ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÓ O LÈ KỌ́ LÁTINÚ BÍBÉLÌ

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 7

Yorùbá
Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 7
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/1102016137/univ/art/1102016137_univ_sqr_xl.jpg
lfb ojú ìwé 94-95

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 7

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 7

Apá yìí dá lórí ìtàn Ọba Sọ́ọ̀lù àti Ọba Dáfídì. Ìtàn náà sì gba nǹkan bí ọgọ́rin (80) ọdún. Onírẹ̀lẹ̀ ni Sọ́ọ̀lù níbẹ̀rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run, àmọ́ nígbà tó yá, ó yíwà pa dà, kò sì tẹ̀ lé òfin Jèhófà mọ́. Torí náà, Jèhófà kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Jèhófà sì sọ fún Sámúẹ́lì pé kó yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba tó máa jẹ lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Dáfídì, ó sì wá ọ̀nà láti pa á, àmọ́ Dáfídì ò gbẹ̀san. Jónátánì tó jẹ́ ọmọ Sọ́ọ̀lù mọ̀ pé Dáfídì ni Jèhófà fẹ́ kó jọba, torí náà ó dúró ti Dáfídì. Nígbà tó yá, Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára, àmọ́ ó gba ìbáwí Jèhófà. Tó o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kọ́mọ ẹ rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ adúróṣinṣin, ká sì máa ṣègbọràn sí Jèhófà àtàwọn tó ń ṣàbójútó nínú ètò ẹ̀.

NÍ APÁ YÌÍ

Ẹ̀KỌ́ 39

Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì

Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láwọn onídàájọ́, àmọ́ wọ́n béèrè fún ọba. Sámúẹ́lì yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba àkọ́kọ́, àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà kọ̀ ọ́ lọ́ba. Kí nìdí?

Ẹ̀KỌ́ 40

Dafidi ati Golayati

Jèhófà yan Dáfídì láti jẹ́ ọba tó kàn ní Ísírẹ́lì, ìwà Dáfídì fi hàn pé ọba tọ́ sí i.

Ẹ̀KỌ́ 41

Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù

Kí nìdí tí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin yìí fi kórìíra ìkejì, báwo ni ìkejì ṣe hùwà sí èyí tó kórìíra rẹ̀?

Ẹ̀KỌ́ 42

Jónátánì Nígboyà, Ó sì Jẹ́ Adúrótini

Jónátánì tó jẹ́ ọmọ ọba di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Dáfídì.

Ẹ̀KỌ́ 43

Ọba Dáfídì Dẹ́ṣẹ̀

Àṣìṣe kan tó fa ọ̀pọ̀ wàhálà.