ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÓ O LÈ KỌ́ LÁTINÚ BÍBÉLÌ

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 14

Yorùbá
Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 14
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/1102016144/univ/art/1102016144_univ_sqr_xl.jpg
lfb ojú ìwé 218-219

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 14

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 14

Àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé àwọn ibi tó jìnnà jù láyé. Jésù ló pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n wàásù, ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu tó jẹ́ kí wọ́n lè máa fi oríṣiríṣi èdè kọ́ àwọn èèyàn. Jèhófà tún jẹ́ kí wọ́n nígboyà, ó sì fún wọn lágbára kí wọ́n lè borí àtakò tó le.

Jésù fi ìran kan han àpọ́sítélì Jòhánù, ó sì jẹ́ kó rí ògo Jèhófà. Nínú ìran míì, Jòhánù rí bí Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ẹ̀ ṣe ṣẹ́gun Sátánì, tí wọn ò sì jé kó máa ṣiṣẹ́ ibi mọ́ títí láé. Jòhánù rí i tí Jésù di Ọba, ó sì rí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó ń jọba pẹ̀lú ẹ̀. Jòhánù tún rí bí gbogbo ayé ṣe di Párádísè, tí gbogbo èèyàn wà ní àlàáfíà, tí wọ́n sì ń jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan.

NÍ APÁ YÌÍ

Ẹ̀KỌ́ 94

Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù Gba Ẹ̀mí Mímọ́

Nǹkan ìyanu wo ni ẹ̀mí mímọ́ mú kí wọ́n ṣe?

Ẹ̀KỌ́ 95

Kò Sóhun Tó Lè Dá Wọn Dúró

Àwọn aṣáájú ìsìn tó pa Jésù ń wá bí wọ́n ṣe máa dá iṣẹ́ ìwàásù àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù dúró. Àmọ́ wọn ò rí i ṣe.

Ẹ̀KỌ́ 96

Jésù Yan Sọ́ọ̀lù

Ọ̀tá àwọn Kristẹni ni Sọ́ọ̀lù, àmọ́ nǹkan máa tó yí pa dà.

Ẹ̀KỌ́ 97

Kọ̀nílíù Gba Ẹ̀mí Mímọ́

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi rán Pétérù lọ sílé ọkùnrin kan tí kì í ṣe Júù?

Ẹ̀KỌ́ 98

Ẹ̀sìn Kristẹni Dé Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò mú ìhìn rere lọ sáwọn ìlú tó jìnnà.

Ẹ̀KỌ́ 99

Ẹ̀ṣọ́ Ọgbà Ẹ̀wọ̀n kan Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ka ìtàn kan tó dá lé ọmọbìnrin kan tó lẹ́mìí èṣù, ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ àti ẹnì kan tó fẹ́ fi idà para ẹ̀.

Ẹ̀KỌ́ 100

Pọ́ọ̀lù àti Tímótì

Àwọn méjèèjì jọ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ àti arákùnrin fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Ẹ̀KỌ́ 101

Wọ́n Gbé Pọ́ọ̀lù Lọ sí Róòmù

Ewu pọ̀ lójú ọ̀nà, ṣùgbọ́n kò sóhun tó lè dá àpọ́sítélì yìí dúró.

Ẹ̀KỌ́ 102

Ìran Tí Jòhánù Rí

Jésù fi àwọn ìran nípa ọjọ́ iwájú hàn án.

Ẹ̀KỌ́ 103

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”

Jòhánù rí ìran nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa tún ayé yìí ṣe.