ÀFIKÚN
Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Fi Í Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn
Ọ̀KẸ́ àìmọye èèyàn ló fẹ́ràn àgbélébùú gan-an ti wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún un. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica pe àgbélébùú ní “àmì pàtàkì nínú ìsìn Kristẹni.” Àmọ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í lo àgbélébùú nínú ìjọsìn. Kí nìdí?
Ìdí kan pàtàkì ni pé kì í ṣe orí àgbélébùú ni Jésù Kristi kú sí. Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “àgbélébùú” ni stau·rosʹ. Àmọ́ ìtumọ̀ rẹ gan-an ni “òpó igi tó dúró ṣánṣán.” Bíbélì The Companion
Bible sọ pé: “[Stau·rosʹ] kò túmọ̀ sí igi méjì tí wọ́n gbé lébùú ara wọn rárá. . . . Kò tiẹ̀ sí ohun kankan nínú èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ [Májẹ̀mú Tuntun] tó túmọ̀ sí igi méjì.”Nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi mélòó kan, àwọn tó kọ Bíbélì lo ọ̀rọ̀ mìíràn fún ohun tí wọ́n kan Jésù mọ́. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò náà ni ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà, xyʹlon. (Ìṣe 5:30; 10:39; 13:29; Gálátíà 3:13; 1 Pétérù 2:24) Ohun tí ọ̀rọ̀ yìí wulẹ̀ túmọ̀ sí ni “igi” tàbí “òpó.”
Ìwé kan ní èdè Jámánì tí Hermann Fulda kọ ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi máa ń lo òpó tí wọ́n bá fẹ́ fìyà ikú jẹ ọ̀daràn, ó ní: “Kì í ṣe gbogbo ibi tí wọ́n yàn láti máa pa ọ̀daràn ni igi wà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń ri òpó mọ́lẹ̀, tí wọ́n á sì fìyà ikú jẹ ọ̀daràn lórí rẹ̀. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é ni pé wọ́n á pa ọwọ́ ọ̀daràn náà pọ̀ sókè orí rẹ̀, àti lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n á pa ẹsẹ̀ rẹ̀ pọ̀, wọ́n á wá fi ìṣó kàn án mọ́ òpó náà tàbí kí wọ́n fokùn dì í mọ ọn.”—Das Kreuz und die Kreuzigung.
Àmọ́, inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀rí tó dájú jù lọ wà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kristi nípa rírà, tú wa sílẹ̀ kúrò lábẹ́ ègún Òfin nípa dídi ègún dípò wa, nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹni ègún ni olúkúlùkù ènìyàn tí a gbé kọ́ sórí òpó igi.’” (Gálátíà 3:13) Diutarónómì 21:22, 23 ni Pọ́ọ̀lù ti fa ọ̀rọ̀ yìí yọ, òpó igi sì ni ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu kàn, kì í ṣe àgbélébùú. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé “ẹni ègún” ni wọ́n ka ẹni tí wọ́n bá pa lọ́nà yìí sí, kò ní bójú mu káwọn Kristẹni máa fi àwòrán Kristi tí wọ́n kàn mọ́gi kọ́ sára ilé wọn.
Kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwọn tí wọ́n sọ pé Kristẹni làwọn lo àgbélébùú nínú ìjọsìn títí fi di ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún lẹ́yìn ikú Kristi. Àmọ́ ní ọ̀rúndún kẹrin, Olú Ọba Kọnsitatáìnì tó jẹ́ Kèfèrí yí padà sí ìsìn Kristẹni apẹ̀yìndà ó sì gbé àgbélébùú lárugẹ gẹ́gẹ́ bí àmì ìsìn Kristẹni apẹ̀yìndà náà. Ohun tó wù kí Kọnsitatáìnì rí lọ́bẹ̀ tó fi warú sọ́wọ́, ohun tá a sáà mọ̀ ni pé àgbélébùú ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú Jésù Kristi. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, inú ìsìn àwọn Kèfèrí àtọdúnmọ́dún ni àgbélébùú ti wá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Wọ́n ti máa ń lo àgbélébùú láàárín àwọn èèyàn tó wà ṣáájú àkókò tí ìsìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ àti láàárín àwọn tí kì í ṣe Kristẹni pàápàá.” Àwọn ìwé mìíràn sọ pé láyé ọjọ́un, àwọn tó
ń jọ́sìn àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá máa ń lo àgbélébùú nínú ìjọsìn wọn, àwọn Kèfèrí sì máa ń lò ó nínú àwọn ayẹyẹ tó ń gbé ìbálòpọ̀ lárugẹ.Kí wá nìdí tí wọ́n fi gbé àgbélébùú tó jẹ́ àmì ìjọsìn àwọn Kèfèrí ayé ọjọ́un lárugẹ? Ó jọ pé ìdí tí wọ́n fi gbé e lárugẹ ni kó bàa lè rọrùn fáwọn Kèfèrí láti yí padà sí “ìsìn Kristẹni” táwọn èèyàn náà gbà pé àwọn ń ṣe. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ ọ́, ó là á, pé jíjọ́sìn ohunkóhun tó jẹ́ àmì ìjọsìn Kèfèrí kò tọ̀nà. (2 Kọ́ríńtì 6:14-18) Ìwé Mímọ́ tún ka onírúurú ìbọ̀rìṣà léèwọ̀. (Ẹ́kísódù 20:4, 5; 1 Kọ́ríńtì 10:14) Nítorí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í lo àgbélébùú nínú ìjọsìn. *
^ ìpínrọ̀ 1 Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àgbélébùú, wo ojú ìwé 89 sí 93 nínú ìwé Reasoning From the Scriptures, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.