Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Ìwé yìí máa ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ látìgbà ìṣẹ̀dá tí Bíbélì sọ títí di ìgbà tí wọ́n bí Jésù àtìgbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, wàá sì tún kọ́ nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ títí dìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa dé.
Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
Báwo la ṣe lè lo ìwé yìí?
Ẹ̀KỌ́ 1
Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé. Àmọ́ ṣé o mọ áńgẹ́lì tí Jèhófà kọ́kọ́ dá kó tó dá gbogbo nǹkan míì?
Ẹ̀KỌ́ 2
Ọlọ́run Dá Ọkùnrin àti Obìnrin Àkọ́kọ́
Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó sì fi wọ́n sínú ọgbà Édẹ́nì. Ó fẹ́ kí wọ́n bímọ, kí wọ́n sì sọ gbogbo ayé di Párádísè.
Ẹ̀KỌ́ 3
Ádámù àti Éfà Ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run
Kí ló mú kí igi kan dá yàtọ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì? Kí nìdí tí Éfà fi jẹ èso igi náà?
Ẹ̀KỌ́ 4
Kéènì Bínú Pa Àbúrò Rẹ̀
Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì àmọ́ kò gba ti Kéènì. Nígbà tí Kéènì rí ohun tó ṣẹlẹ̀, inú bí i, ó sì hùwà búburú kan.
Ẹ̀KỌ́ 5
Nóà Kan Áàkì
Nígbà táwọn áńgẹ́lì burúkú kan fẹ́ àwọn obìnrin tó wà láyé, wọ́n bí àwọn ọmọ tó lágbára, tó sì máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń hùwà burúkú, àmọ́ Nóà yàtọ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó sì máa ń ṣègbọràn sí i.
Ẹ̀KỌ́ 6
Èèyàn Mẹ́jọ La Ìparun Já
Òjò rọ̀ fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. Ó ju ọdún kan lọ tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ fi wà nínú áàkì náà. Nígbà tó yá, wọ́n jáde kúrò nínú rẹ̀.
Ẹ̀KỌ́ 7
Ilé Gogoro Bábélì
Àwọn èèyàn fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tó máa ga dé ọ̀run. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi da èdè wọn rú?
Ẹ̀KỌ́ 8
Ábúráhámù àti Sérà Ṣègbọràn sí Ọlọ́run
Kí ló mú kí Ábúráhámù àti Sérà fi ìlú wọn sílẹ̀ láti lọ máa gbé nínú àgọ́ nílẹ̀ Kénáánì?
Ẹ̀KỌ́ 9
Sérà Bímọ Nígbà Tó Darúgbó!
Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ? Ṣé ipasẹ̀ Ísákì ni àbí Íṣímáẹ́lì?
Ẹ̀KỌ́ 10
Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì
Ọlọ́run mú kí òjò iná àti imí ọjọ́ rọ̀ sórí ìlú Sódómù àti Gòmórà. Kí ló dé tí Ọlọ́run fi pa àwọn ìlú yẹn run? Kí nìdí tó fi yẹ ká rántí aya Lọ́ọ̀tì?
Ẹ̀KỌ́ 11
Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò
Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Jọ̀ọ́, mú ọmọ kan ṣoṣo tó o ní, kẹ́ ẹ jọ lọ sórí òkè kan ní Moráyà kó o sì fi ọmọ náà rúbọ.’ Báwo ni Ábúráhámù ṣe máa kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ yìí?
Ẹ̀KỌ́ 12
Jékọ́bù Rí Ogún Gbà
Ísákì àti Rèbékà bí ìbejì, wọ́n sì sọ wọ́n ní Ísọ̀ àti Jékọ́bù. Torí pé Ísọ̀ ní àkọ́bí, òun ló yẹ kó gba ogún ìdílé wọn. Kí nìdí tó fi sọ ogún yẹn nù torí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré?
Ẹ̀KỌ́ 13
Jékọ́bù àti Ísọ̀ Parí Ìjà Wọn
Kí ni Jékọ́bù ṣe tó fi rí ìbùkún gbà lọ́dọ̀ áńgẹ́lì kan? Báwo ni òun àti Ísọ̀ ṣe parí ìjà wọn?
Ẹ̀KỌ́ 22
Iṣẹ́ Ìyanu ní Òkun Pupa
Fáráò la àwọn ìyọnu mẹ́wàá já, àmọ́ ṣé ó ye iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ṣe yìí?
Ẹ̀KỌ́ 23
Wọ́n Ṣèlérí fún Jèhófà
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣèlérí kan fún Ọlọ́run nígbà tí wọ́n wà ní Òkè Sínáì.
Ẹ̀KỌ́ 24
Wọn Ò Mú Ìlérí Wọn Ṣẹ
Nígbà tí Mósè lọ gba òfin mẹ́wàá náà lórí òkè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hùwà burúkú.
Ẹ̀KỌ́ 26
Àwọn Amí Méjìlá
Jóṣúà àti Kélẹ́bù yàtọ̀ sáwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó kù tí wọ́n rán lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì.
Ẹ̀KỌ́ 27
Wọ́n Ta Ko Jèhófà
Kórà, Dátánì, Ábírámù àtàwọn ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́ta (250) ọkùnrin mí ì kò mọ òtítọ́ pàtàkì kan nípa Jèhófà.
Ẹ̀KỌ́ 30
Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́
Ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀. Àmọ́ ilé Ráhábù dúró bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ògiri yẹn ni wọ́n kọ́ ọ mọ́.
Ẹ̀KỌ́ 31
Jóṣúà àti Àwọn Ará Gíbíónì
Jóṣúà gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí “oòrùn, dúró sójú kan.” Ṣé Ọlọ́run gbọ́ àdúrà ẹ̀?
Ẹ̀KỌ́ 32
Aṣáájú Tuntun àti Obìnrin Onígboyà Méjì
Lẹ́yìn tí Jóṣúà kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn òrìṣà. Àwọn ọ̀tá wá ń ni wọ́n lára, àmọ́ Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́ nípasẹ̀ Bárákì, wòlí ì Dèbórà àti Jáẹ́lì tó lo ìṣó tó fi ń kan àgọ́.
Ẹ̀KỌ́ 33
Rúùtù àti Náómì
Àwọn obìnrin méjì tí ọkọ wọn ti kú pa dà sí Ísírélì. Èyí tó ń jẹ́ Rúùtù lọ ṣiṣẹ́ lóko, Bóásì sì kíyè sí i.
Ẹ̀KỌ́ 34
Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì
Nígbà táwọn ará Mídíánì fòòró ẹ̀mí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Báwo làwọn ọmọ ogun Gídíónì ṣe ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún márùnléláàádóje (135,000) ọ̀tá?
Ẹ̀KỌ́ 35
Hánà Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Fún Òun ní Ọmọkùnrin
Ẹlikénà mú Hánà, Pẹ̀nínà àtàwọn ọmọ ẹ̀ lọ jọ́sìn ní àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò. Níbẹ̀, Hánà gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun ní ọmọkùnrin. Lẹ́yìn ọdún kan, ó bí Sámúẹ́lì.
Ẹ̀KỌ́ 36
Ìlérí Tí Jẹ́fútà Ṣe
Ìlérí wo ni Jẹ́fútà ṣe, kí sì nìdí? Kí ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà ṣe nígbà tó gbọ́ nípa ìlérí bàbá ẹ̀?
Ẹ̀KỌ́ 37
Jèhófà Bá Sámúẹ́lì Sọ̀rọ̀
Élì Àlùfáà Àgbà ní ọmọkùnrin méjì tó ń sìn ní àgọ́ ìjọsìn, àmọ́ wọn ò pa òfin Ọlọ́run mọ́. Sámúẹ́lì yàtọ̀ ní tiẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ kan, Jèhófà bá Sámúẹ́lì sọ̀rọ̀.
Ẹ̀KỌ́ 38
Jèhófà Sọ Sámúsìn Di Alágbára
Ọlọ́run mú kí Sámúsìn lágbára láti bá àwọn Filísínì jà. Àmọ́ nígbà tí Sámúsìn ṣèpinnu tí ò dáa, àwọn Filísínì sì mú un.
Ẹ̀KỌ́ 39
Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì
Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láwọn onídàájọ́, àmọ́ wọ́n béèrè fún ọba. Sámúẹ́lì yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba àkọ́kọ́, àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà kọ̀ ọ́ lọ́ba. Kí nìdí?
Ẹ̀KỌ́ 40
Dafidi ati Golayati
Jèhófà yan Dáfídì láti jẹ́ ọba tó kàn ní Ísírẹ́lì, ìwà Dáfídì fi hàn pé ọba tọ́ sí i.
Ẹ̀KỌ́ 41
Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù
Kí nìdí tí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin yìí fi kórìíra ìkejì, báwo ni ìkejì ṣe hùwà sí èyí tó kórìíra rẹ̀?
Ẹ̀KỌ́ 44
Wọ́n Kọ́ Tẹ́ńpìlì fún Jèhófà
Ọlọ́run gbọ́ àdúrà Sólómọ́nì, ó sì fún un láwọn nǹkan tó dáa.
Ẹ̀KỌ́ 49
Ọlọ́run Fìyà Jẹ Ayaba Kan Tó Burú Gan-an
Jésíbẹ́lì gbìmọ̀ láti pa ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Nábótì kó lè gba ọgbà àjàrà ẹ̀! Jèhófà Ọlọ́run rí ìwà ìkà àti ìwà ìrẹ́jẹ yẹn.
Ẹ̀KỌ́ 50
Jèhófà Gbèjà Jèhóṣáfátì
Ọba Jèhóṣáfátì gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà táwọn ọ̀tá gbógun ti ilẹ̀ Júdà.
Ẹ̀KỌ́ 51
Jagunjagun àti Ọmọbìnrin Kékeré Kan
Ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan sọ fún ìyàwó ọ̀gá ẹ̀ nípa agbára Jèhófà, wọ́n sì rí agbára Jèhófà lóòótọ́.
Ẹ̀KỌ́ 52
Àwọn Ọmọ Ogun Jèhófà
Bí ìránṣẹ́ Èlíṣà ṣe wá mọ̀ pé ‘àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú wọn.’
Ẹ̀KỌ́ 54
Jèhófà Ní Sùúrù fún Jónà
Báwo ló ṣe di pé ẹja ńlá gbé ìránṣẹ́ Ọlọ́run mì? Báwo ló ṣe jáde? Ẹ̀kó wo ni Jèhófà kọ́ ọ?
Ẹ̀KỌ́ 55
Áńgẹ́lì Jèhófà Dáàbò Bo Hẹsikáyà
Àwọn ọ̀tá Júdà sọ pé Jèhófà ò ní dáàbò bo àwon èèyàn ẹ̀, àmọ́ irọ́ ni wọ́n pa!
Ẹ̀KỌ́ 56
Jòsáyà Fẹ́ràn Òfin Ọlọ́run
Jòsáyà di ọba nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ, ó sì ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa jọ́sìn Jèhófà.
Ẹ̀KỌ́ 58
Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Run
Àwọn èèyàn Júdà ò jáwọ́ nínú ẹ̀sìn èké, torí náà Jèhófà pa wọ́n tì.
Ẹ̀KỌ́ 59
Ọ̀dọ́kùnrin Mẹ́rin Ṣègbọràn sí Jèhófà
Àwọn ọ̀dọ́ kan láti Júdà pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kódà nígbà tí wọ́n wà láàfin ọba Bábílónì.
Ẹ̀KỌ́ 61
Wọn Ò Tẹrí Ba
Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kò tẹrí ba fún ère wúrà tí ọba Bábílónì gbé kalẹ̀
Ẹ̀KỌ́ 65
Ẹ́sítà Gba Àwọn Èèyàn Ẹ̀ Nínú Ewu
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àjèjì ni, ó sì jẹ́ ọmọ òrukàn, ó di ayaba.
Ẹ̀KỌ́ 66
Ẹ́sírà Kọ́ Àwọn Èèyàn ní Òfin Ọlọ́run
Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fetí sí Ẹ́sírà, wọ́n ṣèlérí pàtàkì kan fún Ọlọ́run.
Ẹ̀KỌ́ 68
Èlísábẹ́tì Bí Ọmọ Kan
Kí nìdí tí áńgẹ́lì náà fi sọ fún ọkọ Èlísábẹ́tì pé kò ní lè sọ̀rọ̀ títí wọ́n á fi bí ọmọ náà?
Ẹ̀KỌ́ 70
Àwọn Áńgẹ́lì Kéde Pé Wọ́n Ti Bí Jésù
Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó gbọ́ ìkéde náà gbéra lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ẹ̀KỌ́ 73
Jòhánù Múra Àwọn Èèyàn Sílẹ̀
Jòhánù sì dàgbà di wòlí ì. Ó kọ́ àwọn èèyàn pé Mèsáyà ń bọ̀. Kí làwọn èèyàn ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀?
Ẹ̀KỌ́ 75
Èṣù Dán Jésù Wò
Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èṣù dán Jésù wò. Kí làwọn ìdẹwò mẹ́ta náà? Báwo ni Jésù ṣe dáhùn pa dà?
Ẹ̀KỌ́ 76
Jésù Lé Àwọn Tó Ń Tajà Nínú Tẹ́ńpìlì
Kí nìdí tí Jésù fi lé àwọn ẹran tó wà nínú tẹ́ńpìlì tó sì da tábìlì àwọn tó ń ṣẹ́ owó nù?
Ẹ̀KỌ́ 77
Obìnrin kan Wá Pọn Omi Nínú Kànga
Ẹnu ya obìnrin ará Samáríà kan pé Jésù bá a sọ̀rọ̀. Kí nìdí? Kí ni Jésù sọ fún un tó jẹ́ pé kò sọ fún ẹlòmí ì rí?
Ẹ̀KỌ́ 78
Jésù Wàásù Nípa Ìjọba Ọlọ́run
Jésù sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wá di “apẹja èèyàn.” Nígbà tó yá, ó kọ́ àádọ́rin (70) lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà bí wọ́n á ṣe máa wàásù ìhìn rere.
Ẹ̀KỌ́ 79
Jésù Ṣe Ọ̀pọ̀ Iṣẹ́ Ìyanu
Gbogbo ibi tó bá lọ làwọn aláìsàn máa ń wá bá a kó lè wò wọ́n sàn. Ó tiẹ̀ jí ọmọbìnrin kan tó ti kú dìde.
Ẹ̀KỌ́ 82
Jésù Kọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Ẹ̀ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Gbàdúrà
Àwọn nǹkan wo ni Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa béèrè?
Ẹ̀KỌ́ 84
Jésù Rìn Lórí Omi
Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára àwọn àpọ́sítélì lẹ́yìn tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu yìí?
Ẹ̀KỌ́ 85
Jésù Wo Ẹnì Kan Sàn Lọ́jọ́ Sábáàtì
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo èèyàn kọ́ ni inú wọn ń dùn sóhun tí Jésù ṣe?
Ẹ̀KỌ́ 86
Jésù Jí Lásárù Dìde
Nígbà tí Jésù rí i tí Màríà ń sunkún, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Àmọ́ ẹkún wọn dayọ̀ lẹ́yìn-ò-rẹyìn.
Ẹ̀KỌ́ 87
Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
Jésù fún àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ láwọn ìtọ́ni pàtàkì kan nígbà tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ olẹ́ Olúwa.
Ẹ̀KỌ́ 89
Pétérù Sọ Pé Òun Ò Mọ Jésù Rí
Kí ló ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà ilé Káyáfà? Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jésù nínú ilé náà?
Ẹ̀KỌ́ 95
Kò Sóhun Tó Lè Dá Wọn Dúró
Àwọn aṣáájú ìsìn tó pa Jésù ń wá bí wọ́n ṣe máa dá iṣẹ́ ìwàásù àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù dúró. Àmọ́ wọn ò rí i ṣe.
Ẹ̀KỌ́ 97
Kọ̀nílíù Gba Ẹ̀mí Mímọ́
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi rán Pétérù lọ sílé ọkùnrin kan tí kì í ṣe Júù?
Ẹ̀KỌ́ 98
Ẹ̀sìn Kristẹni Dé Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò mú ìhìn rere lọ sáwọn ìlú tó jìnnà.
Ẹ̀KỌ́ 99
Ẹ̀ṣọ́ Ọgbà Ẹ̀wọ̀n kan Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ka ìtàn kan tó dá lé ọmọbìnrin kan tó lẹ́mìí èṣù, ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ àti ẹnì kan tó fẹ́ fi idà para ẹ̀.
Ẹ̀KỌ́ 101
Wọ́n Gbé Pọ́ọ̀lù Lọ sí Róòmù
Ewu pọ̀ lójú ọ̀nà, ṣùgbọ́n kò sóhun tó lè dá àpọ́sítélì yìí dúró.

