Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 Ẹ̀KỌ́ 55

Áńgẹ́lì Jèhófà Dáàbò Bo Hesekáyà

Áńgẹ́lì Jèhófà Dáàbò Bo Hesekáyà

Àwọn ọmọ ogun Ásíríà ti ṣẹ́gun ẹ̀yà mẹ́wàá ti ìjọba Ísírẹ́lì. Ní báyìí, Senakéríbù ọba Ásíríà tún fẹ́ gba ẹ̀yà méjì ìjọba Júdà. Ńṣe ló ń ṣẹ́gun àwọn ìlú Júdà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ ìlú Jerusálẹ́mù gangan ló ń wá bó ṣe máa ṣẹ́gun. Ohun tí Senakéríbù kò mọ̀ ni pé Jèhófà ń dáàbò bo ìlú náà.

Hesekáyà ọba san owó rẹpẹtẹ fún Senakéríbù kó má bàa pa Jerusálẹ́mù run. Senakéríbù gba owó náà, síbẹ̀, ó tún rán àwọn ọmọ ogun alágbára láti wá bá Jerusálẹ́mù jagun. Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn Jerusálẹ́mù torí pé àwọn ọmọ ogun Ásíríà ti ń sún mọ́ tòsí. Àmọ́ Hesekáyà sọ fún wọ́n pé: ‘Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Àwọn ọmọ ogun Ásíríà lágbára lóòótọ́, àmọ́ Jèhófà máa jẹ́ ká ṣẹ́gun wọn.’

Senakéríbù rán ìránṣẹ́ rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Rábúṣákè pé kó lọ máa fi àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù ṣe yẹ̀yẹ́. Ńṣe ni Rábúṣákè dúró níwájú ìlú Jerúsálẹ́mù tó sì ń pariwo pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekáyà tàn yín jẹ, Jèhófà kò lè gbà yín là. Kò sí Ọlọ́run tó lè gbà yín lọ́wọ́ wa.’

Hesekáyà wá bẹ Jèhófà pé kí ó kọ́ òun ni ohun tí òun máa ṣe. Jèhófà dáhùn àdúrà rẹ̀, ó ní: ‘Má ṣe bẹ̀rù nítorí ohun tí Rábúṣákè sọ. Senakéríbù kò ní ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù.’ Lẹ́yìn náà, Senakéríbù tún kọ àwọn lẹ́ta burúkú sí Hesekáyà. Ó sọ nínú lẹ́tà náà pé: ‘Má dara rẹ láàmú. Jèhófà kò lè gbà ẹ́ là.’ Hesekáyà wá gbàdúrà pé: ‘Jọ̀wọ́ Jèhófà, gbà wá là kí gbogbo èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ nìkan ni Ọlọ́run tòọ́tọ́.’ Jèhófà sọ fún un pé: ‘Mi ò ní jẹ́ kí Ọba Ásíríà wọ Jerúsálẹ́mù. Màá dáàbò bo ìlú mi.’

Senakéríbù rò pé òun máa lè ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ nígbà tó di alẹ́ pátápátá ti gbogbo èèyàn ti sùn, Jèhófà rán áńgẹ́lì rẹ̀ kan lọ síbi tí àwọn ọmọ ogun Ásíríà wà ní ìta. Áńgẹ́lì yẹn sì  pa 185,000 ọmọ ogun! Senakéríbù pàdánù gbogbo àwọn alágbára rẹ̀, ó sì fi ìtìjú pa dà sílé. Jèhófà dáàbò bo Hesekáyà àti Jerúsálẹ́mù bó ṣe ṣèlérí. Tó bá jẹ́ pé o wà lára àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn, ṣé wàá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

‘Áńgẹ́lì Jèhófà yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, Ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.’​—Sáàmù 34:7