ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÓ O LÈ KỌ́ LÁTINÚ BÍBÉLÌ

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 3

Yorùbá
Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 3
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/1102016133/univ/art/1102016133_univ_sqr_xl.jpg
lfb ojú ìwé 22-23

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 3

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 3

Lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi omi pa àwọn èèyàn burúkú run, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn díẹ̀ tó jọ́sìn Jèhófà. Lára wọn ni Ábúráhámù tí Bíbélì pè ní ọ̀rẹ́ Jèhófà. Kí nìdí tí Bíbélì fi pè é ní ọ̀rẹ́ Jèhófà? Tó o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kí ọmọ rẹ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an, ó sì fẹ́ ràn án lọ́wọ́. Bí Ábúráhámù, Lọ́ọ̀tì, Jékọ́bù àtàwọn olóòótọ́ míì, àwa náà lè bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Ó sì dá wa lójú pé Jèhófà máa mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ.

NÍ APÁ YÌÍ

Ẹ̀KỌ́ 7

Ilé Gogoro Bábélì

Àwọn èèyàn fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tó máa ga dé ọ̀run. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi da èdè wọn rú?

Ẹ̀KỌ́ 8

Ábúráhámù àti Sérà Ṣègbọràn sí Ọlọ́run

Kí ló mú kí Ábúráhámù àti Sérà fi ìlú wọn sílẹ̀ láti lọ máa gbé nínú àgọ́ nílẹ̀ Kénáánì?

Ẹ̀KỌ́ 9

Sérà Bímọ Nígbà Tó Darúgbó!

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ? Ṣé ipasẹ̀ Ísákì ni àbí Íṣímáẹ́lì?

Ẹ̀KỌ́ 10

Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì

Ọlọ́run mú kí òjò iná àti imí ọjọ́ rọ̀ sórí ìlú Sódómù àti Gòmórà. Kí ló dé tí Ọlọ́run fi pa àwọn ìlú yẹn run? Kí nìdí tó fi yẹ ká rántí aya Lọ́ọ̀tì?

Ẹ̀KỌ́ 11

Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò

Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Jọ̀ọ́, mú ọmọ kan ṣoṣo tó o ní, kẹ́ ẹ jọ lọ sórí òkè kan ní Moráyà kó o sì fi ọmọ náà rúbọ.’ Báwo ni Ábúráhámù ṣe máa kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ yìí?

Ẹ̀KỌ́ 12

Jékọ́bù Rí Ogún Gbà

Ísákì àti Rèbékà bí ìbejì, wọ́n sì sọ wọ́n ní Ísọ̀ àti Jékọ́bù. Torí pé Ísọ̀ ní àkọ́bí, òun ló yẹ kó gba ogún ìdílé wọn. Kí nìdí tó fi sọ ogún yẹn nù torí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré?

Ẹ̀KỌ́ 13

Jékọ́bù àti Ísọ̀ Parí Ìjà Wọn

Kí ni Jékọ́bù ṣe tó fi rí ìbùkún gbà lọ́dọ̀ áńgẹ́lì kan? Báwo ni òun àti Ísọ̀ ṣe parí ìjà wọn?