ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÓ O LÈ KỌ́ LÁTINÚ BÍBÉLÌ

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 12

Yorùbá
Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 12
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/1102016142/univ/art/1102016142_univ_sqr_xl.jpg
lfb ojú ìwé 174-175

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 12

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 12

Jésù kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó tún kọ́ wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí ìfẹ́ Ọlọ́run sì ṣẹ láyé. Tó o bá jẹ́ òbí, ṣàlàyé ohun tí àdúrà yẹn túmọ̀ sí fún ọmọ rẹ. Jésù ò jẹ́ kí Sátánì sọ òun di aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run. Nígbà tó yá, Jésù yan àwọn àpọ́sítélì ẹ̀, àwọn ni wọ́n sì kọ́kọ́ di ọmọ Ìjọba Ọlọ́run. Kíyè sí bí Jésù ṣe nítara fún ìjọsìn tòótọ́. Torí pé Jésù fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó fún àwọn tébi ń pa lóúnjẹ, ó tiẹ̀ tún jí òkú dìde. Àwọn ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún gbogbo èèyàn.

NÍ APÁ YÌÍ

Ẹ̀KỌ́ 74

Jésù Di Mèsáyà

Kí ni Jòhánù ní lọ́kàn nígbà tó pe Jésù ní Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run?

Ẹ̀KỌ́ 75

Èṣù Dán Jésù Wò

Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èṣù dán Jésù wò. Kí làwọn ìdẹwò mẹ́ta náà? Báwo ni Jésù ṣe dáhùn pa dà?

Ẹ̀KỌ́ 76

Jésù Lé Àwọn Tó Ń Tajà Nínú Tẹ́ńpìlì

Kí nìdí tí Jésù fi lé àwọn ẹran tó wà nínú tẹ́ńpìlì tó sì da tábìlì àwọn tó ń ṣẹ́ owó nù?

Ẹ̀KỌ́ 77

Obìnrin kan Wá Pọn Omi Nínú Kànga

Ẹnu ya obìnrin ará Samáríà kan pé Jésù bá a sọ̀rọ̀. Kí nìdí? Kí ni Jésù sọ fún un tó jẹ́ pé kò sọ fún ẹlòmí ì rí?

Ẹ̀KỌ́ 78

Jésù Wàásù Nípa Ìjọba Ọlọ́run

Jésù sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wá di “apẹja èèyàn.” Nígbà tó yá, ó kọ́ àádọ́rin (70) lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà bí wọ́n á ṣe máa wàásù ìhìn rere.

Ẹ̀KỌ́ 79

Jésù Ṣe Ọ̀pọ̀ Iṣẹ́ Ìyanu

Gbogbo ibi tó bá lọ làwọn aláìsàn máa ń wá bá a kó lè wò wọ́n sàn. Ó tiẹ̀ jí ọmọbìnrin kan tó ti kú dìde.

Ẹ̀KỌ́ 80

Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá

Kí nìdí tó fi yàn wọ́n? Ṣé o rántí orúkọ wọn?

Ẹ̀KỌ́ 81

Ìwàásù Orí Òkè

Jésù kọ́ àwọn èèyàn láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì.

Ẹ̀KỌ́ 82

Jésù Kọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Ẹ̀ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Gbàdúrà

Àwọn nǹkan wo ni Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa béèrè?

Ẹ̀KỌ́ 83

Jésù Fún Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lóunjẹ

Kí ni iṣẹ́ ìyanu yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa Jésù àti Jèhófà?

Ẹ̀KỌ́ 84

Jésù Rìn Lórí Omi

Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára àwọn àpọ́sítélì lẹ́yìn tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu yìí?

Ẹ̀KỌ́ 85

Jésù Wo Ẹnì Kan Sàn Lọ́jọ́ Sábáàtì

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo èèyàn kọ́ ni inú wọn ń dùn sóhun tí Jésù ṣe?

Ẹ̀KỌ́ 86

Jésù Jí Lásárù Dìde

Nígbà tí Jésù rí i tí Màríà ń sunkún, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Àmọ́ ẹkún wọn dayọ̀ lẹ́yìn-ò-rẹyìn.