ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÓ O LÈ KỌ́ LÁTINÚ BÍBÉLÌ

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 1

Yorùbá
Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 1
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/1102016131/univ/art/1102016131_univ_sqr_xl.jpg
lfb ojú ìwé 6-7

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 1

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 1

Ohun tó bẹ̀rẹ̀ Bíbélì ni ìtàn bí Jèhófà ṣe dá gbogbo nǹkan, ó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó rẹwà tí Jèhófà dá lọ́run àti láyé. Tó o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kí ọmọ ẹ rí oríṣiríṣi nǹkan tí Ọlọ́run dá. Jẹ́ kó rí i pé Ọlọ́run fún wa ní ọgbọ́n tó ju ti àwọn ẹranko lọ. Bí àpẹẹrẹ, àwa lè sọ̀rọ̀, a lè ronú, a lè fàwọn nǹkan tó wà láyé dá oríṣiríṣi àrà, a lè kọrin, a tún lè gbàdúrà. Bákan náà, jẹ́ kó mọrírì agbára àti ọgbọ́n tí Jèhófà ní, kó o sì jẹ́ kó rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ gbogbo nǹkan tó dá títí kan gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

NÍ APÁ YÌÍ

Ẹ̀KỌ́ 1

Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé. Àmọ́ ṣé o mọ áńgẹ́lì tí Jèhófà kọ́kọ́ dá kó tó dá gbogbo nǹkan míì?

Ẹ̀KỌ́ 2

Ọlọ́run Dá Ọkùnrin àti Obìnrin Àkọ́kọ́

Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó sì fi wọ́n sínú ọgbà Édẹ́nì. Ó fẹ́ kí wọ́n bímọ, kí wọ́n sì sọ gbogbo ayé di Párádísè.