ nígbà àtijọ́ àti lóde òní?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 9E

Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìgbèkùn àti Ìmúbọ̀sípò

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sára àwọn Júù tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Bábílónì àtijọ́, tí wọ́n sì pa dà bọ̀ sípò tún ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò nígbà tí Bábílónì Ńlá mú àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbèkùn tí àwọn náà sì pà dà bọ̀ sípò.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 9Ẹ

‘Àkókò Ìmúbọ̀sípò Ohun Gbogbo’

Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pétérù láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò kan tó máa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jésù bá di Ọba títí dé ìparí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 10A

Ìjọsìn Mímọ́​—Pa Dà Bọ̀ Sípò Díẹ̀díẹ̀

Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ tó mú ká lè máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù lóde òní?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 10B

Àwọn “Egungun Gbígbẹ” Àtàwọn ‘Ẹlẹ́rìí Méjì’​—Báwo Ni Wọ́n Ṣe Jọra?

Báwo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ lóde òní?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 10C

Ó Ń Mú Ká Pa Dà Dìde Dúró

Nígbà mí ì, ìṣòro lè mu wá lómi gan-an, kó sì mú kí nǹkan tojú sú wa, àmọ́ ìran nípa egungun gbígbẹ tó di alààyè lè fún wa lókun.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 11A

Díẹ̀ Lára Àwọn Olùṣọ́ Tó Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere

Wọ́n kojú àtakò, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà bí wọ́n ṣe ń kéde ìhìn rere àti ìdájọ́ Ọlọ́run.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 12A

Síso Igi Méjì Pọ̀

Àwọn wo ni igi méjì náà ń ṣàpẹẹrẹ nígbà àtijọ́ àti lóde òní?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 13A

Tẹ́ńpìlì Méjì Tó Yàtọ̀ Síra àti Ohun Tó Kọ́ Wa

Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí àti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 14A

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìran Tẹ́ńpìlì Tí Ìsíkíẹ́lì Rí

Ẹ̀kọ́ wo lo fẹ́ fi sílò nínú ìjọsìn rẹ̀ látinú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa tẹ́ńpìlì?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 15A

Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Tó Ń Ṣe Aṣẹ́wó

Àpèjúwe tí Jèhófà ṣe nípa Òhólà àti Òhólíbà jẹ́ ká mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn tó ń tàbùkù sí orúkọ mímọ́ rẹ̀ tí wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó rọ̀ mọ́ ìjọsìn mímọ́.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 16A

Ṣé Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Ni Ìlú Jerúsálẹ́mù Ṣàpẹẹrẹ?

Kí nìdí tí òye wa fi yí pa dà?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 16B

Ìgbà Wo Ni Ìkẹ́dùn, Ìkérora, Ìsàmì àti Fífọ́ Nǹkan Máa Ṣẹlẹ̀, Báwo Ló sì Ṣe Máa Ṣẹlẹ̀?

Ìran tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 9 lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ bí òpin ètò àwọn nǹkan yìí ṣe ń sún mọ́lé

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 18A

Jèhófà Kìlọ̀ Nípa Ogun Ńlá Tó Ń Bọ̀

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ogun àjàmọ̀gá tí Jèhófà máa fi pa àwọn tó ta ko òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ run.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 19A

Àwọn Odò Ìbùkún Látọ̀dọ̀ Jèhófà

Àwọn ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó kọ Bíbélì fi àpèjúwe kan náà ṣàlàyé ìbùkún Jèhófà.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 19B

Omi Kékeré Di Odò Ńlá!

Kí ni omi tó ṣàn láti ibi mímọ́ Ọlọ́run ṣàpẹẹrẹ?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 20A

Bí Wọ́n Ṣe Pín Ilẹ̀ Náà

Ìran ilẹ̀ pínpín tí Ìsíkíẹ́lì rí fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì níṣìírí, àmọ́ kì í ṣàwọn nìkan, ó tún fún àwọn èèyàn Ọlọ́run òde òní náà níṣìírí.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 21A

“Ilẹ̀ Tí Ẹ Ó Yà Sọ́tọ̀ Láti Fi Ṣe Ọrẹ”

Apá márùn-ún wo ni ilẹ̀ tí Ọlọ́run yà sọ́tọ̀ náà pín sí? Kí ni wọ́n wà fún?

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 22A

Ìdánwò Ìkẹyìn Tí Aráyé Máa Dojú Kọ

Ìbùkún wo làwọn tó borí ìdánwò ìkẹyìn máa rí?