Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 Ẹ̀KỌ́ 77

Obìnrin kan Wá Pọn Omi Nínú Kànga

Obìnrin kan Wá Pọn Omi Nínú Kànga

Lẹ́yìn tí àjọyọ̀ Ìrékọjá parí, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń rin ìrìn-àjò pa dà sí ìlú Gálílì, àmọ́ ìlú Samáríà ni wọ́n gbà kọjá. Nígbà tí wọ́n dé ìtòsí ìlú Síkárì, Jésù sinmi ní ìdí kànga kan tí wọ́n ń pè ní kànga Jékọ́bù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì lọ ra oúnjẹ wá.

Kò pẹ́ sí ìgbà yẹn, obìnrin kan wá pọn omi. Jésù sọ fún un pé: ‘Fún mi lómi mu.’ Obìnrin náà sọ pé: ‘Kí ló dé tí ò ń bá mi sọ̀rọ̀? Ọmọ ìlú Samáríà ni mí. Àwọn Júù kì í sì í bá àwa ọmọ ìlú Samáríà sọ̀rọ̀.’ Jésù wá sọ fún un pé: ‘Ká ní o mọ ẹni tí mo jẹ́ ni, ìwọ ló máa béèrè omi lọ́wọ́ mi, màá sì fún ẹ ní omi ìyè.’ Obìnrin náà bi Jésù pé: ‘Ọ̀rọ̀ ẹ kò yé mi o, torí kò sí korobá kankan lọ́wọ́ rẹ.’ Jésù sọ fún un pé: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá mu omi tí mo sọ yìí, òùngbẹ kí yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé.’ Obìnrin náà wá sọ fún un pé: “Ọ̀gá, fún mi ní omi yìí.”

Jésù sọ fún un pé: ‘Lọ pe ọkọ rẹ wá.’ Obìnrin náà dáhùn pé: ‘Èmi kò ní ọkọ.’ Jésù sọ fún un pé: ‘Òótọ́ lo sọ. Ìgbà márùn-ún ni o ti ṣe ìgbéyàwó, ẹni tí o sì ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ.’ Obìnrin náà wá sọ fún un pé: ‘Mo ti rí i pé wòlíì ni ẹ́. Àwọn èèyàn wa gbà pé a lè jọ́sìn lórí òkè ńlá yìí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin Júù sọ pé Jerúsálẹ́mù nìkan ló yẹ ká ti máa jọ́sìn. Mo mọ̀ pé tí Mèsáyà bá dé, ó máa kọ́ wa bó ṣe yẹ ká máa jọ́sìn.’ Jésù wá sọ ohun kan tí kò tíì sọ fún ẹnikẹ́ni rí, ó ní: ‘Èmi ni Mèsáyà náà.’

Bí obìnrin yẹn ṣe sáré lọ sí ìlú rẹ̀ nìyẹn, ó sì lọ sọ fún àwọn ará  Samáríà pé: ‘Ó dà bíi pé mo ti rí Mèsáyà, torí pé gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi ló mọ̀. Ẹ wá lọ wò ó!’ Bí gbogbo wọn ṣe tẹ̀ lé e pa dà sí ìdí kànga nìyẹn, wọ́n sì tẹ́tí sí ohun tí Jésù kọ́ wọn.

Àwọn ará Samáríà yẹn ní kí Jésù wá sí ìlú àwọn. Torí náà, Jésù lo ọjọ́ méjì pẹ̀lú wọn, ó ń kọ́ wọn, àwọn èèyàn náà sì gba ohun tó sọ gbọ́. Wọ́n wá ń sọ fún obìnrin náà pé: ‘Lẹ́yìn tí a ti gbọ́ àwọn ohun tí ọkùnrin yìí ń sọ, a ti wá mọ̀ pé, dájúdájú òun ni ẹni tó máa gba aráyé là.’

“‘Come!’ and let anyone thirsting come; let anyone who wishes take life’s water free.”​​—Revelation 22:17