Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?

A dìídì ṣe ìwé yìí kó o lè fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa oríṣiríṣi nǹkan. Lára wọn ni ìdí tí ìyà fi ń jẹ àwa èèyàn, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú, bá a ṣe lè ní ilé aláyọ̀, àtàwọn kókó pàtàkì míì.

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Wa?

O lè máa ronú pé kí nìdí tí ìṣòro fi pọ̀ láyé lónìí? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa tó mú ìṣòro aráyé kúrò, irú bí ìyà, àìsàn àti ikú.

ORÍ 1

Ta Ni Ọlọ́run?

Ṣé o rò pé Ọlọ́run bìkítà nípa rẹ? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti bó o ṣe lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀.

ORÍ 2

Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti Wá

Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro rẹ? Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbà pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì máa ṣẹ?

ORÍ 3

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Aráyé?

Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun nígbà tí ayé bá di Párádísè?

ORÍ 4

Ta Ni Jésù Kristi?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdí tó fi dá wa lójú pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, ibi tó ti wá, àti ìdí tí Bíbélì fi pè é ní Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà.

ORÍ 5

Ìràpadà Ni Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fún Wa

Kí ni ìràpadà? Báwo ló ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní?

ORÍ 6

Ibo Là Ń Lọ Tá A Bá Kú?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ìdí tí àwa èèyàn fi ń kú àti ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn to ti ku.

ORÍ 7

Àjíǹde Máa Wà!

Ṣé èèyàn rẹ kan ti kú? Ṣé o tún lè pa dà rí wọn? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa àjíǹde.

ORÍ 8

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ àdúrà Olúwa. Kí ni ìtúmọ̀ gbólóhùn náà: “Kí Ìjọba rẹ dé”?

ORÍ 9

Ṣé Òpin Ayé Ti Sún Mọ́lé?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn ní àyíká wa ṣe ń fi hàn pé àkókò tó ṣáájú òpin ayé là ń gbé báyìí, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀.

ORÍ 10

Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì àtàwọn ẹ̀mí èṣù. Ṣé wọ́n wà lóòótọ́? Ṣé wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n ṣèkà fún wa?

ORÍ 11

Kí Nìdí Tí Ìyà Fi Pọ̀ Láyé?

Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé Ọlọ́run ló lẹ̀bi gbogbo ìyà tó wà láyé. Kí lèrò rẹ? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ohun tó ń fa ìyà.

ORÍ 12

Kí Lo Lè Ṣe Láti Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

Èèyàn lè gbé ìgbé ayé tó ń mú inú Ọlọ́run dùn. O tiẹ̀ lè di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

ORÍ 13

Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀mí

Ojú wo ní Ọlọ́run fi ń wo ìṣẹ́yún, ìfàjẹ̀sínilára, àti ẹ̀mí àwọn ẹranko?

ORÍ 14

Bí Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Láyọ̀

Jésù fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, èyí sì jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fún àwọn ọkọ, àwọn ìyawo, àwọn obi, àtàwọn ọmọ láti tẹ̀ lé. Ẹ̀kọ́ wo ni àpẹẹrẹ Jésù kọ́ wa?

ORÍ 15

Ọ̀nà Tó Tọ́ Láti Jọ́sìn Ọlọ́run

Ẹ jẹ́ ká wo ohun mẹ́fà tá a lè fi mọ àwọn to ń ṣe ìsìn tòótọ́.

ORÍ 16

Pinnu Láti Jọ́sìn Ọlọ́run

Àwọn nǹkan wo lo lè dojú kọ nígbà tó o bá ń sọ ohun tó o gbà gbọ́ fún àwọn èèyàn? Báwo lo ṣe lè ṣe é láì múnú bí wọn?

ORÍ 17

Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́

Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń fetí sílẹ̀ tó o bá ń gbàdúrà? Kó o lè rí ìdáhùn ìbéèrè yẹn, o ní láti lóye ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa àdúrà.

ORÍ 18

Ṣé Ó Yẹ Kí N Ya Ìgbésí Ayé Mi Sí Mímọ́ fún Ọlọ́run, Kí N sì Ṣe Ìrìbọmi?

Àwọn nǹkan wo ni ẹni kan ní láti ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi láti di Kristẹni? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó túmọ̀ sí àti bó ṣe yẹ kéèyàn ṣe é.

ORÍ 19

Dúró Sọ́dọ̀ Jèhófà

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí a sì mọyì rẹ̀ torí gbogbo ohun tó ti ṣe fún wa?

Àlàyé Ìparí Ìwé

Àwọn ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn tá a lò nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?